Oni 4:7-12
Oni 4:7-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni mo pada, mo si ri asan labẹ õrun. Ẹnikan ṣoṣo wà, kò si ni ẹnikeji; nitõtọ kò li ọmọ, bẹ̃ni kò li arakunrin: sibẹ kò si opin ninu lãla rẹ̀ gbogbo; bẹ̃li ọrọ̀ kò tẹ oju rẹ̀ lọrun: bẹ̃ni kò si wipe, Nitori tali emi nṣe lãla, ti mo si nfi ire dù ọkàn mi? Eyi pẹlu asan ni ati iṣẹ òṣi. Ẹni meji san jù ẹnikan; nitori nwọn ni ère rere fun lãla wọn. Nitoripe bi nwọn ba ṣubu, ẹnikini yio gbe ọ̀gba rẹ̀ dide: ṣugbọn egbe ni fun ẹniti o ṣe on nikan nigbati o ba ṣubu; ti kò li ẹlomiran ti yio gbé e dide. Ati pẹlu, bi ẹni meji ba dubulẹ pọ̀, nigbana ni nwọn o mõru: ṣugbọn ẹnikan yio ha ti ṣe mõru? Bi ẹnikan ba kọlu ẹnikan, ẹni meji yio kò o loju; ati okùn onikọ mẹta kì iyá fàja.
Oni 4:7-12 Yoruba Bible (YCE)
Mo tún rí ohun asán kan láyé: Ọkunrin kan wà tí kò ní ẹnìkan, kò lọ́mọ, kò lárá, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìyekan, sibẹsibẹ làálàá rẹ̀ kò lópin, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìtẹ́lọ́rùn ninu ọrọ̀ rẹ̀. Kò fijọ́ kan bi ara rẹ̀ léèrè rí pé, “Ta ni mò ń ṣe làálàá yìí fún tí mo sì ń fi ìgbádùn du ara mi?” Asán ni èyí pàápàá ati ìmúlẹ̀mófo. Eniyan meji sàn ju ẹnìkan ṣoṣo lọ, nítorí wọn yóo lè jọ ṣiṣẹ́, èrè wọn yóo sì pọ̀. Bí ọ̀kan bá ṣubú, ekeji yóo gbé e dìde. Ṣugbọn ẹni tí ó dá wà gbé! Nítorí nígbà tí ó bá ṣubú kò ní sí ẹni tí yóo gbé e dìde. Bẹ́ẹ̀ sì tún ni, bí eniyan meji bá sùn pọ̀, wọn yóo fi ooru mú ara wọn ṣugbọn báwo ni ẹnìkan ṣe lè fi ooru mú ara rẹ̀? Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ni eniyan kan lè dojú ìjà kọ, nítorí pé eniyan meji lè gba ara wọn kalẹ̀. Okùn onípọn mẹta kò lè ṣe é já bọ̀rọ̀.
Oni 4:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn: Ọkùnrin kan ṣoṣo dá wà; kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbí kò sí òpin nínú làálàá rẹ̀ gbogbo, síbẹ̀, ọrọ̀ kò tẹ́ ojú rẹ̀ lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni kò sì wí pé, “Nítorí ta ni èmí ṣe ń ṣe làálàá, àti wí pé, èétiṣe tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?” Eléyìí náà asán ni iṣẹ́ òsì! Ẹni méjì sàn ju ẹnìkan, nítorí wọ́n ní èrè rere fún làálàá wọn: Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀, ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fà á sókè, ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubú tí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn án lọ́wọ́! Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá sùn pọ̀, wọn yóò móoru. Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan, àwọn méjì le è gbìjà ara wọn, ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn ún yára fà já.