Oni 3:1-13
Oni 3:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUKULÙKU ohun li akoko wà fun, ati ìgba fun iṣẹ gbogbo labẹ ọrun. Ìgba bibini, ati ìgba kikú, ìgba gbigbin ati ìgba kika ohun ti a gbin; Ìgba pipa ati ìgba imularada; ìgba wiwo lulẹ ati ìgba kikọ; Ìgba sisọkun ati ìgba rirẹrín; ìgba ṣiṣọ̀fọ ati igba jijo; Ìgba kikó okuta danu, ati ìgba kiko okuta jọ; ìgba fifọwọkoni mọra, ati ìgba fifasẹhin ni fifọwọkoni mọra; Ìgba wiwari, ati ìgba sísọnu: ìgba pipamọ́ ati ìgba ṣiṣa tì; Ìgba fifaya, ati ìgba rirán; ìgba didakẹ, ati ìgba fifọhùn; Ìgba fifẹ, ati ìgba kikorira; ìgba ogun, ati ìgba alafia. Ere kili ẹniti nṣiṣẹ ni ninu eyiti o nṣe lãla? Mo ti ri ìṣẹ́ ti Ọlọrun fi fun awọn ọmọ enia lati ma ṣíṣẹ ninu rẹ̀. O ti ṣe ohun gbogbo daradara ni ìgba tirẹ̀; pẹlupẹlu o fi aiyeraiye si wọn li aiya, bẹ̃li ẹnikan kò le ridi iṣẹ na ti Ọlọrun nṣe lati ipilẹṣẹ titi de opin. Emi mọ̀ pe kò si rere ninu wọn, bikoṣe ki enia ki o ma yọ̀, ki o si ma ṣe rere li aiya rẹ̀. Ati pẹlu ki olukulùku enia ki o ma jẹ ki o si ma mu, ki o si ma jadùn gbogbo lãla rẹ̀, ẹ̀bun Ọlọrun ni.
Oni 3:1-13 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo nǹkan láyé yìí ló ní àkókò ati ìgbà tirẹ̀: àkókò bíbí wà, àkókò kíkú sì wà; àkókò gbígbìn wà, àkókò kíkórè ohun tí a gbìn sì wà. Àkókò pípa wà, àkókò wíwòsàn sì wà, àkókò wíwó lulẹ̀ wà, àkókò kíkọ́ sì wà. Àkókò ẹkún wà, àkókò ẹ̀rín sì wà; àkókò ọ̀fọ̀ wà, àkókò ijó sì wà. Àkókò fífọ́n òkúta ká wà, àkókò kíkó òkúta jọ sì wà; àkókò ìkónimọ́ra wà, àkókò àìkónimọ́ra sì wà. Àkókò wíwá nǹkan wà, àkókò sísọ nǹkan nù wà; àkókò fífi nǹkan pamọ́ wà, àkókò dída nǹkan nù sì wà. Àkókò fífa nǹkan ya wà, àkókò rírán nǹkan pọ̀ sì wà; àkókò dídákẹ́ wà, àkókò ọ̀rọ̀ sísọ sì wà. Àkókò láti fi ìfẹ́ hàn wà àkókò láti kórìíra sì wà; àkókò ogun wà, àkókò alaafia sì wà. Kí ni èrè làálàá òṣìṣẹ́? Mo ti mọ ẹrù ńlá tí Ọlọrun dì ru ọmọ eniyan. Ó ṣe ohun gbogbo dáradára, ní àkókò rẹ̀. Ó fi ayérayé sí ọkàn eniyan, sibẹ, ẹnikẹ́ni kò lè rídìí ohun tí Ọlọrun ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Mo mọ̀ pé kò sí ohun tí ó yẹ wọ́n ju pé kí inú wọn máa dùn, kí wọ́n sì máa ṣe rere ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn; ati pé ẹ̀bùn Ọlọrun ni pé kí olukuluku jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn lẹ́yìn làálàá rẹ̀.
Oni 3:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àsìkò wà fún ohun gbogbo, àti ìgbà fún gbogbo nǹkan ní abẹ́ ọ̀run. Ìgbà láti bí àti ìgbà kíkú, ìgbà láti gbìn àti ìgbà láti fàtu. Ìgbà láti pa àti ìgbà láti mú láradá ìgbà láti wó lulẹ̀ àti ìgbà láti kọ́. Ìgbà láti sọkún àti ìgbà láti rín ẹ̀rín ìgbà láti ṣọ̀fọ̀ àti ìgbà láti jó Ìgbà láti tú òkúta ká àti ìgbà láti ṣà wọ́n jọ ìgbà láti súnmọ́ àti ìgbà láti fàsẹ́yìn Ìgbà láti wá kiri àti ìgbà láti ṣàì wá kiri ìgbà láti pamọ́ àti ìgbà láti jù nù, Ìgbà láti ya àti ìgbà láti rán ìgbà láti dákẹ́ àti ìgbà láti sọ̀rọ̀ Ìgbà láti ní ìfẹ́ àti ìgbà láti kórìíra ìgbà fún ogun àti ìgbà fún àlàáfíà. Kí ni òṣìṣẹ́ jẹ ní èrè nínú wàhálà rẹ̀? Mo ti rí àjàgà tí Ọlọ́run gbé lé ọmọ ènìyàn. Ó ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní àsìkò tirẹ̀, ó sì ti fi èrò nípa ayérayé sí ọkàn ọmọ ènìyàn, síbẹ̀, wọn kò le ṣe àwárí ìdí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin. Mo mọ̀ wí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ju pé kí inú wọn dùn kí wọn sì ṣe rere níwọ̀n ìgbà tí wọ́n sì wà láààyè. Wí pé: kí olúkúlùkù le è jẹ, kí wọn sì mu, kí wọn sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú gbogbo iṣẹ́ wọn ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí jẹ́.