Oni 4:1-16

Oni 4:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

BẸ̃NI mo pada, mo si rò inilara gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn; mo si wò omije awọn ti a nnilara, nwọn kò si ni olutunu; ati lọwọ aninilara wọn ni ipá wà; ṣugbọn nwọn kò ni olutunu. Nitorina mo yìn okú ti o ti kú pẹ jù awọn alãye ti o wà lãye sibẹ. Nitõtọ, ẹniti kò ti isi san jù awọn mejeji; ẹniti kò ti iri iṣẹ buburu ti a nṣe labẹ õrùn. Ati pẹlu, mo rò gbogbo lãla ati ìmọ iṣẹ gbogbo, pe eyiyi ni ilara ẹnikini lati ọdọ ẹnikeji rẹ̀. Asan li eyi pẹlu ati imulẹmofo. Aṣiwère fọwọ rẹ̀ lọwọ, o si njẹ ẹran-ara rẹ̀. Onjẹ ikunwọ kan pẹlu idakẹjẹ, o san jù ikunwọ meji lọ ti o kun fun lãla ati imulẹmofo. Nigbana ni mo pada, mo si ri asan labẹ õrun. Ẹnikan ṣoṣo wà, kò si ni ẹnikeji; nitõtọ kò li ọmọ, bẹ̃ni kò li arakunrin: sibẹ kò si opin ninu lãla rẹ̀ gbogbo; bẹ̃li ọrọ̀ kò tẹ oju rẹ̀ lọrun: bẹ̃ni kò si wipe, Nitori tali emi nṣe lãla, ti mo si nfi ire dù ọkàn mi? Eyi pẹlu asan ni ati iṣẹ òṣi. Ẹni meji san jù ẹnikan; nitori nwọn ni ère rere fun lãla wọn. Nitoripe bi nwọn ba ṣubu, ẹnikini yio gbe ọ̀gba rẹ̀ dide: ṣugbọn egbe ni fun ẹniti o ṣe on nikan nigbati o ba ṣubu; ti kò li ẹlomiran ti yio gbé e dide. Ati pẹlu, bi ẹni meji ba dubulẹ pọ̀, nigbana ni nwọn o mõru: ṣugbọn ẹnikan yio ha ti ṣe mõru? Bi ẹnikan ba kọlu ẹnikan, ẹni meji yio kò o loju; ati okùn onikọ mẹta kì iyá fàja. Otoṣi ipẹ̃rẹ ti o ṣe ọlọgbọ́n, o san jù arugbo ati aṣiwère ọba lọ ti kò mọ̀ bi a ti igbà ìmọran. Nitoripe lati inu tubu li o ti jade wá ijọba; bi a tilẹ ti bi i ni talaka ni ijọba rẹ̀. Mo ri gbogbo alãye ti nrìn labẹ õrun, pẹlu ipẹ̃rẹ ekeji ti yio dide duro ni ipò rẹ̀. Kò si opin gbogbo awọn enia na, ani fun gbogbo awọn ti on wà ṣiwaju wọn: awọn pẹlu ti mbọ̀ lẹhin kì yio yọ̀ si i. Nitõtọ asan li eyi pẹlu ati imulẹmofo.

Oni 4:1-16 Yoruba Bible (YCE)

Mo tún rí i bí àwọn eniyan tí ń ni ẹlòmíràn lára láyé. Wò ó! Omi ń bọ́ lójú àwọn tí à ń ni lára, Kò sì sí ẹnìkan tí yóo tù wọ́n ninu. Ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára ni agbára kọ̀dí sí, kò sì sí ẹni tí yóo tu àwọn tí à ń ni lára ninu. Mo wá rò ó pé, àwọn òkú, tí wọ́n ti kú, ṣe oríire ju àwọn alààyè tí wọ́n ṣì wà láàyè lọ. Ṣugbọn ti ẹni tí wọn kò tíì bí rárá, sàn ju ti àwọn mejeeji lọ, nítorí kò tíì rí iṣẹ́ ibi tí àwọn ọmọ aráyé ń ṣe. Mo rí i pé gbogbo làálàá tí eniyan ń ṣe ati gbogbo akitiyan rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, ó ń ṣe é nítorí pé eniyan ń jowú aládùúgbò rẹ̀ ni. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pàápàá. Òmùgọ̀ eniyan níí káwọ́ gbera, tíí fi ebi pa ara rẹ̀ dójú ikú. Ó sàn kí eniyan ní nǹkan díẹ̀ pẹlu ìbàlẹ̀ àyà ju pé kí ó ní ọpọlọpọ, pẹlu làálàá ati ìmúlẹ̀mófo lọ. Mo tún rí ohun asán kan láyé: Ọkunrin kan wà tí kò ní ẹnìkan, kò lọ́mọ, kò lárá, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìyekan, sibẹsibẹ làálàá rẹ̀ kò lópin, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìtẹ́lọ́rùn ninu ọrọ̀ rẹ̀. Kò fijọ́ kan bi ara rẹ̀ léèrè rí pé, “Ta ni mò ń ṣe làálàá yìí fún tí mo sì ń fi ìgbádùn du ara mi?” Asán ni èyí pàápàá ati ìmúlẹ̀mófo. Eniyan meji sàn ju ẹnìkan ṣoṣo lọ, nítorí wọn yóo lè jọ ṣiṣẹ́, èrè wọn yóo sì pọ̀. Bí ọ̀kan bá ṣubú, ekeji yóo gbé e dìde. Ṣugbọn ẹni tí ó dá wà gbé! Nítorí nígbà tí ó bá ṣubú kò ní sí ẹni tí yóo gbé e dìde. Bẹ́ẹ̀ sì tún ni, bí eniyan meji bá sùn pọ̀, wọn yóo fi ooru mú ara wọn ṣugbọn báwo ni ẹnìkan ṣe lè fi ooru mú ara rẹ̀? Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ni eniyan kan lè dojú ìjà kọ, nítorí pé eniyan meji lè gba ara wọn kalẹ̀. Okùn onípọn mẹta kò lè ṣe é já bọ̀rọ̀. Ọlọ́gbọ́n ọdọmọde tí ó jẹ́ talaka, sàn ju òmùgọ̀ àgbàlagbà ọba, tí kò jẹ́ gba ìmọ̀ràn lọ, kì báà jẹ́ pé láti ọgbà ẹ̀wọ̀n ni òmùgọ̀ ọba náà ti bọ́ sórí ìtẹ́, tabi pé láti inú ìran talaka ni a ti bí i. Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn kiri láyé ati ọdọmọde náà tí yóo gba ipò ọba. Àwọn eniyan tí ó jọba lé lórí pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní òǹkà; sibẹ, àwọn ìran tí ó bá dé lẹ́yìn kò ní máa yọ̀ nítorí rẹ̀. Dájúdájú asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí.

Oni 4:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Mo sì tún wò ó, mo sì rí gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn, mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni, wọn kò sì ní olùtùnú kankan, agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lára, wọn kò sì ní olùtùnú kankan. Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kú tí wọ́n sì ti lọ, ó sàn fún wọn ju àwọn tí wọ́n sì wà láààyè lọ. Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn ju àwọn méjèèjì lọ: ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburú tí ó ń lọ ní abẹ́ oòrùn. Mo sì tún mọ̀ pẹ̀lú, ìdí tí ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ tagbára tagbára láti ṣe àṣeyọrí, nítorí pé wọn ń jowú àwọn aládùúgbò wọn ni. Ṣùgbọ́n, asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́. Aṣiwèrè ká ọwọ́ rẹ̀ kò ó sì ba tara rẹ̀ jẹ́. Oúnjẹ ẹ̀kúnwọ́ kan pẹ̀lú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì pẹ̀lú wàhálà, àti gbígba ìyànjú àti lé afẹ́fẹ́ lọ. Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn: Ọkùnrin kan ṣoṣo dá wà; kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbí kò sí òpin nínú làálàá rẹ̀ gbogbo, síbẹ̀, ọrọ̀ kò tẹ́ ojú rẹ̀ lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni kò sì wí pé, “Nítorí ta ni èmí ṣe ń ṣe làálàá, àti wí pé, èétiṣe tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?” Eléyìí náà asán ni iṣẹ́ òsì! Ẹni méjì sàn ju ẹnìkan, nítorí wọ́n ní èrè rere fún làálàá wọn: Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀, ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fà á sókè, ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubú tí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn án lọ́wọ́! Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá sùn pọ̀, wọn yóò móoru. Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan, àwọn méjì le è gbìjà ara wọn, ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn ún yára fà já. Òtòṣì ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ tí ó ṣe ọlọ́gbọ́n, ó sàn ju arúgbó àti aṣiwèrè ọba lọ tí kò mọ bí yóò ti ṣe gba ìmọ̀ràn, Nítorí pé láti inú túbú ni ó ti jáde láti jẹ ọba, bí a tilẹ̀ bí i ní tálákà ní ìjọba rẹ̀. Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn lábẹ́ oòrùn, pẹ̀lú ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ kejì tí yóò gba ipò ọba yìí. Gbogbo àwọn tí ó wà níwájú wọn kò sì lópin, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ní ó jẹ ọba lé lórí, ẹni tí ó wà ní ipò yìí kò dùn mọ́ àwọn tí ó tẹ̀lé wọn nínú. Asán ni eléyìí pẹ̀lú jẹ́, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa