Kol 3:1-14

Kol 3:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)

NJẸ bi a ba ti ji nyin dide pẹlu Kristi, ẹ mã ṣafẹri awọn nkan ti mbẹ loke, nibiti Kristi gbé wà ti o joko li ọwọ́ ọtun Ọlọrun. Ẹ mã ronu awọn nkan ti mbẹ loke kì iṣe awọn nkan ti mbẹ li aiye. Nitori ẹnyin ti kú, a si fi ìye nyin pamọ́ pẹlu Kristi ninu Ọlọrun. Nigbati Kristi, ẹniti iṣe ìye wa yio farahàn, nigbana li ẹnyin pẹlu o farahàn pẹlu rẹ̀ ninu ogo. Nitorina ẹ mã pa ẹ̀ya-ara nyin ti mbẹ li aiye run: àgbere, iwa-ẽri, ifẹkufẹ, ifẹ buburu, ati ojukòkoro, ti iṣe ibọriṣa: Nitori ohun tí ibinu Ọlọrun fi mbọ̀wa sori awọn ọmọ alaigbọran. Ninu eyiti ẹnyin pẹlu ti nrìn nigbakan rí, nigbati ẹnyin ti wà ninu nkan wọnyi. Ṣugbọn nisisiyi, ẹ fi gbogbo wọnyi silẹ pẹlu; ibinu, irunu, arankàn, ọrọ-odi, ati ọrọ itiju kuro li ẹnu nyin. Ẹ má si ṣe purọ́ fun ẹnikeji nyin, ẹnyin sa ti bọ́ ogbologbo ọkunrin nì silẹ pẹlu iṣe rẹ̀; Ẹ si ti gbé ọkunrin titun nì wọ̀, eyiti a sọ di titun si ìmọ gẹgẹ bi aworan ẹniti o da a: Nibiti kò le si Hellene ati Ju, ikọla ati aikọla, alaigbede, ara Skitia, ẹrú ati omnira: ṣugbọn Kristi li ohun gbogbo, ninu ohun gbogbo. Nitorina, bi ayanfẹ Ọlọrun, ẹni mimọ́ ati olufẹ, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nu wọ̀, iṣeun, irẹlẹ, inu tutù, ipamọra; Ẹ mã farada a fun ara nyin, ẹ si mã dariji ara nyin bi ẹnikẹni bá ni ẹ̀sun si ẹnikan: bi Kristi ti darijì nyin, gẹgẹ bẹ̃ni ki ẹnyin ki o mã ṣe pẹlu. Ati bori gbogbo nkan wọnyi, ẹ gbé ifẹ wọ̀, ti iṣe àmure ìwa pipé.

Kol 3:1-14 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí náà, bí a bá ti ji yín dìde pẹlu Kristi, ẹ máa lépa àwọn ohun tí ó wà lọ́run níbi tí Kristi wà, tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun. Ẹ máa lépa àwọn ohun tí ó wà lọ́run, ẹ má lépa àwọn ohun tí ó wà láyé. Nítorí ẹ ti kú, ẹ̀mí yín wà ní ìpamọ́ pẹlu Kristi ninu Ọlọrun. Nígbà tí Kristi, ẹni tíí ṣe ẹ̀mí yín bá farahàn, ẹ̀yin náà yóo farahàn pẹlu rẹ̀ ninu ògo. Nítorí náà, ẹ pa àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀yà ara yín ti ayé run: àwọn bíi àgbèrè, ìwà èérí, ìṣekúṣe, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ati ojúkòkòrò tíí ṣe ìbọ̀rìṣà. Nítorí nǹkan wọnyi ni ibinu Ọlọrun ṣe ń bọ̀. Ẹ̀yin náà ti wà lára irú àwọn eniyan wọnyi nígbà kan rí, nígbà tí ẹ̀yin náà ń ṣe nǹkan wọnyi. Ṣugbọn ní àkókò yìí, ẹ pa gbogbo àwọn nǹkan wọnyi tì: ibinu, inúfùfù, ìwà burúkú, ìsọkúsọ, ọ̀rọ̀ ìtìjú. Ẹ má purọ́ fún ara yín, nígbà tí ẹ ti bọ́ ara àtijọ́ sílẹ̀ pẹlu iṣẹ́ rẹ̀, tí ẹ ti gbé ẹ̀dá titun wọ̀. Èyí ni ẹ̀dá tí ó túbọ̀ ń di titun siwaju ati siwaju gẹ́gẹ́ bí àwòrán ẹni tí ó dá a, tí ó ń mú kí eniyan ní ìmọ̀ Ọlọrun. Ninu ipò titun yìí, kò sí pé ẹnìkan ni Giriki, ẹnìkan ni Juu; tabi pé ẹnìkan kọlà, ẹnìkan kò kọlà, ẹnìkan aláìgbédè, ẹnìkan ẹlẹ́nu òdì, ẹnìkan ẹrú, ẹnìkan òmìnira. Nítorí Kristi ni ohun gbogbo, tí ó wà ninu ohun gbogbo. Nítorí náà, ẹ gbé àánú wọ̀ bí ẹ̀wù, ati inú rere, ìrẹ̀lẹ̀, ìwà pẹ̀lẹ́ ati sùúrù, bí ó ti yẹ àwọn ẹni tí Ọlọrun yàn, tí wọ́n sì jẹ́ eniyan Ọlọrun ati àyànfẹ́ rẹ̀. Ẹ ní ìfaradà láàrin ara yín. Ẹ máa dáríjì ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn kan sí ẹnìkejì rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí Oluwa ti dáríjì yín bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí ara yín. Boríborí gbogbo nǹkan wọnyi, ni pé kí ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀. Ìfẹ́ ni ó so àwọn nǹkan yòókù pọ̀, tí ó sì mú wọn pé.

Kol 3:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Níwọ́n ìgbà tí a ti jí yín dìde pẹ̀lú Kristi ẹ máa ṣàfẹ́rí àwọn nǹkan tí ń bẹ lókè, níbi tí Kristi gbé wà tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Ẹ máa ronú àwọn ohun tí ń bẹ lókè kì í ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ ní ayé. Nítorí ẹ̀yin ti kú, a sì fi ìyè yín pamọ́ pẹ̀lú Kristi nínú Ọlọ́run. Nígbà tí Kristi, ẹni tí í ṣe ìyè yín yóò farahàn, nígbà náà ni ẹ̀yin pẹ̀lú yóò farahàn pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo. Ẹ máa pa ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ ní ayé run: àgbèrè, panṣágà, ìwà àìmọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwọra, nítorí pé ìwọ̀nyí jásí ìbọ̀rìṣà. Lórí àwọn wọ̀nyí ni ìbínú Ọlọ́run ń bọ̀ wá. Ẹ máa ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀ nígbà tí ìgbé ayé yín sì jẹ́ apá kan ayé yìí. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ gbọdọ̀ fi àwọn wọ̀nyí sílẹ̀: ìbínú, ìrunú, àrankàn, fífi ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ àti ọ̀rọ̀ èérí kúrò ní ètè yín. Ẹ má ṣe purọ́ fún ara yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti bọ́ ògbólógbòó ara yín pẹ̀lú ìṣe rẹ̀ sílẹ̀, tí ẹ sì ti gbé ìgbé ayé tuntun wọ̀, èyí tí a sọ di tuntun nínú ìmọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán ẹni tí ó dá a. Níbi tí kò gbé sí Giriki tàbí Júù, ìkọlà tàbí aláìkọlà, aláìgbédè, ara Skitia, ẹrú tàbí òmìnira, ṣùgbọ́n Kristi ni ohun gbogbo nínú ohun gbogbo. Nítorí náà, bí àyànfẹ́ Ọlọ́run, ẹni mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nú wọ̀, ìṣoore, ìrẹ̀lẹ̀, inú tútù àti sùúrù. Ẹ máa fi ara dà á fún ara yín, ẹ sì máa dáríjì ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkan: bí Kristi ti dáríjì yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó máa ṣe pẹ̀lú. Àti borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tí í ṣe àmùrè ìwà pípé.

Kol 3:1-14

Kol 3:1-14 YBCVKol 3:1-14 YBCVKol 3:1-14 YBCVKol 3:1-14 YBCV