Dan 10:10-12
Dan 10:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọwọ́ kan kàn mí, ó gbé mi dìde ní ìwárìrì lórí ọwọ́ àti eékún mi. Ó sọ pé, “Daniẹli ẹni tí a yàn fẹ́ gidigidi gba ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ bá ọ sọ yìí yẹ̀ wò dáradára, kí o sì dìde, nítorí tí a rán mi sí ọ.” Bí ó ṣe sọ èyí fún mi, mo dìde ní ìwárìrì. Nígbà náà ni ó tẹ̀síwájú, pé, “Má ṣe bẹ̀rù Daniẹli. Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí ìwọ ti fi ọkàn rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run rẹ, a gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì wá nítorí ọ̀rọ̀ náà.
Dan 10:10-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Sa si kiyesi i, ọwọ kan kàn mi, ti o gbé mi dide lori ẽkun mi, ati lori atẹlẹwọ mi. O si wi fun mi pe, Danieli, iwọ ọkunrin olufẹ gidigidi, ki oye ọ̀rọ ti mo nsọ fun ọ ki o ye ọ, ki o si duro ni ipò rẹ: nitoripe iwọ li a rán mi si nisisiyi. Nigbati on ti sọ̀rọ bayi fun mi, mo dide duro ni ìwariri. Nigbana ni o wi fun mi pe, má bẹ̀ru, Danieli: lati ọjọ kini ti iwọ ti fi aiya rẹ si lati moye, ti iwọ si npọ́n ara rẹ loju niwaju Ọlọrun rẹ, a gbọ́ ọ̀rọ rẹ, emi si wá nitori ọ̀rọ rẹ.
Dan 10:10-12 Yoruba Bible (YCE)
Ọwọ́ kan bá dì mí mú, ó gbé mi nílẹ̀, mo da ọwọ́ ati orúnkún mi délẹ̀. Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n fún ìbẹ̀rù. Ẹni náà pè mí, ó ní, “Daniẹli, ẹni tí Ọlọrun fẹ́ràn! Dìde nàró kí o gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ, nítorí ìwọ ni a rán mi sí.” Bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, mo dìde nàró, ṣugbọn mo ṣì tún ń gbọ̀n. Ó bá dá mi lọ́kàn le, ó ní, “Má bẹ̀rù, Daniẹli, nítorí láti ọjọ́ tí o ti pinnu láti mòye, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọrun rẹ, gbogbo ohun tí ò ń bèèrè ni a ti gbọ́, adura rẹ ni mo sì wá dáhùn.