Deu 24:14-15
Deu 24:14-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ kò gbọdọ ni alagbaṣe kan lara ti iṣe talakà ati alaini, ibaṣe ninu awọn arakunrin rẹ, tabi ninu awọn alejò rẹ ti mbẹ ni ilẹ rẹ ninu ibode rẹ: Ni ọjọ́ rẹ̀, ni ki iwọ ki o sanwo ọ̀ya rẹ̀ fun u, bẹ̃ni ki o máṣe jẹ ki õrùn ki o wọ̀ bá a; nitoripe talakà li on, o si gbẹkẹ rẹ̀ lé e: ki o má ba kepè OLUWA si ọ, a si di ẹ̀ṣẹ si ọ lọrùn.
Deu 24:14-15 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ kò gbọdọ̀ rẹ́ alágbàṣe yín tí ó jẹ́ talaka ati aláìní jẹ, kì báà jẹ́ ọmọ Israẹli ẹlẹgbẹ́ yín, tabi àlejò tí ó ń gbé ọ̀kan ninu àwọn ìlú yín. Lojoojumọ, kí oòrùn tó wọ̀, ni kí ẹ máa san owó iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ fún un, nítorí pé ó nílò owó yìí, kò sì sí ohun mìíràn tí ó gbẹ́kẹ̀lé. Bí ẹ kò bá san án fún un, yóo ké pe OLUWA, yóo sì di ẹ̀ṣẹ̀ sí yín lọ́rùn.
Deu 24:14-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Má ṣe ni alágbàṣe kan lára tí ó jẹ́ tálákà àti aláìní, bóyá ó jẹ́ arákùnrin Israẹli tàbí àlejò tí ó ń gbé ní ọ̀kan nínú àwọn ìlú rẹ. San owó iṣẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà kí ó tó di àṣálẹ́, nítorí ó jẹ́ tálákà, ó sì gbẹ́kẹ̀lé e bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ó lè ké pe OLúWA sí ọ, o sì máa gba ìdálẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀.