Oni 4:1-4
Oni 4:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
BẸ̃NI mo pada, mo si rò inilara gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn; mo si wò omije awọn ti a nnilara, nwọn kò si ni olutunu; ati lọwọ aninilara wọn ni ipá wà; ṣugbọn nwọn kò ni olutunu. Nitorina mo yìn okú ti o ti kú pẹ jù awọn alãye ti o wà lãye sibẹ. Nitõtọ, ẹniti kò ti isi san jù awọn mejeji; ẹniti kò ti iri iṣẹ buburu ti a nṣe labẹ õrùn. Ati pẹlu, mo rò gbogbo lãla ati ìmọ iṣẹ gbogbo, pe eyiyi ni ilara ẹnikini lati ọdọ ẹnikeji rẹ̀. Asan li eyi pẹlu ati imulẹmofo.
Oni 4:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Mo tún rí i bí àwọn eniyan tí ń ni ẹlòmíràn lára láyé. Wò ó! Omi ń bọ́ lójú àwọn tí à ń ni lára, Kò sì sí ẹnìkan tí yóo tù wọ́n ninu. Ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára ni agbára kọ̀dí sí, kò sì sí ẹni tí yóo tu àwọn tí à ń ni lára ninu. Mo wá rò ó pé, àwọn òkú, tí wọ́n ti kú, ṣe oríire ju àwọn alààyè tí wọ́n ṣì wà láàyè lọ. Ṣugbọn ti ẹni tí wọn kò tíì bí rárá, sàn ju ti àwọn mejeeji lọ, nítorí kò tíì rí iṣẹ́ ibi tí àwọn ọmọ aráyé ń ṣe. Mo rí i pé gbogbo làálàá tí eniyan ń ṣe ati gbogbo akitiyan rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, ó ń ṣe é nítorí pé eniyan ń jowú aládùúgbò rẹ̀ ni. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pàápàá.
Oni 4:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo sì tún wò ó, mo sì rí gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn, mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni, wọn kò sì ní olùtùnú kankan, agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lára, wọn kò sì ní olùtùnú kankan. Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kú tí wọ́n sì ti lọ, ó sàn fún wọn ju àwọn tí wọ́n sì wà láààyè lọ. Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn ju àwọn méjèèjì lọ: ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburú tí ó ń lọ ní abẹ́ oòrùn. Mo sì tún mọ̀ pẹ̀lú, ìdí tí ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ tagbára tagbára láti ṣe àṣeyọrí, nítorí pé wọn ń jowú àwọn aládùúgbò wọn ni. Ṣùgbọ́n, asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.