DANIẸLI 10:10-12

DANIẸLI 10:10-12 YCE

Ọwọ́ kan bá dì mí mú, ó gbé mi nílẹ̀, mo da ọwọ́ ati orúnkún mi délẹ̀. Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n fún ìbẹ̀rù. Ẹni náà pè mí, ó ní, “Daniẹli, ẹni tí Ọlọrun fẹ́ràn! Dìde nàró kí o gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ, nítorí ìwọ ni a rán mi sí.” Bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, mo dìde nàró, ṣugbọn mo ṣì tún ń gbọ̀n. Ó bá dá mi lọ́kàn le, ó ní, “Má bẹ̀rù, Daniẹli, nítorí láti ọjọ́ tí o ti pinnu láti mòye, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọrun rẹ, gbogbo ohun tí ò ń bèèrè ni a ti gbọ́, adura rẹ ni mo sì wá dáhùn.