Kol 4:1-18

Kol 4:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

ẸNYIN oluwa, ẹ ma fi eyiti o tọ́ ti o si dọgba fun awọn ọmọ-ọdọ nyin; ki ẹ si mọ̀ pe ẹnyin pẹlu ni Oluwa kan li ọrun. Ẹ mã duro ṣinṣin ninu adura igbà, ki ẹ si mã ṣọra ninu rẹ̀ pẹlu idupẹ; Ju gbogbo rẹ̀, ẹ mã gbadura fun wa pẹlu, ki Ọlọrun le ṣí ilẹkun fun wa fun ọrọ na, lati mã sọ ohun ijinlẹ Kristi, nitori eyiti mo ṣe wà ninu ìde pẹlu: Ki emi ki o le fihan, gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati mã sọ. Ẹ mã rìn nipa ọgbọ́n si awọn ti mbẹ lode, ki ẹ si mã ṣe ìrapada ìgba. Ẹ jẹ ki ọ̀rọ nyin ki o dàpọ mọ́ ore-ọfẹ nigbagbogbo, eyiti a fi iyọ̀ dùn, ki ẹnyin ki o le mọ̀ bi ẹnyin ó ti mã dá olukuluku enia lohùn. Gbogbo bi nkan ti ri fun mi ni Tikiku yio jẹ́ ki ẹ mọ̀, arakunrin olufẹ ati olõtọ iranṣẹ, ati ẹlẹgbẹ ninu Oluwa: Ẹniti mo ti rán si nyin nitori eyi kanna, ki ẹnyin le mọ̀ bi a ti wà, ki on ki o le tù ọkàn nyin ninu; Pẹlu Onesimu, arakunrin olõtọ ati olufẹ, ẹniti iṣe ọ̀kan ninu nyin. Awọn ni yio sọ ohun gbogbo ti a nṣe nihinyi fun nyin. Aristarku, ẹlẹgbẹ mi ninu tubu ki nyin, ati Marku, ọmọ arabinrin Barnaba (nipasẹ ẹniti ẹnyin ti gbà aṣẹ: bi o ba si wá sọdọ nyin, ẹ gbà a), Ati Jesu, ẹniti a npè ni Justu, ẹniti iṣe ti awọn onila. Awọn wọnyi nikan ni olubaṣiṣẹ mi fun ijọba Ọlọrun, awọn ẹniti o ti jasi itunu fun mi. Epafra, ẹniti iṣe ọkan ninu nyin, iranṣẹ Kristi, kí nyin, on nfi iwaya-ija gbadura nigbagbogbo fun nyin, ki ẹnyin ki o le duro ni pipé ati ni kíkun ninu gbogbo ifẹ Ọlọrun. Nitori mo jẹri rẹ̀ pe, o ni itara pupọ fun nyin, ati fun awọn ti o wà ni Laodikea, ati awọn ti o wà ni Hierapoli. Luku, oniṣegun olufẹ, ati Dema ki nyin. Ẹ kí awọn ará ti o wà ni Laodikea, ati Nimfa, ati ijọ ti o wà ni ile rẹ̀. Nigbati a ba si kà iwe yi larin nyin tan, ki ẹ mu ki a kà a pẹlu ninu ìjọ Laodikea; ki ẹnyin pẹlu si kà eyi ti o ti Laodikea wá. Ki ẹ si wi fun Arkippu pe, Kiyesi iṣẹ-iranṣẹ ti iwọ ti gbà ninu Oluwa, ki o si ṣe e ni kikún. Ikíni nipa ọwọ́ emi Paulu. Ẹ mã ranti ìde mi. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu nyin. Amin.

Kol 4:1-18 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ̀yin ọ̀gá, ohun tí ó dára ati ohun tí ó yẹ ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn ẹrú yín. Kí ẹ ranti pé ẹ̀yin náà ní Ọ̀gá kan ní ọ̀run. Ẹ tẹra mọ́ adura gbígbà. Ẹ máa fi ọkàn bá adura yín lọ. Kí ẹ sì máa dúpẹ́. Ẹ tún máa gbadura fún wa, pé kí Ọlọrun lè ṣí ìlẹ̀kùn iwaasu fún wa, kí á lè sọ ìjìnlẹ̀ àṣírí Kristi. Nítorí èyí ni mo fi wà ninu ẹ̀wọ̀n. Kí ẹ gbadura pé kí n lè ṣe àlàyé bí ó ti yẹ. Ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín pẹlu ọgbọ́n níwájú àwọn alaigbagbọ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àkókò kan kọjá láìjẹ́ pé ẹ lò ó bí ó ti yẹ. Ọ̀rọ̀ ọmọlúwàbí ni kí ó máa ti ẹnu yín jáde nígbà gbogbo, ọ̀rọ̀ tí ó bá etí mu, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ láti dá ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ń bá sọ̀rọ̀ lóhùn. Tukikọsi, àyànfẹ́ ati arakunrin wa, yóo fun yín ní ìròyìn nípa mi. Iranṣẹ tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ati ẹrú bí àwa náà ninu iṣẹ́ Oluwa. Nítorí èyí gan-an ni mo fi rán an wá sọ́dọ̀ yín, kí ẹ lè mọ bí gbogbo nǹkan ti ń lọ fún wa, kí ó lè fi ọkàn yín balẹ̀. Mo tún rán Onisimu, ọ̀kan ninu yín, tí òun náà jẹ́ àyànfẹ́ ati arakunrin tí ó sì ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Gbogbo bí nǹkan bá ti rí níhìn-ín ni wọn óo ròyìn fun yín. Arisitakọsi, ẹlẹ́wọ̀n, ẹlẹgbẹ́ mi ki yín, ati Maku, ìbátan Banaba. Ẹ ti rí ìwé gbà nípa rẹ̀. Tí ó bá dé ọ̀dọ̀ yín, kí ẹ gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀. Jesu tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Jusitu náà ki yín. Àwọn yìí nìkan ni wọ́n kọlà ninu àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi ninu iṣẹ́ ìjọba Ọlọrun. Ìtùnú ni wọ́n jẹ́ fún mi. Epafirasi, iranṣẹ Kristi Jesu, ọ̀kan ninu yín, ki yín. Nígbà gbogbo ni ó ń gbadura kíkankíkan fun yín, pé kí ẹ lè dúró ní pípé ati pé kí ẹ lè kún fún gbogbo ohun tíí ṣe ìfẹ́ Ọlọrun. Nítorí pé mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ti ṣiṣẹ́ pupọ fun yín ati fún àwọn tí ó wà ní Laodikia ati ní Hierapoli. Luku, àyànfẹ́ oníṣègùn ati Demasi ki yín. Ẹ kí àwọn arakunrin tí ó wà ní Laodikia. Ẹ kí Nimfa ati ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀. Nígbà tí ẹ bá ti ka ìwé yìí tán, kí ẹ rí i pé ìjọ tí ó wà ní Laodikia kà á pẹlu. Kí ẹ̀yin náà sì ka ìwé tí a kọ sí àwọn ará Laodikia. Ẹ sọ fún Akipu pé kí ó má jáfara nípa iṣẹ́ tí ó gbà láti ọ̀dọ̀ Oluwa, kí ó ṣe é parí. Ìkíni tí èmi Paulu fi ọwọ́ ara mi kọ nìyí. Ẹ ranti pé ninu ẹ̀wọ̀n ni mo wà. Kí oore-ọ̀fẹ́ kí ó wà pẹlu yín.

Kol 4:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹyin ọ̀gá, ẹ máa fi èyí tí ó tọ́ tí ó sì dọ́gba fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ yín; kí ẹ sì mọ̀ pé ẹ̀yin pẹ̀lú ní Olúwa kan ní ọ̀run. Ẹ fi ara yín jì fún àdúrà gbígbà, kí ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì máa dúpẹ́; Ẹ máa gbàdúrà fún wa pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè ṣí ìlẹ̀kùn fún wa fún ọ̀rọ̀ náà, láti máa sọ ohun ìjìnlẹ̀ Kristi, nítorí èyí tí mo ṣe wà nínú ìdè pẹ̀lú: Ẹ gbàdúrà pé kí èmi le è máa kéde rẹ̀ kedere gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi. Ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti bí ẹ ti ń ṣe pẹ̀lú àwọn tí ń bẹ lóde, kí ẹ sì máa ṣe ṣí àǹfààní tí ẹ bá nílò. Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kí ó dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó le mọ́ bí ẹ̀yin ó tí máa dá olúkúlùkù ènìyàn lóhùn. Gbogbo bí nǹkan ti rí fún mi ní Tikiku yóò jẹ́ kí ẹ mọ̀. Òun jẹ́ arákùnrin olùfẹ́ àti olóòtítọ́ ìránṣẹ́ àti ẹlẹgbẹ́ nínú Olúwa: Ẹni tí èmí ń rán sí yín nítorí èyí kan náà, kí ẹ̀yin lè mọ́ bí a ti wà, kí òun kí ó lè tu ọkàn yín nínú; Òun sì ń bọ̀ pẹ̀lú Onesimu, arákùnrin olóòtítọ́ àti olùfẹ́, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú yín. Àwọn ní yóò sọ ohun gbogbo tí à ń ṣe níhìn-ín-yìí fún un yín. Aristarku, ẹlẹgbẹ́ mí nínú túbú kí i yín, àti Marku, ọmọ arábìnrin Barnaba (Nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ti gba àṣẹ; bí ó bá sì wá sí ọ̀dọ̀ yín, ẹ gbà á). Àti Jesu, ẹni tí à ń pè ní Justu, ẹni tí ń ṣe ti àwọn onílà. Àwọn wọ̀nyí nìkan ni olùbáṣiṣẹ́ mí fún ìjọba Ọlọ́run, àwọn ẹni tí ó tí jásí ìtùnú fún mi. Epafira, ẹni tí ń ṣe ọ̀kan nínú yín àti ìránṣẹ́ Kristi Jesu kí i yín. Òun fi ìwàyáàjà gbàdúrà nígbà gbogbo fún un yín, kí ẹ̀yin kí ó lè dúró ní pípé nínú ohun gbogbo nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. Nítorí mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ń ṣiṣẹ́ kárakára fún yín, àti fún àwọn tí ó wà ní Laodikea, àti àwọn tí ó wà ní Hirapoli. Luku, arákùnrin wa ọ̀wọ́n, oníṣègùn, àti Dema ki í yín. Ẹ kí àwọn ará tí ó wà ní Laodikea, àti Nimpa, àti ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀. Nígbà tí a bá sì ka ìwé yìí ní àárín yín tan, kí ẹ mú kí a kà á pẹ̀lú nínú ìjọ Laodikea; ẹ̀yin pẹ̀lú sì ka èyí tí ó ti Laodikea wá. Kí ẹ sì wí fún Arkippu pe, “Kíyèsi iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ìwọ ti gbà nínú Olúwa kí o sì ṣe é ní kíkún.” Ìkíni láti ọwọ́ èmi Paulu. Ẹ máa rántí ìdè mi. Kí oore-ọ̀fẹ́ kí ó wà pẹ̀lú yín.

Kol 4:1-18

Kol 4:1-18 YBCVKol 4:1-18 YBCVKol 4:1-18 YBCVKol 4:1-18 YBCV