Deu 22:6-7
Deu 22:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi iwọ ba bá itẹ́ ẹiyẹ kan pade lori igi kan, tabi ni ilẹ, ti o ní ọmọ tabi ẹyin, ti iya si bà lé ọmọ tabi lé ẹyin na, iwọ kò gbọdọ kó iya pẹlu ọmọ: Bikoṣe ki iwọ ki o jọwọ iya lọwọ lọ, ki iwọ ki o si kó ọmọ fun ara rẹ; ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le mu ọjọ́ rẹ pẹ.
Deu 22:6-7 Yoruba Bible (YCE)
“Bí ẹ bá rí ìtẹ́ ẹyẹ lórí igi tabi ní ilẹ̀, tí ẹyin tabi ọmọ bá wà ninu rẹ̀, tí ìyá ẹyẹ yìí bá ràdọ̀ bò wọ́n, tabi tí ó bá sàba lé ẹyin rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ kó àwọn ọmọ ẹyẹ náà pẹlu ìyá wọn. Ẹ níláti fi ìyá wọn sílẹ̀ kí ó máa lọ ṣugbọn ẹ lè kó àwọn ọmọ rẹ̀, kí ó lè dára fun yín, kí ẹ sì lè pẹ́ láyé.
Deu 22:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ìwọ bá ṣe alábòápàdé ìtẹ́ ẹyẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, bóyá lára igi tàbí lórí ilẹ̀, tí ìyá wọn sì jókòó lórí àwọn ọmọ, tàbí lórí àwọn ẹyin, má ṣe gbé ìyá pẹ̀lú àwọn ọmọ. Ìwọ lè gbé ọmọ, ṣùgbọ́n rí i dájú pé o jọ̀wọ́ ìyá lọ́wọ́ lọ, kí ó ba à lè dára fún ọ àti kí o lè ní ẹ̀mí gígùn.