DIUTARONOMI 11:18-19

DIUTARONOMI 11:18-19 YCE

“Nítorí náà, ohun tí mo sọ fun yín yìí, ẹ pa á mọ́ sinu ọkàn yín. Ẹ fi ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn, ẹ so ó mọ́ ọwọ́ yín gẹ́gẹ́ bí àmì, kí ẹ fi ṣe ọ̀já ìgbàjú, kí ó wà ní agbede meji ojú yín mejeeji. Kí ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín dáradára, ẹ máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ nígbà tí ẹ bá jókòó ninu ilé yín ati ìgbà tí ẹ bá ń rìn lọ lójú ọ̀nà, ati ìgbà tí ẹ bá dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn yín ati nígbà tí ẹ bá dìde.