Deu 11:18-19
Deu 11:18-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ fi ọ̀rọ mi wọnyi si àiya nyin ati si ọkàn nyin, ki ẹ si so wọn mọ́ ọwọ́ nyin fun àmi, ki nwọn ki o si ma ṣe ọjá-igbaju niwaju nyin. Ki ẹnyin ki o si ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ nyin, ki ẹnyin ma fi wọn ṣe ọ̀rọ isọ nigbati iwọ ba joko ninu ile rẹ, ati nigbati iwọ ba nrìn li ọ̀na, nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide.

Deu 11:18-19 Yoruba Bible (YCE)
“Nítorí náà, ohun tí mo sọ fun yín yìí, ẹ pa á mọ́ sinu ọkàn yín. Ẹ fi ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn, ẹ so ó mọ́ ọwọ́ yín gẹ́gẹ́ bí àmì, kí ẹ fi ṣe ọ̀já ìgbàjú, kí ó wà ní agbede meji ojú yín mejeeji. Kí ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín dáradára, ẹ máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ nígbà tí ẹ bá jókòó ninu ilé yín ati ìgbà tí ẹ bá ń rìn lọ lójú ọ̀nà, ati ìgbà tí ẹ bá dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn yín ati nígbà tí ẹ bá dìde.
Deu 11:18-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí sí àyà a yín, àti ọkàn an yín, ẹ so wọ́n bí ààmì sórí ọwọ́ yín, kí ẹ sì so wọ́n mọ́ iwájú orí yín. Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín, ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa wọn bí ẹ bá jókòó nínú ilé, àti ní ojú ọ̀nà bí ẹ bá ń rìn lọ, bí ẹ bá sùn àti bí ẹ bá jí.