Deu 1:29-35
Deu 1:29-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni mo wi fun nyin pe, Ẹ máṣe fòya, bẹ̃ni ki ẹ máṣe bẹ̀ru wọn. OLUWA Ọlọrun nyin ti nṣaju nyin, on ni yio jà fun nyin, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe fun nyin ni Egipti li oju nyin; Ati li aginjù, nibiti iwọ ri bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti gbé ọ, bi ọkunrin ti igbé ọmọ rẹ̀, li ọ̀na nyin gbogbo ti ẹnyin rìn, titi ẹnyin fi dé ihinyi. Sibẹ̀ ninu nkan yi ẹnyin kò gbà OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́. Ti nlọ li ọ̀na ṣaju nyin, lati wá ibi fun nyin, ti ẹnyin o pagọ́ nyin si, ninu iná li oru, lati fi ọ̀na ti ẹnyin o gbà hàn nyin, ati ninu awọsanma li ọsán. OLUWA si gbọ́ ohùn ọ̀rọ nyin, o si binu, o si bura, wipe, Nitõtọ ọkan ninu awọn ọkunrin wọnyi ti iran buburu yi, ki yio ri ilẹ rere na, ti mo ti bura lati fi fun awọn baba nyin
Deu 1:29-35 Yoruba Bible (YCE)
“Mo wí fun yín nígbà náà pé kí ẹ má ṣojo, kí ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín. OLUWA Ọlọrun yín tí ń ṣáájú yín ni yóo jà fun yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti jà fun yín ní ilẹ̀ Ijipti, tí ẹ̀yin náà sì fi ojú ara yín rí i. Ninu aṣálẹ̀ ńkọ́? Ṣebí ẹ rí i bí OLUWA Ọlọrun yín ti gbé yín, bí baba tíí gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ tọ̀ títí tí ẹ fi dé ibi tí ẹ wà yìí. Sibẹsibẹ ẹ kò gba OLUWA Ọlọrun yín gbọ́, Ọlọrun tí ń lọ níwájú yín ninu ọ̀wọ̀n iná lóru, ati ninu ìkùukùu lọ́sàn-án, láti fi ọ̀nà tí ẹ óo máa tọ̀ hàn yín kí ó lè bá yín wá ibi tí ẹ óo pàgọ́ yín sí. “OLUWA gbọ́ ohun tí ẹ sọ, inú bí i, ó sì búra pé, ẹnikẹ́ni ninu ìran burúkú náà kò ní fi ojú kan ilẹ̀ dáradára tí òun ti búra pé òun óo fún àwọn baba yín
Deu 1:29-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni mo sọ fún un yín pé, “Ẹ má ṣojo, ẹ kò sì gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn. OLúWA Ọlọ́run yín, tí ń ṣáájú yín yóò jà fún un yín; bí ó ti ṣe fún un yín ní Ejibiti lójú ẹ̀yin tìkára yín àti ní aginjù. Níbẹ̀ ni ẹ ti rí i bí OLúWA Ọlọ́run yín ti gbé yín, bí baba ti í gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ lọ títí ẹ fi padà dé ibí yìí.” Pẹ̀lú gbogbo èyí tí mo wí, ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé OLúWA Ọlọ́run yín, tí ń ṣáájú u yín lọ ní gbogbo ọ̀nà yín, nípa fífi iná ṣe amọ̀nà yín ní òru àti ìkùùkuu ní ọ̀sán, láti fi àwọn ibi tí ẹ lè tẹ̀dó sí hàn yín àti àwọn ọ̀nà tí ẹ ó rìn. Nígbà tí OLúWA gbọ́ ohun tí ẹ sọ, inú bí i, ó sì búra wí pé: “Kò sí ọ̀kan nínú ìran búburú yìí tí yóò dé ilẹ̀ rere tí mo ti búra láti fún àwọn baba ńlá a yín.