Deu 22
22
1IWỌ kò gbọdọ ri akọ-malu tabi agutan arakunrin rẹ ti o nṣako, ki iwọ ki o si mú oju rẹ kuro lara wọn; bi o ti wù ki o ṣe ki iwọ ki o mú wọn pada tọ̀ arakunrin rẹ wá.
2Bi arakunrin rẹ kò ba si sí nitosi rẹ, tabi bi iwọ kò ba mọ̀ ọ, njẹ ki iwọ ki o mú u wá sinu ile rẹ, ki o si wà lọdọ rẹ titi arakunrin rẹ yio fi wá a wá, ki iwọ ki o si fun u pada.
3Bẹ̃ na ni ki iwọ ki o ṣe si kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; bẹ̃ na ni ki iwọ ki o ṣe si aṣọ rẹ̀; bẹ̃ na ni ki iwọ ki o si ṣe si gbogbo ohun ninù arakunrin rẹ, ti o nù lọwọ rẹ̀, ti iwọ si ri: ki iwọ ki o máṣe mú oju rẹ kuro.
4Iwọ kò gbọdọ ri kẹtẹkẹtẹ tabi akọ-malu arakunrin rẹ ki o ṣubu li ọ̀na, ki iwọ ki o si mú oju rẹ kuro lara wọn: iwọ o si ràn a lọwọ nitõtọ lati gbé e dide.
5Obinrin kò gbọdọ mú ohun ti iṣe ti ọkunrin wọ̀, bẹ̃li ọkunrin kò gbọdọ mú aṣọ obinrin wọ̀: nitoripe gbogbo ẹniti o ba ṣe bẹ̃ irira ni nwọn si OLUWA Ọlọrun rẹ.
6Bi iwọ ba bá itẹ́ ẹiyẹ kan pade lori igi kan, tabi ni ilẹ, ti o ní ọmọ tabi ẹyin, ti iya si bà lé ọmọ tabi lé ẹyin na, iwọ kò gbọdọ kó iya pẹlu ọmọ:
7Bikoṣe ki iwọ ki o jọwọ iya lọwọ lọ, ki iwọ ki o si kó ọmọ fun ara rẹ; ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le mu ọjọ́ rẹ pẹ.
8Nigbati iwọ ba kọ ile titun kan, ki iwọ ki o ṣe igbáti si orule rẹ, ki iwọ o má ba mú ẹ̀jẹ wá sara ile rẹ, bi ẹnikan ba ti ibẹ̀ ṣubu.
9Iwọ kò gbọdọ fi irú meji irugbìn gbìn ọgbà-àjara rẹ; ki eso irugbìn rẹ gbogbo ti iwọ ti gbìn, ati asunkún ọgbà-àjara rẹ, ki o má ba di ti Ọlọrun.
10Iwọ kò gbọdọ fi akọ-malu ati kẹtẹkẹtẹ tulẹ pọ̀.
11Iwọ kò gbọdọ wọ̀ aṣọ olori-ori, ti kubusu ati ti ọ̀gbọ pọ̀.
12Ki iwọ ki o ṣe wajawaja si igun mẹrẹrin aṣọ rẹ, ti iwọ fi mbò ara rẹ.
Òfin nípa Ìbálòpọ̀ Ọkunrin ati Obinrin
13Bi ọkunrin kan ba gbé iyawo kan, ti o wọle tọ̀ ọ, ti o si korira rẹ̀,
14Ti o si kà ọ̀ran si i lọrùn, ti o si bà orukọ rẹ̀ jẹ́, ti o si wipe, Mo gbé obinrin yi, nigbati mo si wọle tọ̀ ọ, emi kò bá a ni wundia:
15Nigbana ni ki baba ọmọbinrin na, ati iya rẹ̀, ki o mú àmi wundia ọmọbinrin na tọ̀ awọn àgba ilu lọ li ẹnu-bode:
16Ki baba ọmọbinrin na ki o si wi fun awọn àgba na pe, Emi fi ọmọbinrin mi fun ọkunrin yi li aya, o si korira rẹ̀;
17Si kiyesi i, o si kà ọ̀ran si i lọrùn, wipe, Emi kò bá ọmọbinrin rẹ ni wundia; bẹ̃ni wọnyi ni àmi wundia ọmọbinrin mi. Ki nwọn ki o si nà aṣọ na niwaju awọn àgba ilu.
18Ki awọn àgba ilu na ki o si mú ọkunrin na ki nwọn ki o si nà a;
19Ki nwọn ki o si bù ọgọrun ṣekeli fadakà fun u, ki nwọn ki o si fi i fun baba ọmọbinrin na, nitoriti o bà orukọ wundia kan ni Israeli jẹ́: ki on ki o si ma ṣe aya rẹ̀; ki o máṣe kọ̀ ọ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo.
20Ṣugbọn bi ohun na ba ṣe otitọ, ti a kò ba si ri àmi wundia ọmọbinrin na:
21Nigbana ni ki nwọn ki o mú ọmọbinrin na wá si ẹnu-ọ̀na ile baba rẹ̀, ki awọn ọkunrin ilu rẹ̀ ki o sọ ọ li okuta pa: nitoriti o hù ìwa-buburu ni Israeli, ni ṣiṣe àgbere ninu ile baba rẹ̀: bẹ̃ni ki iwọ ki o mú ìwa-buburu kuro lãrin nyin.
22Bi a ba mú ọkunrin kan ti o bá obinrin kan dàpọ, ti a gbé ni iyawo fun ọkọ, njẹ ki awọn mejeji ki o kú, ati ọkunrin ti o bá obinrin na dàpo, ati obinrin na: bẹ̃ni ki iwọ ki o si mú ìwa-buburu kuro ni Israeli.
23Bi ọmọbinrin wundia kan ba wà ni afẹsọna fun ọkọ, ti ọkunrin kan si ri i ni ilu, ti o si bá a dàpọ;
24Njẹ ki ẹnyin ki o mú awọn mejeji wá si ẹnu-bode ilu na, ki ẹnyin ki o si ṣo wọn li okuta pa; eyi ọmọbinrin nitoriti kò kigbe, nigbati o wà ni ilu; ati eyi ọkunrin nitoriti o tẹ́ aya ẹnikeji rẹ̀ logo: bẹ̃ni ki iwọ ki o mú ìwa-buburu kuro lãrin nyin.
25Ṣugbọn bi ọkunrin na ba ri ọmọbinrin ti afẹsọna na ni igbẹ́, ti ọkunrin na si fi agbara mú u, ti o si bà a dàpọ; njẹ kìki ọkunrin na ti o bá a dàpọ ni ki o kú:
26Ṣugbọn si ọmọbinrin na ni ki iwọ ki o máṣe ohun kan; ẹ̀ṣẹ ti o yẹ si ikú kò sí lara ọmọbinrin na: nitori bi igbati ọkunrin kan dide si ẹnikeji rẹ̀, ti o si pa a, bẹ̃li ọ̀ran yi ri:
27Nitoripe o bá a ninu igbẹ́; ọmọbinrin na ti afẹsọna kigbe, kò si sí ẹniti yio gbà a silẹ.
28Bi ọkunrin kan ba si ri ọmọbinrin kan ti iṣe wundia, ti a kò ti fẹsọna fun ọkọ, ti o si mú u, ti o si bá a dàpọ, ti a si mú wọn;
29Njẹ ki ọkunrin na ti o bá a dàpọ ki o fi ãdọta ṣekeli fadakà fun baba ọmọbinrin na, ki on ki o si ma ṣe aya rẹ̀, nitoriti o ti tẹ́ ẹ logo, ki on ki o máṣe kọ̀ ọ silẹ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo.
30Ki ọkunrin kan ki o máṣe fẹ́ aya baba rẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe tú aṣọ baba rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Deu 22: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.