Deu 1:21-23
Deu 1:21-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Wò o, OLUWA Ọlọrun rẹ ti fi ilẹ na siwaju rẹ: gòke lọ, ki o si gbà a, bi OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ ti wi fun ọ; máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya máṣe fò ọ. Gbogbo nyin si tọ̀ mi wá, ẹ si wipe, Jẹ ki awa ki o rán enia lọ siwaju wa, ki nwọn ki o si rìn ilẹ na wò fun wa, ki nwọn ki o si mú ìhin pada tọ̀ wa wá, niti ọ̀na ti a o ba gòke lọ, ati ti ilu ti a o yọ si. Ọ̀rọ na si dara loju mi: mo si yàn ọkunrin mejila ninu nyin, ẹnikan ninu ẹ̀ya kan
Deu 1:21-23 Yoruba Bible (YCE)
ilẹ̀ náà ni OLUWA Ọlọrun yín tẹ́ kalẹ̀ níwájú yín yìí, mo ní kí ẹ gbéra, kí ẹ lọ gbà á, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá yín ti sọ fun yín. Mo ní kí ẹ má bẹ̀rù rárá, kí ẹ má sì fòyà. “Gbogbo yín wá sọ́dọ̀ mi, ẹ sì wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á rán àwọn eniyan lọ ṣiwaju wa, láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà, kí wọ́n lè wá jábọ̀ fún wa, kí á lè mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí á tọ̀, ati àwọn ìlú tí ó yẹ kí á wọ̀.’ “Ọ̀rọ̀ yín dára lójú mi, mo sì yan ọkunrin mejila láàrin yín, ọkunrin kọ̀ọ̀kan láàrin ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.
Deu 1:21-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ kíyèsi i, OLúWA Ọlọ́run yín ló ni ilẹ̀ náà. Ẹ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà bí OLúWA Ọlọ́run àwọn baba yín tí sọ fún un yín. Ẹ má bẹ̀rù, Ẹ má sì ṣe fòyà.” Nígbà náà ni gbogbo yín tọ̀ mí wá wí pé, “Jẹ́ kí a yan àwọn ayọ́lẹ̀wò láti yọ́ ilẹ̀ náà wò fún wa, kí wọn sì fún wa ní ìròyìn àwọn ọ̀nà tí a ó gbà àti àwọn ìlú tí a ó bá pàdé.” Èrò náà sì dára lójú mi, torí èyí ni mo ṣe yan àwọn ènìyàn méjìlá nínú yín, ẹnìkan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.