Kol 3:1-11

Kol 3:1-11 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí náà, bí a bá ti ji yín dìde pẹlu Kristi, ẹ máa lépa àwọn ohun tí ó wà lọ́run níbi tí Kristi wà, tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun. Ẹ máa lépa àwọn ohun tí ó wà lọ́run, ẹ má lépa àwọn ohun tí ó wà láyé. Nítorí ẹ ti kú, ẹ̀mí yín wà ní ìpamọ́ pẹlu Kristi ninu Ọlọrun. Nígbà tí Kristi, ẹni tíí ṣe ẹ̀mí yín bá farahàn, ẹ̀yin náà yóo farahàn pẹlu rẹ̀ ninu ògo. Nítorí náà, ẹ pa àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀yà ara yín ti ayé run: àwọn bíi àgbèrè, ìwà èérí, ìṣekúṣe, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ati ojúkòkòrò tíí ṣe ìbọ̀rìṣà. Nítorí nǹkan wọnyi ni ibinu Ọlọrun ṣe ń bọ̀. Ẹ̀yin náà ti wà lára irú àwọn eniyan wọnyi nígbà kan rí, nígbà tí ẹ̀yin náà ń ṣe nǹkan wọnyi. Ṣugbọn ní àkókò yìí, ẹ pa gbogbo àwọn nǹkan wọnyi tì: ibinu, inúfùfù, ìwà burúkú, ìsọkúsọ, ọ̀rọ̀ ìtìjú. Ẹ má purọ́ fún ara yín, nígbà tí ẹ ti bọ́ ara àtijọ́ sílẹ̀ pẹlu iṣẹ́ rẹ̀, tí ẹ ti gbé ẹ̀dá titun wọ̀. Èyí ni ẹ̀dá tí ó túbọ̀ ń di titun siwaju ati siwaju gẹ́gẹ́ bí àwòrán ẹni tí ó dá a, tí ó ń mú kí eniyan ní ìmọ̀ Ọlọrun. Ninu ipò titun yìí, kò sí pé ẹnìkan ni Giriki, ẹnìkan ni Juu; tabi pé ẹnìkan kọlà, ẹnìkan kò kọlà, ẹnìkan aláìgbédè, ẹnìkan ẹlẹ́nu òdì, ẹnìkan ẹrú, ẹnìkan òmìnira. Nítorí Kristi ni ohun gbogbo, tí ó wà ninu ohun gbogbo.

Kol 3:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Níwọ́n ìgbà tí a ti jí yín dìde pẹ̀lú Kristi ẹ máa ṣàfẹ́rí àwọn nǹkan tí ń bẹ lókè, níbi tí Kristi gbé wà tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Ẹ máa ronú àwọn ohun tí ń bẹ lókè kì í ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ ní ayé. Nítorí ẹ̀yin ti kú, a sì fi ìyè yín pamọ́ pẹ̀lú Kristi nínú Ọlọ́run. Nígbà tí Kristi, ẹni tí í ṣe ìyè yín yóò farahàn, nígbà náà ni ẹ̀yin pẹ̀lú yóò farahàn pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo. Ẹ máa pa ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ ní ayé run: àgbèrè, panṣágà, ìwà àìmọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwọra, nítorí pé ìwọ̀nyí jásí ìbọ̀rìṣà. Lórí àwọn wọ̀nyí ni ìbínú Ọlọ́run ń bọ̀ wá. Ẹ máa ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀ nígbà tí ìgbé ayé yín sì jẹ́ apá kan ayé yìí. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ gbọdọ̀ fi àwọn wọ̀nyí sílẹ̀: ìbínú, ìrunú, àrankàn, fífi ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ àti ọ̀rọ̀ èérí kúrò ní ètè yín. Ẹ má ṣe purọ́ fún ara yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti bọ́ ògbólógbòó ara yín pẹ̀lú ìṣe rẹ̀ sílẹ̀, tí ẹ sì ti gbé ìgbé ayé tuntun wọ̀, èyí tí a sọ di tuntun nínú ìmọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán ẹni tí ó dá a. Níbi tí kò gbé sí Giriki tàbí Júù, ìkọlà tàbí aláìkọlà, aláìgbédè, ara Skitia, ẹrú tàbí òmìnira, ṣùgbọ́n Kristi ni ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.

Kol 3:1-11

Kol 3:1-11 YBCVKol 3:1-11 YBCVKol 3:1-11 YBCVKol 3:1-11 YBCV