Oni 3:1-22

Oni 3:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUKULÙKU ohun li akoko wà fun, ati ìgba fun iṣẹ gbogbo labẹ ọrun. Ìgba bibini, ati ìgba kikú, ìgba gbigbin ati ìgba kika ohun ti a gbin; Ìgba pipa ati ìgba imularada; ìgba wiwo lulẹ ati ìgba kikọ; Ìgba sisọkun ati ìgba rirẹrín; ìgba ṣiṣọ̀fọ ati igba jijo; Ìgba kikó okuta danu, ati ìgba kiko okuta jọ; ìgba fifọwọkoni mọra, ati ìgba fifasẹhin ni fifọwọkoni mọra; Ìgba wiwari, ati ìgba sísọnu: ìgba pipamọ́ ati ìgba ṣiṣa tì; Ìgba fifaya, ati ìgba rirán; ìgba didakẹ, ati ìgba fifọhùn; Ìgba fifẹ, ati ìgba kikorira; ìgba ogun, ati ìgba alafia. Ere kili ẹniti nṣiṣẹ ni ninu eyiti o nṣe lãla? Mo ti ri ìṣẹ́ ti Ọlọrun fi fun awọn ọmọ enia lati ma ṣíṣẹ ninu rẹ̀. O ti ṣe ohun gbogbo daradara ni ìgba tirẹ̀; pẹlupẹlu o fi aiyeraiye si wọn li aiya, bẹ̃li ẹnikan kò le ridi iṣẹ na ti Ọlọrun nṣe lati ipilẹṣẹ titi de opin. Emi mọ̀ pe kò si rere ninu wọn, bikoṣe ki enia ki o ma yọ̀, ki o si ma ṣe rere li aiya rẹ̀. Ati pẹlu ki olukulùku enia ki o ma jẹ ki o si ma mu, ki o si ma jadùn gbogbo lãla rẹ̀, ẹ̀bun Ọlọrun ni. Emi mọ̀ pe ohunkohun ti Ọlọrun ṣe yio wà lailai: a kò le fi ohun kan kún u, bẹ̃li a kò le mu ohun kan kuro ninu rẹ̀; Ọlọrun si ṣe eyi ki enia ki o le ma bẹ̀ru rẹ̀. Ohun ti o ti wà ri mbẹ nisisiyi, ati eyi ti yio si wà, o ti wà na; Ọlọrun si bère eyi ti o ti kọja lọ. Ati pẹlupẹlu mo ri ibi idajọ labẹ õrùn pe ìwa buburu mbẹ nibẹ; ati ni ibi ododo, pe aiṣedẽde mbẹ nibẹ. Mo wi li aiya mi pe, Ọlọrun yio ṣe idajọ olododo ati enia buburu: nitoripe ìgba kan mbẹ fun ipinnu ati fun iṣẹ gbogbo. Mo wi li aiya mi niti ìwa awọn ọmọ enia; ki Ọlọrun ki o le fi wọn hàn, ati ki nwọn ki o le ri pe ẹran ni awọn tikalawọn fun ara wọn. Nitoripe ohun ti nṣe ọmọ enia nṣe ẹran; ani ohun kanna li o nṣe wọn: bi ekini ti nkú bẹ̃li ekeji nkú; nitõtọ ẹmi kanna ni gbogbo wọn ní, bẹ̃li enia kò li ọlá jù ẹran lọ: nitoripe asan ni gbogbo rẹ̀. Nibikanna ni gbogbo wọn nlọ; lati inu erupẹ wá ni gbogbo wọn, gbogbo wọn si tun pada di erupẹ. Tali o mọ̀ ẹmi ọmọ enia ti ngoke si apa òke, ati ẹmi ẹran ti nsọkalẹ si isalẹ ilẹ? Nitorina mo woye pe kò si ohun ti o dara jù ki enia ki o ma yọ̀ ni iṣẹ ara rẹ̀; nitori eyini ni ipin rẹ̀: nitoripe tani yio mu u wá ri ohun ti yio wà lẹhin rẹ̀.

Oni 3:1-22 Yoruba Bible (YCE)

Gbogbo nǹkan láyé yìí ló ní àkókò ati ìgbà tirẹ̀: àkókò bíbí wà, àkókò kíkú sì wà; àkókò gbígbìn wà, àkókò kíkórè ohun tí a gbìn sì wà. Àkókò pípa wà, àkókò wíwòsàn sì wà, àkókò wíwó lulẹ̀ wà, àkókò kíkọ́ sì wà. Àkókò ẹkún wà, àkókò ẹ̀rín sì wà; àkókò ọ̀fọ̀ wà, àkókò ijó sì wà. Àkókò fífọ́n òkúta ká wà, àkókò kíkó òkúta jọ sì wà; àkókò ìkónimọ́ra wà, àkókò àìkónimọ́ra sì wà. Àkókò wíwá nǹkan wà, àkókò sísọ nǹkan nù wà; àkókò fífi nǹkan pamọ́ wà, àkókò dída nǹkan nù sì wà. Àkókò fífa nǹkan ya wà, àkókò rírán nǹkan pọ̀ sì wà; àkókò dídákẹ́ wà, àkókò ọ̀rọ̀ sísọ sì wà. Àkókò láti fi ìfẹ́ hàn wà àkókò láti kórìíra sì wà; àkókò ogun wà, àkókò alaafia sì wà. Kí ni èrè làálàá òṣìṣẹ́? Mo ti mọ ẹrù ńlá tí Ọlọrun dì ru ọmọ eniyan. Ó ṣe ohun gbogbo dáradára, ní àkókò rẹ̀. Ó fi ayérayé sí ọkàn eniyan, sibẹ, ẹnikẹ́ni kò lè rídìí ohun tí Ọlọrun ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Mo mọ̀ pé kò sí ohun tí ó yẹ wọ́n ju pé kí inú wọn máa dùn, kí wọ́n sì máa ṣe rere ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn; ati pé ẹ̀bùn Ọlọrun ni pé kí olukuluku jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn lẹ́yìn làálàá rẹ̀. Mo mọ̀ pé gbogbo ohun tí Ọlọrun ṣe, yóo wà títí lae. Kò sí ohun tí ẹ̀dá lè fi kún un, tabi tí ẹ̀dá lè yọ kúrò níbẹ̀, Ọlọrun ni ó dá a bẹ́ẹ̀ kí eniyan lè máa bẹ̀rù rẹ̀. Ohunkohun tí ó wà, ó ti wà tẹ́lẹ̀, èyí tí yóo sì tún wà, òun pàápàá ti wà rí; Ọlọrun yóo ṣe ìwádìí gbogbo ohun tí ó ti kọjá. Mo rí i pé ninu ayé yìí ibi tí ó yẹ kí ìdájọ́ òtítọ́ ati òdodo wà ibẹ̀ gan-an ni ìwà ìkà wà. Mo wí ní ọkàn ara mi pé, Ọlọrun yóo dájọ́ fún olódodo ati fún eniyan burúkú; nítorí ó ti yan àkókò fún ohun gbogbo ati fún iṣẹ́ gbogbo. Mo wí ní ọkàn ara mi pé Ọlọrun ń dán àwọn ọmọ eniyan wò, láti fihàn wọ́n pé wọn kò yàtọ̀ sí ẹranko; nítorí kò sí ìyàtọ̀ láàrin òpin eniyan ati ti ẹranko. Bí eniyan ṣe ń kú, ni ẹranko ṣe ń kú. Èémí kan náà ni wọ́n ń mí; eniyan kò ní anfaani kankan ju ẹranko lọ; nítorí pé asán ni ohun gbogbo. Ibìkan náà ni gbogbo wọn ń lọ; inú erùpẹ̀ ni gbogbo wọn ti wá, inú erùpẹ̀ ni wọn yóo sì pada sí. Ta ló mọ̀ dájúdájú, pé ẹ̀mí eniyan a máa gòkè lọ sọ́run; tí ti ẹranko sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ sinu ilẹ̀? Nítorí náà, mo rí i pé kò sí ohun tí ó dára, ju pé kí eniyan jẹ ìgbádùn iṣẹ́ rẹ̀ lọ, nítorí ìpín tirẹ̀ ni. Ta ló lè dá eniyan pada sáyé, kí ó wá rí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ó bá ti kú?

Oni 3:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àsìkò wà fún ohun gbogbo, àti ìgbà fún gbogbo nǹkan ní abẹ́ ọ̀run. Ìgbà láti bí àti ìgbà kíkú, ìgbà láti gbìn àti ìgbà láti fàtu. Ìgbà láti pa àti ìgbà láti mú láradá ìgbà láti wó lulẹ̀ àti ìgbà láti kọ́. Ìgbà láti sọkún àti ìgbà láti rín ẹ̀rín ìgbà láti ṣọ̀fọ̀ àti ìgbà láti jó Ìgbà láti tú òkúta ká àti ìgbà láti ṣà wọ́n jọ ìgbà láti súnmọ́ àti ìgbà láti fàsẹ́yìn Ìgbà láti wá kiri àti ìgbà láti ṣàì wá kiri ìgbà láti pamọ́ àti ìgbà láti jù nù, Ìgbà láti ya àti ìgbà láti rán ìgbà láti dákẹ́ àti ìgbà láti sọ̀rọ̀ Ìgbà láti ní ìfẹ́ àti ìgbà láti kórìíra ìgbà fún ogun àti ìgbà fún àlàáfíà. Kí ni òṣìṣẹ́ jẹ ní èrè nínú wàhálà rẹ̀? Mo ti rí àjàgà tí Ọlọ́run gbé lé ọmọ ènìyàn. Ó ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní àsìkò tirẹ̀, ó sì ti fi èrò nípa ayérayé sí ọkàn ọmọ ènìyàn, síbẹ̀, wọn kò le ṣe àwárí ìdí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin. Mo mọ̀ wí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ju pé kí inú wọn dùn kí wọn sì ṣe rere níwọ̀n ìgbà tí wọ́n sì wà láààyè. Wí pé: kí olúkúlùkù le è jẹ, kí wọn sì mu, kí wọn sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú gbogbo iṣẹ́ wọn ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí jẹ́. Mo mọ̀ wí pé ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe ni yóò wà títí láé, kò sí ohun tí a lè fi kún un tàbí kí a yọ kúrò nínú rẹ̀. Ọlọ́run ṣe èyí kí ènìyàn le è ní ìbẹ̀rù rẹ̀ ni. Ohun tí ó wà ti wà tẹ́lẹ̀, ohun tí ó ń bọ̀ wá ti wà tẹ́lẹ̀, Ọlọ́run yóò sì mú kí àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn tún ṣẹlẹ̀. Mo sì tún rí ohun mìíràn ní abẹ́ ọ̀run dípò ìdájọ́, òdodo ni ó wà níbẹ̀ dípò ètò òtítọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ni o wà níbẹ̀. Mo wí nínú ọkàn mi, “Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ olódodo àti ènìyàn búburú, nítorí pé àsìkò yóò wà fún gbogbo iṣẹ́, àti àsìkò ṣe ìdájọ́ gbogbo ìṣe.” Mo tún rò pé “Ọlọ́run ń dán wa wò láti fihàn wá wí pé bí ẹranko ni ènìyàn rí. Ó ní láti jẹ́ ohun ìrántí pé ìpín ènìyàn rí bí i tẹranko ìpín kan náà ń dúró dè wọ́n. Bí ọ̀kan ti ń kú náà ni èkejì yóò kú. Àwọn méjèèjì ni irú èémí kan náà, ènìyàn kò sàn ju ẹranko lọ, nítorí pé asán ni yíyè jẹ́ fún wọn. Ibìkan náà ni gbogbo wọn ń lọ, wọ́n wá láti inú erùpẹ̀, inú erùpẹ̀ náà ni wọn yóò tún padà sí. Ta ni ó mọ̀ bóyá ẹ̀mí ènìyàn ń lọ sí òkè tí ẹ̀mí ẹranko sì ń lọ sí ìsàlẹ̀ nínú ilẹ̀ ni?” Nígbà náà, ni mo wá rí i wí pé, kò sí ohun tí ó sàn fún ènìyàn ju kí ó gbádùn iṣẹ́ rẹ̀, nítorí pé ìpín tirẹ̀ ni èyí. Tàbí ta ni ó le è mú kí ó rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ kò sí!