DIUTARONOMI 14

14
Àṣà Tí A kò Gbọdọ̀ Dá tí A bá ń Ṣọ̀fọ̀
1“Ọmọ ni ẹ jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ fi abẹ ya ara yín lára tabi kí ẹ fá irun yín níwájú nígbà tí ẹ bá ń ṣọ̀fọ̀ ẹni tí ó kú.#Lef 19:28; 21:5 2Nítorí pé, ẹni ìyàsọ́tọ̀ ni yín fún OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA ti yàn yín láti jẹ́ eniyan tirẹ̀ láàrin gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé.#Eks 19:5-6; Diut 4:20; 7:6; 26:18; Tit 2:14; 1 Pet 2:9.
Ẹran Tí Ó Mọ́ ati Èyí Tí Kò Mọ́
(Lef 11:1-47)
3“Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ ohun ìríra. 4Àwọn ẹran tí ẹ lè jẹ nìwọ̀nyí: mààlúù, aguntan, 5ewúrẹ́, àgbọ̀nrín ati èsúó ati ìgalà, ati oríṣìí ẹranko igbó kan tí ó dàbí ewúrẹ́, ati ẹranko kan tí wọn ń pè ní Pigarigi, ati ẹfọ̀n, ati ẹtu. 6Àwọn ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ wọn là sí meji, tabi tí wọ́n bá ní ìka ẹsẹ̀, tí wọ́n sì ń jẹ àpọ̀jẹ, irú wọn ni kí ẹ máa jẹ. 7Ṣugbọn ninu àwọn ẹran tí wọn ń jẹ àpọ̀jẹ ati àwọn tí pátákò ẹsẹ̀ wọn là sí meji tabi tí wọ́n ní ìka ẹsẹ̀, àwọn wọnyi ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ: ràkúnmí, ati ehoro ati ẹranko kan tí ó dàbí gara. Àwọn wọnyi ń jẹ àpọ̀jẹ lóòótọ́, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ wọn kò là, nítorí náà, wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín. 8Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹlẹ́dẹ̀, lóòótọ́ ó ní ìka ẹsẹ̀, ṣugbọn kì í jẹ àpọ̀jẹ, nítorí náà, ó jẹ́ aláìmọ́ fun yín. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fara kan òkú wọn.
9“Ninu gbogbo àwọn abẹ̀mí tí ó wà ninu omi, àwọn wọnyi ni kí ẹ máa jẹ: gbogbo àwọn ohun tí ó bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́ ni ẹ lè jẹ. 10Ṣugbọn èyíkéyìí tí kò bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n, nítorí wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín.
11“Ẹ lè jẹ gbogbo àwọn ẹyẹ tí wọ́n bá mọ́. 12Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àwọn ẹyẹ wọnyi: ẹyẹ idì, igún ati idì tí ń jẹ ẹja, 13ati àṣá gidi, ati oríṣìíríṣìí àṣá mìíràn, ati igún gidi, ati àwọn oríṣìíríṣìí igún yòókù, 14ati oríṣìíríṣìí àwọn ẹyẹ ìwò, 15ati ògòǹgò, ati òwìwí, ati ẹ̀lulùú, ati oríṣìíríṣìí àwòdì, 16ati òwìwí ńlá, ati òwìwí kéékèèké, ati ògbúgbú, 17ati ẹyẹ òfù, ati àkàlà, ati ẹyẹ ìgo, 18ati ẹyẹ àkọ̀, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ òòdẹ̀, ati ẹyẹ atọ́ka, ati àdán.
19“Gbogbo àwọn kòkòrò tí wọn ń fò jẹ́ aláìmọ́ fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n. 20Ṣugbọn ẹ lè jẹ gbogbo àwọn ohun tí ó bá ní ìyẹ́, tí wọ́n sì mọ́.
21“Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá kú fúnrarẹ̀, ẹ lè fún àwọn àlejò tí ń gbé ààrin yín, kí ó jẹ ẹ́, tabi kí ẹ tà á fún àjèjì, nítorí pé, ẹ̀yin jẹ́ ẹni mímọ́ fún OLUWA Ọlọrun yín.#Eks 23:19; 34:26
“Ẹ kò gbọdọ̀ se ọmọ ewúrẹ́ ninu wàrà ọmú ìyá rẹ̀.
Òfin nípa Ìdámẹ́wàá
22“Ẹ gbọdọ̀ san ìdámẹ́wàá gbogbo ìkórè oko yín ní ọdọọdún. 23Ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun ni kí ẹ ti jẹ ìdámẹ́wàá ọkà yín, ati ti ọtí waini yín, ati ti òróró yín, ati àkọ́bí àwọn mààlúù yín, ati ti agbo ẹran yín; kí ẹ lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín nígbà gbogbo. 24Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá bukun yín tán, tí ibi tí ó yàn pé kí ẹ ti máa sin òun bá jìnnà jù fun yín láti ru ìdámẹ́wàá ìkórè oko yín lọ, 25ẹ tà á, kí ẹ sì gba owó rẹ̀ sọ́wọ́, kí ẹ kó owó náà lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun. 26Ẹ fi owó náà ra ohunkohun tí ọkàn yín bá fẹ́, ìbáà ṣe akọ mààlúù, tabi aguntan, tabi ọtí waini, tabi ọtí líle, tabi ohunkohun tí ọkàn yín bá ṣá fẹ́. Ẹ óo jẹ ẹ́ níbẹ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, ẹ óo sì máa yọ̀, ẹ̀yin ati ìdílé yín.
27“Ẹ kò gbọdọ̀ gbàgbé àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà láàrin yín nítorí pé, wọn kò ní ìpín tabi ohun ìní láàrin yín. 28Ní òpin ọdún kẹtakẹta, ẹ níláti kó ìdámẹ́wàá ìkórè gbogbo oko yín ti ọdún náà jọ, kí ẹ kó wọn kalẹ̀ ninu gbogbo àwọn ìlú yín. 29Kí àwọn ọmọ Lefi, tí wọn kò ní ìpín ati ohun ìní láàrin yín, ati àwọn àlejò, ati àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó tí wọ́n wà ninu àwọn ìlú yín jẹ, kí wọ́n sì yó, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun yín ninu gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín.#Lef 27:30-33; Nọm 18:21

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

DIUTARONOMI 14: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀