Deu 14:22-23
Deu 14:22-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki iwọ ki o dá idamẹwa gbogbo ibisi irugbìn rẹ, ti nti oko rẹ wá li ọdọdún. Niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni ibi ti on o gbé yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, ni ki iwọ ki o si ma jẹ idamẹwa ọkà rẹ, ti ọti-waini rẹ, ati ti oróro rẹ, ati akọ́bi ọwọ́-ẹran rẹ, ati ti agbo-ẹran rẹ; ki iwọ ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ nigbagbogbo.
Deu 14:22-23 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ gbọdọ̀ san ìdámẹ́wàá gbogbo ìkórè oko yín ní ọdọọdún. Ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun ni kí ẹ ti jẹ ìdámẹ́wàá ọkà yín, ati ti ọtí waini yín, ati ti òróró yín, ati àkọ́bí àwọn mààlúù yín, ati ti agbo ẹran yín; kí ẹ lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín nígbà gbogbo.
Deu 14:22-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń fi ìdákan nínú mẹ́wàá nínú ìre oko yín lọ́dọọdún pamọ́ sí apá kan Ẹ jẹ ìdámẹ́wàá oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àti àkọ́bí àwọn màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín, níwájú OLúWA Ọlọ́run yín, ní ibi tí yóò yàn bí ibùgbé orúkọ rẹ̀. Kí ẹ lè kọ́ bí a ṣé ń bu ọlá fún OLúWA Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.