Oni 4:7-8
Oni 4:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni mo pada, mo si ri asan labẹ õrun. Ẹnikan ṣoṣo wà, kò si ni ẹnikeji; nitõtọ kò li ọmọ, bẹ̃ni kò li arakunrin: sibẹ kò si opin ninu lãla rẹ̀ gbogbo; bẹ̃li ọrọ̀ kò tẹ oju rẹ̀ lọrun: bẹ̃ni kò si wipe, Nitori tali emi nṣe lãla, ti mo si nfi ire dù ọkàn mi? Eyi pẹlu asan ni ati iṣẹ òṣi.
Oni 4:7-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn: Ọkùnrin kan ṣoṣo dá wà; kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbí kò sí òpin nínú làálàá rẹ̀ gbogbo, síbẹ̀, ọrọ̀ kò tẹ́ ojú rẹ̀ lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni kò sì wí pé, “Nítorí ta ni èmí ṣe ń ṣe làálàá, àti wí pé, èétiṣe tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?” Eléyìí náà asán ni iṣẹ́ òsì!
Oni 4:7-8 Yoruba Bible (YCE)
Mo tún rí ohun asán kan láyé: Ọkunrin kan wà tí kò ní ẹnìkan, kò lọ́mọ, kò lárá, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìyekan, sibẹsibẹ làálàá rẹ̀ kò lópin, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìtẹ́lọ́rùn ninu ọrọ̀ rẹ̀. Kò fijọ́ kan bi ara rẹ̀ léèrè rí pé, “Ta ni mò ń ṣe làálàá yìí fún tí mo sì ń fi ìgbádùn du ara mi?” Asán ni èyí pàápàá ati ìmúlẹ̀mófo.