Deu 24:17-22
Deu 24:17-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ kò gbọdọ yi idajọ alejò po, tabi ti alainibaba; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe gbà aṣọ opó ni ogò: Ṣugbọn ki iwọ ki o ranti pe iwọ ti ṣe ẹrú ni Egipti, OLUWA Ọlọrun rẹ si gbà ọ silẹ kuro nibẹ̀: nitorina ni mo ṣe paṣẹ fun ọ lati ma ṣe nkan yi. Nigbati iwọ ba kore rẹ li oko rẹ, ti iwọ ba si gbagbé ití-ọkà kan silẹ ninu oko, ki iwọ ki o máṣe pada lọ mú u: ki o le ma jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó: ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le ma busi i fun ọ, ninu iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo. Nigbati iwọ ba ngún igi olifi rẹ, ki iwọ ki o máṣe tun pada wò ẹka rẹ̀: ki eyinì ki o jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó. Nigbati iwọ ba nká eso ọgbà-àjara rẹ, ki iwọ ki o máṣe peṣẹ́ lẹhin rẹ: ki eyinì ki o jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó. Ki iwọ ki o si ma ranti pe iwọ ti ṣe ẹrú ni ilẹ Egipti: nitorina ni mo ṣe paṣẹ fun ọ lati ma ṣe nkan yi.
Deu 24:17-22 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí àlejò tabi aláìníbaba po, bẹ́ẹ̀ sì ni, tí ẹ bá yá opó ní ohunkohun, ẹ kò gbọdọ̀ gba aṣọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò. Ṣugbọn ẹ ranti pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti, ati pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó rà yín pada níbẹ̀, nítorí náà ni mo fi ń pàṣẹ fun yín láti ṣe èyí. “Nígbà tí ẹ bá ń kórè ọkà ninu oko yín, tí ẹ bá gbàgbé ìdì ọkà kan sinu oko, ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ gbé e. Ẹ fi sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn aláìní baba ati àwọn opó, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun iṣẹ́ ọwọ́ yín. Bí ẹ bá ti ká èso olifi yín, ẹ kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti ká àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn aláìní baba ati àwọn opó. Bí ẹ bá ti ká èso àjàrà yín, ẹ kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti ká àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn opó ati àwọn aláìní baba. Ẹ ranti pé ẹ ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti, nítorí náà ni mo fi pàṣẹ fun yín láti ṣe èyí.
Deu 24:17-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Má ṣe yí ìdájọ́ po fún àlejò tàbí aláìní baba, tàbí gba aṣọ ìlekè opó bí ẹ̀rí. Rántí pé o jẹ́ ẹrú ní Ejibiti tí OLúWA Ọlọ́run rẹ sì gbà ọ́ níbẹ̀. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí. Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ tí o sì fojú fo ìtí kan, má ṣe padà lọ mú u. Fi í kalẹ̀ fún àwọn àlejò, aláìní baba àti opó, kí OLúWA Ọlọ́run rẹ lè bùkún fún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ. Nígbà tí o bá ń gun igi olifi lára àwọn igi i rẹ, má ṣe padà lọ sí ẹ̀ka náà ní ìgbà kejì. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó. Nígbà tí ìwọ bá kórè èso àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ, má ṣe lọ sí ọgbà náà mọ́. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó. Rántí pé ìwọ ti jẹ́ àlejò ní Ejibiti. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí.