Kol 4:1-18
ẸNYIN oluwa, ẹ ma fi eyiti o tọ́ ti o si dọgba fun awọn ọmọ-ọdọ nyin; ki ẹ si mọ̀ pe ẹnyin pẹlu ni Oluwa kan li ọrun. Ẹ mã duro ṣinṣin ninu adura igbà, ki ẹ si mã ṣọra ninu rẹ̀ pẹlu idupẹ; Ju gbogbo rẹ̀, ẹ mã gbadura fun wa pẹlu, ki Ọlọrun le ṣí ilẹkun fun wa fun ọrọ na, lati mã sọ ohun ijinlẹ Kristi, nitori eyiti mo ṣe wà ninu ìde pẹlu: Ki emi ki o le fihan, gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati mã sọ. Ẹ mã rìn nipa ọgbọ́n si awọn ti mbẹ lode, ki ẹ si mã ṣe ìrapada ìgba. Ẹ jẹ ki ọ̀rọ nyin ki o dàpọ mọ́ ore-ọfẹ nigbagbogbo, eyiti a fi iyọ̀ dùn, ki ẹnyin ki o le mọ̀ bi ẹnyin ó ti mã dá olukuluku enia lohùn. Gbogbo bi nkan ti ri fun mi ni Tikiku yio jẹ́ ki ẹ mọ̀, arakunrin olufẹ ati olõtọ iranṣẹ, ati ẹlẹgbẹ ninu Oluwa: Ẹniti mo ti rán si nyin nitori eyi kanna, ki ẹnyin le mọ̀ bi a ti wà, ki on ki o le tù ọkàn nyin ninu; Pẹlu Onesimu, arakunrin olõtọ ati olufẹ, ẹniti iṣe ọ̀kan ninu nyin. Awọn ni yio sọ ohun gbogbo ti a nṣe nihinyi fun nyin. Aristarku, ẹlẹgbẹ mi ninu tubu ki nyin, ati Marku, ọmọ arabinrin Barnaba (nipasẹ ẹniti ẹnyin ti gbà aṣẹ: bi o ba si wá sọdọ nyin, ẹ gbà a), Ati Jesu, ẹniti a npè ni Justu, ẹniti iṣe ti awọn onila. Awọn wọnyi nikan ni olubaṣiṣẹ mi fun ijọba Ọlọrun, awọn ẹniti o ti jasi itunu fun mi. Epafra, ẹniti iṣe ọkan ninu nyin, iranṣẹ Kristi, kí nyin, on nfi iwaya-ija gbadura nigbagbogbo fun nyin, ki ẹnyin ki o le duro ni pipé ati ni kíkun ninu gbogbo ifẹ Ọlọrun. Nitori mo jẹri rẹ̀ pe, o ni itara pupọ fun nyin, ati fun awọn ti o wà ni Laodikea, ati awọn ti o wà ni Hierapoli. Luku, oniṣegun olufẹ, ati Dema ki nyin. Ẹ kí awọn ará ti o wà ni Laodikea, ati Nimfa, ati ijọ ti o wà ni ile rẹ̀. Nigbati a ba si kà iwe yi larin nyin tan, ki ẹ mu ki a kà a pẹlu ninu ìjọ Laodikea; ki ẹnyin pẹlu si kà eyi ti o ti Laodikea wá. Ki ẹ si wi fun Arkippu pe, Kiyesi iṣẹ-iranṣẹ ti iwọ ti gbà ninu Oluwa, ki o si ṣe e ni kikún. Ikíni nipa ọwọ́ emi Paulu. Ẹ mã ranti ìde mi. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu nyin. Amin.
Kol 4:1-18