DIUTARONOMI 9

9
Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣe Àìgbọràn
1“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ óo la odò Jọdani kọjá sí òdìkejì lónìí, ẹ óo sì gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ. Àwọn ìlú wọn tóbi, tí odi tí wọ́n mọ yí wọn ká sì ga kan ojú ọ̀run. 2Àwọn eniyan náà pọ̀, wọ́n ṣígbọnlẹ̀. Àwọn òmìrán tíí ṣe ìran Anakimu ni wọ́n. Àwọn tí ẹ ti mọ̀, tí ẹ sì ti ń gbọ́ nípa wọn pé, ‘Ta ni ó lè dúró níwájú àwọn ìran Anaki?’ 3Nítorí náà, kí ẹ mọ̀ lónìí pé, OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń lọ níwájú yín, bíi iná ajónirun. Yóo pa wọ́n run, yóo sì tẹ orí wọn ba fun yín, nítorí náà, kíá ni ẹ óo lé wọn jáde, tí ẹ óo sì pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe ìlérí fun yín.
4“Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá lé wọn jáde fun yín, ẹ má ṣe wí ninu ọkàn yín pé, ‘Nítorí òdodo wa ni OLUWA ṣe mú wa wá láti gba ilẹ̀ yìí, bẹ́ẹ̀ sì ni nítorí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi ni OLUWA ṣe lé wọn jáde fún wa.’ 5Kì í ṣe nítorí ìwà òdodo yín, tabi ìdúróṣinṣin ọkàn yín ni ẹ óo fi rí ilẹ̀ náà gbà; ṣugbọn nítorí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi ni OLUWA Ọlọrun yín fi ń lé wọn jáde fun yín, kí ó lè mú ìlérí tí ó fi ìbúra ṣe fún Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu, àwọn baba yín, ṣẹ. 6Nítorí náà, ẹ mọ̀ dájú pé, kì í ṣe nítorí ìwà òdodo yín ni OLUWA Ọlọrun yín fi ń fun yín ní ilẹ̀ dáradára yìí, nítorí pé, olórí kunkun eniyan ni yín.
7“Ẹ ranti, ẹ má sì ṣe gbàgbé, bí ẹ ti mú OLUWA Ọlọrun yín bínú ninu aṣálẹ̀, láti ọjọ́ tí ẹ ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti títí tí ẹ fi dé ibí yìí ni ẹ̀ ń ṣe oríkunkun sí OLUWA. 8Àní, ní òkè Horebu, ẹ mú kí inú bí OLUWA, tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi fẹ́ pa yín run. 9Nígbà tí mo gun orí òkè lọ, láti gba tabili òkúta, tíí ṣe majẹmu tí OLUWA ba yín dá, mo wà ní orí òkè náà fún ogoji ọjọ́, láìjẹ, láìmu. 10OLUWA fún mi ní àwọn tabili òkúta meji náà, tí Ọlọrun fúnrarẹ̀ fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ. Gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ba yín sọ láti ààrin iná, ní ọjọ́ tí ẹ péjọ sí ẹsẹ̀ òkè náà ni ó wà lára àwọn tabili náà. 11Lẹ́yìn ogoji ọjọ́, OLUWA kó àwọn tabili òkúta náà, tíí ṣe tabili majẹmu, fún mi.#Eks 24:18.
12“OLUWA bá sọ fún mi pé, ‘Dìde, sọ̀kalẹ̀ kíákíá, nítorí pé àwọn eniyan rẹ, tí o kó ti Ijipti wá ti dẹ́ṣẹ̀, wọ́n ti yára yipada kúrò ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn, wọ́n ti yá ère tí a fi iná yọ́ fún ara wọn.’
13“OLUWA tún sọ fún mi pé, ‘Mo ti rí i pé olórí kunkun ni àwọn eniyan wọnyi. 14Fi mí sílẹ̀, jẹ́ kí n pa wọ́n run, kí n sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò láyé. N óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè tí yóo tóbi, tí yóo sì lágbára jù wọ́n lọ.’
15“Mo bá gbéra, mo sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè pẹlu àwọn tabili òkúta mejeeji tí a kọ majẹmu náà sí ní ọwọ́ mi. Iná sì ń jó lórí òkè náà. 16Ojú tí n óo gbé sókè, mo rí i pé ẹ ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín, ẹ ti yá ère wúrà tí ẹ fi iná yọ́, ẹ ti yára yipada kúrò ní ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín pa láṣẹ fun yín. 17Mo bá mú àwọn tabili mejeeji, mo là wọ́n mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ wọn lójú yín. 18Mo bá dọ̀bálẹ̀ gbalaja níwájú OLUWA bíi ti àkọ́kọ́, fún ogoji ọjọ́; n kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì mu, nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ ti dá, tí ẹ ṣe ohun tí ó burú níwájú OLUWA, tí ẹ sì mú un bínú. 19Nítorí inú tí OLUWA ń bí si yín ati inú rẹ̀ tí kò dùn sí yín bà mí lẹ́rù, nítorí ó ti ṣetán láti pa yín run. Ṣugbọn OLUWA tún gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi nígbà náà.#(a) Nọm 13:17; (b) Eks 17:7; (d) Nọm 11:34. 20Inú bí OLUWA sí Aaroni tóbẹ́ẹ̀ tí OLUWA fi ṣetán láti pa á run, ṣugbọn mo gbadura fún Aaroni nígbà náà. 21Mo bá gbé ère ọmọ mààlúù tí ẹ yá, tí ó jẹ́ ohun ẹ̀ṣẹ̀, mo dáná sun ún, mo lọ̀ ọ́ lúbúlúbú, mo sì dà á sinu odò tí ń ṣàn wá láti orí òkè.
22“Bẹ́ẹ̀ ni ẹ mú OLUWA bínú ní Tabera ati ní Masa, ati ni Kibiroti Hataafa. 23Bákan náà ni ẹ ṣe ní Kadeṣi Banea, nígbà tí OLUWA ran yín lọ, tí ó ní kí ẹ lọ gba ilẹ̀ tí òun ti fi fun yín. Ẹ ṣe orí kunkun sí àṣẹ OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò gbà á gbọ́, ẹ kò sì tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀. 24Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ yín, kò sí ìgbà kan tí ẹ kò ṣe orí kunkun sí OLUWA.#(a) Nọm 13:17; (b) Diut 1:21; (d) Nọm 13:31; Diut 1:26; Heb 3:16.
25“Mo bá dọ̀bálẹ̀ gbalaja níwájú rẹ̀ fún ogoji ọjọ́ nítorí pé ó pinnu láti pa yín run. 26Mo gbadura sí OLUWA, mo ní, ‘OLUWA Ọlọrun, má ṣe pa àwọn eniyan rẹ run. Ohun ìní rẹ ni wọ́n, àwọn tí o ti fi agbára rẹ rà pada, tí o fi ipá kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti. 27Ranti Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu, àwọn iranṣẹ rẹ. Má wo ti oríkunkun àwọn eniyan wọnyi, tabi ìwà burúkú wọn, ati ẹ̀ṣẹ̀ wọn,’ 28kí àwọn ará ilẹ̀ tí o ti kó wa wá má baà wí pé, ‘OLUWA kò lè mú wọn lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún wọn ati pé ó kórìíra wọn, ni ó ṣe kó wọn wá sinu aṣálẹ̀ láti pa wọ́n. 29Nítorí pé, eniyan rẹ ni wọ́n, ohun ìní rẹ ni wọ́n sì jẹ́, àwọn tí o fi agbára ńlá ati ipá kó jáde.’

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

DIUTARONOMI 9: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀