Kol 3:15-16
Kol 3:15-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ si jẹ ki alafia Ọlọrun ki o mã ṣe akoso ọkàn nyin, sinu eyiti a pè nyin pẹlu ninu ara kan; ki ẹ si ma dupẹ. Ẹ jẹ ki ọ̀rọ Kristi mã gbé inu nyin li ọ̀pọlọpọ ninu ọgbọ́n gbogbo; ki ẹ mã kọ́, ki ẹ si mã gbà ara nyin niyanju ninu psalmu, ati orin iyìn, ati orin ẹmí, ẹ mã fi ore-ọfẹ kọrin li ọkàn nyin si Oluwa.
Kol 3:15-16 Yoruba Bible (YCE)
Kí alaafia láti ọ̀dọ̀ Kristi máa ṣe alákòóso ọkàn yín; nítorí Ọlọrun pè yín láti jẹ́ ara kan nítorí alaafia yìí, ẹ sì máa ṣọpẹ́. Kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Kí ẹ máa fi gbogbo ọgbọ́n kọ́ ara yín, kí ẹ máa fún ara yín ní ìwúrí nípa kíkọ Orin Dafidi, ati orin ìyìn ati orin àtọkànwá. Ẹ máa kọrin sí Ọlọrun pẹlu ọpẹ́ ninu ọkàn yín.
Kol 3:15-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà Ọlọ́run kí ó máa ṣe àkóso ọkàn yín, sínú èyí tí a pè yín pẹ̀lú nínú ara kan; kí ẹ sì máa dúpẹ́. Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo; kí ẹ máa kọ́ ọ, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa kọrin sí Ọlọ́run ní ọkàn ọpẹ́.