DIUTARONOMI 24

24
Kíkọ Iyawo sílẹ̀ ati Títún Igbeyawo ṣe
1“Bí ọkunrin kan bá fẹ́ iyawo, tí iyawo náà kò bá wù ú mọ́ nítorí pé ó rí ohun àléébù kan ninu ìwà rẹ̀ tí kò tẹ́ ẹ lọ́rùn; tí ó bá já ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, tí obinrin náà jáde kúrò ní ilé rẹ̀, tí obinrin náà sì bá tirẹ̀ lọ;#Mat 5:31; 19:7; Mak 10:4 2bí obinrin yìí bá lọ ní ọkọ mìíràn, 3ṣugbọn tí kò tún wu ọkọ titun náà, tí òun náà tún já ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, tí ó sì tún tì í jáde kúrò ninu ilé rẹ̀, tabi tí ọkọ keji tí obinrin yìí fẹ́ bá kú, 4ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ kò gbọdọ̀ gbà á pada mọ́ nítorí pé obinrin náà ti di aláìmọ́. Ohun ìríra ni èyí lójú OLUWA. Ẹ kò gbọdọ̀ dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín.
Oríṣìíríṣìí Àwọn Òfin Mìíràn
5“Bí ọkunrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbeyawo, kò gbọdọ̀ jáde lọ sí ojú ogun tabi kí á fún un ní iṣẹ́ ìlú ṣe, ó gbọdọ̀ wà ní òmìnira ninu ilé rẹ̀ fún ọdún kan gbáko, kí ó máa faramọ́ iyawo rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́.
6“Bí ẹnikẹ́ni bá yá eniyan ní nǹkankan, kò gbọdọ̀ gba ọlọ tabi ọmọ ọlọ tí ẹni náà fi ń lọ ọkà gẹ́gẹ́ bíi ìdógò, nítorí pé bí ó bá gba èyíkéyìí ninu mejeeji, bí ìgbà tí ó gba ẹ̀mí eniyan ni.
7“Bí ẹnìkan bá jí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ gbé, tí ó sì ń lò ó gẹ́gẹ́ bí ẹrú, tabi tí ó tà á, pípa ni ẹ gbọdọ̀ pa olúwarẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ohun burúkú yìí kúrò láàrin yín.#Eks 21:16.
8“Bí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú yín, ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ sì rí i pé ẹ ṣe gbogbo ohun tí àwọn alufaa, ọmọ Lefi, bá là sílẹ̀ fun yín láti ṣe, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún wọn.#Lef 13:1-14:54. 9Ẹ ranti ohun tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe sí Miriamu nígbà tí ẹ̀ ń jáde ti ilẹ̀ Ijipti bọ̀.#Nọm 12:10.
10“Tí ẹ bá yá ẹnìkejì yín ní nǹkankan, ẹ kò gbọdọ̀ wọ ilé rẹ̀ lọ láti wá ohun tí yóo fi dógò. 11Ìta ni kí ẹ dúró sí, kí ẹ sì jẹ́ kí ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú un wá fun yín. 12Bí ó bá jẹ́ aláìní ni olúwarẹ̀, aṣọ tí ó bá fi dógò kò gbọdọ̀ sùn lọ́dọ̀ yín. 13Ẹ gbọdọ̀ dá a pada fún un ní alẹ́, kí ó lè rí aṣọ fi bora sùn, kí ó lè súre fun yín. Èyí yóo jẹ́ ìwà òdodo lójú OLUWA Ọlọrun yín.#Eks 22:26-27
14“Ẹ kò gbọdọ̀ rẹ́ alágbàṣe yín tí ó jẹ́ talaka ati aláìní jẹ, kì báà jẹ́ ọmọ Israẹli ẹlẹgbẹ́ yín, tabi àlejò tí ó ń gbé ọ̀kan ninu àwọn ìlú yín. 15Lojoojumọ, kí oòrùn tó wọ̀, ni kí ẹ máa san owó iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ fún un, nítorí pé ó nílò owó yìí, kò sì sí ohun mìíràn tí ó gbẹ́kẹ̀lé. Bí ẹ kò bá san án fún un, yóo ké pe OLUWA, yóo sì di ẹ̀ṣẹ̀ sí yín lọ́rùn.#Lef 19:13.
16“Ẹ kò gbọdọ̀ pa baba dípò ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ kò gbọdọ̀ pa ọmọ dípò baba, olukuluku ni yóo kú fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó bá dá.#2A. Ọba 14:6; 2Kron 25:4; Isi 18:20
17“Ẹ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí àlejò tabi aláìníbaba po, bẹ́ẹ̀ sì ni, tí ẹ bá yá opó ní ohunkohun, ẹ kò gbọdọ̀ gba aṣọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò. 18Ṣugbọn ẹ ranti pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti, ati pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó rà yín pada níbẹ̀, nítorí náà ni mo fi ń pàṣẹ fun yín láti ṣe èyí.#Eks 23:9; Lef 19:33-34; Diut 27:19.
19“Nígbà tí ẹ bá ń kórè ọkà ninu oko yín, tí ẹ bá gbàgbé ìdì ọkà kan sinu oko, ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ gbé e. Ẹ fi sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn aláìní baba ati àwọn opó, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun iṣẹ́ ọwọ́ yín. 20Bí ẹ bá ti ká èso olifi yín, ẹ kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti ká àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn aláìní baba ati àwọn opó. 21Bí ẹ bá ti ká èso àjàrà yín, ẹ kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti ká àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn opó ati àwọn aláìní baba. 22Ẹ ranti pé ẹ ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti, nítorí náà ni mo fi pàṣẹ fun yín láti ṣe èyí.#Lef 19:9-10; 23:22.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

DIUTARONOMI 24: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀