Kol 3:18-21
Kol 3:18-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin aya, ẹ mã tẹriba fun awọn ọkọ nyin, gẹgẹ bi o ti yẹ ninu Oluwa. Ẹnyin ọkọ, ẹ mã fẹran awọn aya nyin, ẹ má si ṣe korò si wọn. Ẹnyin ọmọ, ẹ mã gbọ ti awọn õbi nyin li ohun gbogbo: nitori eyi dara gidigidi ninu Oluwa. Ẹnyin baba, ẹ máṣe mu awọn ọmọ nyin binu, ki nwọn má bã rẹwẹsi.
Kol 3:18-21 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin aya, ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ kí onigbagbọ máa ṣe. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín. Ẹ má ṣe kanra mọ́ wọn. Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu ninu ohun gbogbo, nítorí ohun tí ó wu Oluwa nìyí. Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe rorò mọ́ àwọn ọmọ yín, kí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn má baà bá wọn.
Kol 3:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ nínú Olúwa. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fẹ́ràn àwọn aya yín, ẹ má sì ṣe korò sí wọn. Ẹ̀yin ọmọ ẹ máa gbọ́ ti àwọn òbí yín ní ohun gbogbo: nítorí èyí dára gidigidi nínú Olúwa. Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, kí wọn má bà á rẹ̀wẹ̀sì.