Deu 9:5
Deu 9:5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki iṣe nitori ododo rẹ, tabi nitori pipé ọkàn rẹ, ni iwọ fi nlọ lati gbà ilẹ wọn: ṣugbọn nitori ìwabuburu awọn orilẹ-ède wọnyi li OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe lé wọn kuro niwaju rẹ, ati ki o le mu ọ̀rọ na ṣẹ ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ, Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu.
Deu 9:5 Yoruba Bible (YCE)
Kì í ṣe nítorí ìwà òdodo yín, tabi ìdúróṣinṣin ọkàn yín ni ẹ óo fi rí ilẹ̀ náà gbà; ṣugbọn nítorí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi ni OLUWA Ọlọrun yín fi ń lé wọn jáde fun yín, kí ó lè mú ìlérí tí ó fi ìbúra ṣe fún Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu, àwọn baba yín, ṣẹ.
Deu 9:5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kì í ṣe nítorí òdodo yín, tàbí ìdúró ṣinṣin ni ẹ ó fi wọ ìlú wọn lọ láti gba ilẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ni OLúWA Ọlọ́run yín yóò fi lé wọn jáde kúrò níwájú u yín láti lè mú ohun tí ó búra fún àwọn baba ṣẹ: fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.