Iṣe Apo 5:17-42

Iṣe Apo 5:17-42 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ṣugbọn olori alufa dide, ti on ti gbogbo awọn ti nwọn wà lọdọ rẹ̀ (ti iṣe ẹya ti awọn Sadusi), nwọn si kún fun owu. Nwọn si nawọ́ mu awọn aposteli, nwọn si fi wọn sinu tubu. Ṣugbọn angẹli Oluwa ṣí ilẹkun tubu li oru; nigbati o si mu wọn jade, o wipe, Ẹ lọ, ẹ duro, ki ẹ si mã sọ gbogbo ọ̀rọ iye yi fun awọn enia ni tẹmpili. Nigbati nwọn si gbọ́ yi, nwọn wọ̀ tẹmpili lọ ni kutukutu, nwọn si nkọ́ni. Ṣugbọn olori alufa de, ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀, nwọn si pè apejọ igbimọ, ati gbogbo awọn agbàgba awọn ọmọ Israeli, nwọn si ranṣẹ si ile tubu lati mu wọn wá. Ṣugbọn nigbati awọn onṣẹ de ibẹ̀, nwọn kò si ri wọn ninu tubu, nwọn pada wá, nwọn si sọ pe, Awa bá ile tubu o sé pinpin, ati awọn oluṣọ duro lode niwaju ilẹkun: ṣugbọn nigbati awa ṣílẹkun, awa kò bá ẹnikan ninu tubu. Nigbati olori ẹṣọ́ tẹmpili ati awọn olori alufa si gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, nwọn dãmu nitori wọn pe, nibo li eyi ó yọri si. Nigbana li ẹnikan de, o wi fun wọn pe, Wo o, awọn ọkunrin ti ẹnyin fi sinu tubu wà ni tẹmpili, nwọn duro nwọn si nkọ́ awọn enia. Nigbana li olori ẹṣọ́ lọ pẹlu awọn onṣẹ, o si mu wọn wá kì iṣe pẹlu ipa: nitoriti nwọn bẹ̀ru awọn enia, ki a má ba sọ wọn li okuta. Nigbati nwọn si mu wọn de, nwọn mu wọn duro niwaju ajọ igbimọ; olori alufa si bi wọn lẽre, Wipe, Awa kò ti kìlọ fun nyin gidigidi pe, ki ẹ maṣe fi orukọ yi kọ́ni mọ́? si wo o, ẹnyin ti fi ẹkọ́ nyin kún Jerusalemu, ẹ si npete ati mu ẹ̀jẹ ọkunrin yi wá si ori wa. Ṣugbọn Peteru ati awọn aposteli dahùn, nwọn si wipe, Awa kò gbọdọ má gbọ́ ti Ọlọrun jù ti enia lọ. Ọlọrun awọn baba wa ji Jesu dide, ẹniti ẹnyin pa, tí ẹnyin si gbe kọ́ sori igi. On li Ọlọrun fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ gbéga lati jẹ Ọmọ alade ati Olugbala, lati fi ironupiwada fun Israeli, ati idariji ẹ̀ṣẹ. Awa si li ẹlẹri nkan wọnyi; ati Ẹmí Mimọ́ pẹlu, ti Ọlọrun fifun awọn ti o gbọ́ tirẹ̀. Ṣugbọn nigbati nwọn gbọ́ eyi, àiya wọn gbà ọgbẹ́ de inu, nwọn gbèro ati pa wọn. Ṣugbọn ọkan ninu ajọ igbimọ, ti a npè ni Gamalieli, Farisi ati amofin, ti o ni iyìn gidigidi lọdọ gbogbo enia, o dide duro, o ni ki a mu awọn aposteli bì sẹhin diẹ; O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ọkunrin Israeli, ẹ kiyesi ara nyin li ohun ti ẹnyin npete ati ṣe si awọn ọkunrin wọnyi. Nitori ṣaju ọjọ wọnyi ni Teuda dide, o nwipe ẹni nla kan li on; ẹniti ìwọn irinwo ọkunrin gbatì: ẹniti a pa; ati gbogbo iye awọn ti o gbà tirẹ̀, a tú wọn ká, a si sọ wọn di asan. Lẹhin ọkunrin yi ni Juda ti Galili dide lakoko kikà enia, o si fà enia pipọ lẹhin rẹ̀: on pẹlu ṣegbé; ati gbogbo iye awọn ti o gbà tirẹ̀, a fọn wọn ká. Njẹ emi wi fun nyin nisisiyi, Ẹ gafara fun awọn ọkunrin wọnyi, ki ẹ si jọwọ wọn jẹ: nitori bi ìmọ tabi iṣẹ yi ba jẹ ti enia, a o bì i ṣubu: Ṣugbọn bi ti Ọlọrun ba ni, ẹnyin kì yio le bì i ṣubu; ki o ma ba jẹ pe, a ri nyin ẹ mba Ọlọrun jà. Nwọn si tẹ̀ si tirẹ̀: nigbati nwọn si pè awọn aposteli wọle, nwọn lù wọn, nwọn si kìlọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ̀rọ li orukọ Jesu mọ́, nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ. Nitorina nwọn si lọ kuro niwaju ajọ igbimọ: nwọn nyọ̀ nitori ti a kà wọn yẹ si ìya ijẹ nitori orukọ rẹ̀. Ati li ojojumọ́ ni tẹmpili ati ni ile, nwọn kò dẹkun ikọ́ni, ati lati wasu Jesu Kristi.

Iṣe Apo 5:17-42 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà náà ni ẹ̀tanú gba ọkàn Olórí Alufaa ati gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Sadusi tí ó wà pẹlu rẹ̀. Wọ́n bá mú àwọn aposteli, wọ́n tì wọ́n mọ́lé ninu ilé ẹ̀wọ̀n ìgboro ìlú. Nígbà tí ó di òru, angẹli Oluwa ṣí ìlẹ̀kùn ilé-ẹ̀wọ̀n, ó sìn wọ́n jáde, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ dúró ninu Tẹmpili kí ẹ sọ gbogbo ọ̀rọ̀ ìyè yìí fún àwọn eniyan.” Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n wọ inú Tẹmpili lọ nígbà tí ojúmọ́ mọ́, wọ́n bá ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí Olórí Alufaa dé pẹlu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó pe ìgbìmọ̀ ati gbogbo àwọn àgbààgbà láàrin àwọn ọmọ Israẹli jọ. Wọ́n bá ranṣẹ lọ sí inú ẹ̀wọ̀n kí wọn lọ mú àwọn aposteli náà wá. Nígbà tí àwọn tí wọ́n rán dé ilé-ẹ̀wọ̀n, wọn kò rí wọn níbẹ̀. Wọ́n bá pada lọ jíṣẹ́ pé, “A fojú wa rí ilé-ẹ̀wọ̀n ní títì, a bá àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọ tí wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà. Ṣugbọn nígbà tí a ṣílẹ̀kùn, tí a wọ inú ilé, a kò rí ẹnìkan.” Nígbà tí ọ̀gá àwọn ẹ̀ṣọ́ ti Tẹmpili ati àwọn olórí alufaa gbọ́ ìròyìn yìí, ọkàn wọn dàrú; wọ́n ń ronú pé, irú kí ni eléyìí? Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹnìkan bá dé, wọ́n sọ fún wọn pé, “Àwọn ọkunrin tí ẹ tì mọ́lé wà ninu Tẹmpili, tí wọn ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́.” Nígbà náà ni ọ̀gá àwọn ẹ̀ṣọ́ ati àwọn iranṣẹ lọ mú àwọn aposteli. Àwọn ẹ̀ṣọ́ náà kò fi ipá mú wọn, nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan kí àwọn eniyan má baà sọ wọ́n ní òkúta. Wọ́n mú wọn wá siwaju ìgbìmọ̀. Olórí Alufaa wá bi wọ́n pé, “Mo ṣebí a pàṣẹ fun yín pé kí ẹ má fi orúkọ yìí kọ́ ẹnikẹ́ni mọ́? Sibẹ gbogbo ará Jerusalẹmu ni ó ti gbọ́ nípa ẹ̀kọ́ yín yìí. Ẹ wá tún di ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkunrin yìí lé wa lórí?” Peteru pẹlu àwọn aposteli dáhùn pé, “A níláti gbọ́ ti Ọlọrun ju ti eniyan lọ. Jesu tí ẹ̀yin pa, tí ẹ kàn mọ́ igi, Ọlọrun àwọn baba wa jí i dìde. Òun ni Ọlọrun fi ṣe aṣiwaju ati olùgbàlà, tí ó gbé sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, kí ó lè fi anfaani ìrònúpìwàdà ati ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún Israẹli. Àwa gan-an ati Ẹ̀mí Mímọ́ tí Ọlọrun fi fún àwọn tí ó gbọ́ràn sí i lẹ́nu ni ẹlẹ́rìí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi.” Ọ̀rọ̀ yìí gún àwọn tí ó gbọ́ ọ lọ́kàn tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fẹ́ pa wọ́n. Ṣugbọn Farisi kan ninu àwọn ìgbìmọ̀ dìde. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gamalieli, olùkọ́ nípa ti òfin ni, ó lókìkí láàrin gbogbo àwọn eniyan. Ó ní kí àwọn ọkunrin náà jáde fún ìgbà díẹ̀. Ó wá sọ fún àwọn ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ṣọ́ra nípa ohun tí ẹ fẹ́ ṣe sí àwọn ọkunrin yìí. Nítorí nígbà kan, Tudasi kan dìde. Ó ní òun jẹ́ eniyan ńlá kan. Ó kó àwọn eniyan bí irinwo (400) jọ. Nígbà tó yá wọ́n pa á, wọ́n sì tú gbogbo àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ká; gbogbo ọ̀tẹ̀ rẹ̀ sì jásí òfo. Lẹ́yìn èyí, Judasi kan, ará Galili, dìde ní àkókò tí à ń kọ orúkọ àwọn eniyan sílẹ̀. Àwọn eniyan tẹ̀lé e. Ṣugbọn wọ́n pa á, wọ́n sì tú gbogbo àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ká. To ò, mo sọ fun yín o! Ẹ gáfárà fún àwọn ọkunrin yìí; ẹ fi wọ́n sílẹ̀ o! Bí ète yìí tabi ohun tí wọn ń ṣe bá jẹ́ láti ọwọ́ eniyan, yóo parẹ́. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ láti ọwọ́ Ọlọrun ni, ẹ kò lè pa wọ́n run, ẹ óo kàn máa bá Ọlọrun jagun ni!” Àwọn ìgbìmọ̀ rí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n bá pe àwọn aposteli wọlé, wọ́n nà wọ́n, wọ́n kìlọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ fi orúkọ Jesu sọ̀rọ̀ mọ́. Wọ́n bá dá wọn sílẹ̀. Wọ́n jáde kúrò níwájú ìgbìmọ̀, wọ́n ń yọ̀ nítorí a kà wọ́n yẹ kún àwọn tí a fi àbùkù kan nítorí orúkọ Jesu. Lojoojumọ, ninu Tẹmpili ati láti ilé dé ilé, wọn kò dẹ́kun láti máa kọ́ eniyan ati láti máa waasu pé Jesu ni Mesaya.

Iṣe Apo 5:17-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni ẹ̀mí owú gbígbóná gbé olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn tí wọn wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ì ṣe ẹ̀yà tí àwọn Sadusi wọ̀. Wọ́n sì nawọ́ mú àwọn aposteli wọn sì fi wọ́n sínú túbú. Ṣùgbọ́n ní òru, angẹli Olúwa ṣí ìlẹ̀kùn túbú; ó sì mú wọn jáde. Ó sì wí pé “Ẹ lọ dúró nínú tẹmpili kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ìyè yìí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ fún àwọn ènìyàn.” Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ èyí, wọ́n wọ tẹmpili lọ ní kùtùkùtù, wọ́n sì ń kọ́ni. Nígbà tí olórí àlùfáà àti àwọn ti ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ dé, wọn sì pè àpéjọ ìgbìmọ̀, àti gbogbo àwọn àgbàgbà àwọn ọmọ Israẹli, wọn sì ránṣẹ́ sí ilé túbú láti mú àwọn aposteli wá. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olùṣọ́ dé ibẹ̀ wọn kò sì rí wọn nínú túbú, wọn padà wá, wọn sísọ fún wọn pé, “Àwa bá ilé túbú ni títí pinpin, àti àwọn olùṣọ́ dúró lóde níwájú ìlẹ̀kùn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwa ṣí ìlẹ̀kùn, àwa kò bá ẹnìkan nínú túbú.” Nígbà tí olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili àti àwọn olórí àlùfáà sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n dààmú nítorí wọn kò mọ ibi tí ọ̀rọ̀ yìí yóò yọrí sí. Nígbà náà ni ẹnìkan dé, ó wí fún wọn pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin tí ẹ̀yin fi sínú túbú wà ní tẹmpili, wọn dúró wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn.” Nígbà náà ni olórí ẹ̀ṣọ́ lọ pẹ̀lú àwọn olùṣọ́, ó sì mú àwọn aposteli wá. Wọn kò fi ipá mú wọn, nítorí tí wọn bẹ̀rù àwọn ènìyàn kí a má ba à sọ wọ́n ní òkúta. Nígbà tí wọn sì mú àwọn aposteli dé, wọn mú wọn dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀; olórí àlùfáà sì bi wọ́n léèrè. Ó wí pé, “Àwa kò ha ti kìlọ̀ fún un yín gidigidi pé, kí ẹ má ṣe fi orúkọ yìí kọ́ni, síbẹ̀ ẹ̀yin ti fi ìkọ́ni yín kún Jerusalẹmu, ẹ sì ń pète àti mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí wá sí orí wá.” Ṣùgbọ́n Peteru àti àwọn aposteli dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Àwa kò gbọdọ̀ má gbọ́ tí Ọlọ́run ju ti ènìyàn lọ! Ọlọ́run àwọn baba wa jí Jesu dìde kúrò ní ipò òkú, ẹni tí ẹ̀yin pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi. Òun ni Ọlọ́run fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé gẹ́gẹ́ bí Ọmọ-aládé àti Olùgbàlà láti fi ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún Israẹli. Àwa sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí, àti gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti ṣe ẹlẹ́rìí pẹ̀lú, tí Ọlọ́run fi fún àwọn tí ó gbà á gbọ́.” Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọ́n gbèrò láti pa wọ́n. Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àjọ ìgbìmọ̀, tí a ń pè ni Gamalieli, Farisi àti amòfin, tí ó ní ìyìn gidigidi lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, ó dìde dúró, ó ni kí a mú àwọn aposteli bì sẹ́yìn díẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ kíyèsi ara yín lóhùn tí ẹ̀yin ń pète láti ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí. Nítorí ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí ni Teuda dìde, ó ń wí pé, ẹni ńlá kan ní òun; ẹni tí ìwọ̀n irínwó ọkùnrin dara wọn pọ̀ mọ́; ṣùgbọ́n a pa á; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ sì túká, tí wọn sí di asán. Lẹ́yìn ọkùnrin yìí ni Judasi ti Galili dìde ni àkókò kíka àwọn ènìyàn, ó sì ni ẹni púpọ̀ lẹ́yìn rẹ̀; òun pẹ̀lú ṣègbé; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ ni a fọ́nká. Ǹjẹ́ èmi wí fún un yín nísinsin yìí, ṣọ́ra fún àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, kí ẹ sí fi wọn sílẹ̀, nítorí bí ìmọ̀ tàbí iṣẹ́ yìí bá jẹ́ ti ènìyàn, a ó bì í ṣubú. Ṣùgbọ́n bí ti Ọlọ́run bá ní, ẹ̀yin kì yóò lè bì í ṣubú; kí ó má ba à jẹ́ pé, a rí yín bí ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà.” Wọ́n sì gbà ìmọ̀ràn rẹ̀. Wọn pe àwọn aposteli wọlé, wọ́n si lù wọ́n. Wọn sí kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ ni orúkọ Jesu mọ́, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn sílẹ̀ lọ. Nítorí náà wọn sì lọ kúrò níwájú àjọ ìgbìmọ̀; wọn ń yọ̀ nítorí tí a kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ rẹ̀. Ní ojoojúmọ́ nínú tẹmpili àti ni ojúlé dé ojúlé, wọn kò dẹ́kun kíkọ́ni àti láti wàásù ìhìnrere náà pé Jesu ni Kristi.