ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 5:17-42

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 5:17-42 YCE

Nígbà náà ni ẹ̀tanú gba ọkàn Olórí Alufaa ati gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Sadusi tí ó wà pẹlu rẹ̀. Wọ́n bá mú àwọn aposteli, wọ́n tì wọ́n mọ́lé ninu ilé ẹ̀wọ̀n ìgboro ìlú. Nígbà tí ó di òru, angẹli Oluwa ṣí ìlẹ̀kùn ilé-ẹ̀wọ̀n, ó sìn wọ́n jáde, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ dúró ninu Tẹmpili kí ẹ sọ gbogbo ọ̀rọ̀ ìyè yìí fún àwọn eniyan.” Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n wọ inú Tẹmpili lọ nígbà tí ojúmọ́ mọ́, wọ́n bá ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí Olórí Alufaa dé pẹlu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó pe ìgbìmọ̀ ati gbogbo àwọn àgbààgbà láàrin àwọn ọmọ Israẹli jọ. Wọ́n bá ranṣẹ lọ sí inú ẹ̀wọ̀n kí wọn lọ mú àwọn aposteli náà wá. Nígbà tí àwọn tí wọ́n rán dé ilé-ẹ̀wọ̀n, wọn kò rí wọn níbẹ̀. Wọ́n bá pada lọ jíṣẹ́ pé, “A fojú wa rí ilé-ẹ̀wọ̀n ní títì, a bá àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọ tí wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà. Ṣugbọn nígbà tí a ṣílẹ̀kùn, tí a wọ inú ilé, a kò rí ẹnìkan.” Nígbà tí ọ̀gá àwọn ẹ̀ṣọ́ ti Tẹmpili ati àwọn olórí alufaa gbọ́ ìròyìn yìí, ọkàn wọn dàrú; wọ́n ń ronú pé, irú kí ni eléyìí? Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹnìkan bá dé, wọ́n sọ fún wọn pé, “Àwọn ọkunrin tí ẹ tì mọ́lé wà ninu Tẹmpili, tí wọn ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́.” Nígbà náà ni ọ̀gá àwọn ẹ̀ṣọ́ ati àwọn iranṣẹ lọ mú àwọn aposteli. Àwọn ẹ̀ṣọ́ náà kò fi ipá mú wọn, nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan kí àwọn eniyan má baà sọ wọ́n ní òkúta. Wọ́n mú wọn wá siwaju ìgbìmọ̀. Olórí Alufaa wá bi wọ́n pé, “Mo ṣebí a pàṣẹ fun yín pé kí ẹ má fi orúkọ yìí kọ́ ẹnikẹ́ni mọ́? Sibẹ gbogbo ará Jerusalẹmu ni ó ti gbọ́ nípa ẹ̀kọ́ yín yìí. Ẹ wá tún di ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkunrin yìí lé wa lórí?” Peteru pẹlu àwọn aposteli dáhùn pé, “A níláti gbọ́ ti Ọlọrun ju ti eniyan lọ. Jesu tí ẹ̀yin pa, tí ẹ kàn mọ́ igi, Ọlọrun àwọn baba wa jí i dìde. Òun ni Ọlọrun fi ṣe aṣiwaju ati olùgbàlà, tí ó gbé sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, kí ó lè fi anfaani ìrònúpìwàdà ati ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún Israẹli. Àwa gan-an ati Ẹ̀mí Mímọ́ tí Ọlọrun fi fún àwọn tí ó gbọ́ràn sí i lẹ́nu ni ẹlẹ́rìí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi.” Ọ̀rọ̀ yìí gún àwọn tí ó gbọ́ ọ lọ́kàn tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fẹ́ pa wọ́n. Ṣugbọn Farisi kan ninu àwọn ìgbìmọ̀ dìde. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gamalieli, olùkọ́ nípa ti òfin ni, ó lókìkí láàrin gbogbo àwọn eniyan. Ó ní kí àwọn ọkunrin náà jáde fún ìgbà díẹ̀. Ó wá sọ fún àwọn ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ṣọ́ra nípa ohun tí ẹ fẹ́ ṣe sí àwọn ọkunrin yìí. Nítorí nígbà kan, Tudasi kan dìde. Ó ní òun jẹ́ eniyan ńlá kan. Ó kó àwọn eniyan bí irinwo (400) jọ. Nígbà tó yá wọ́n pa á, wọ́n sì tú gbogbo àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ká; gbogbo ọ̀tẹ̀ rẹ̀ sì jásí òfo. Lẹ́yìn èyí, Judasi kan, ará Galili, dìde ní àkókò tí à ń kọ orúkọ àwọn eniyan sílẹ̀. Àwọn eniyan tẹ̀lé e. Ṣugbọn wọ́n pa á, wọ́n sì tú gbogbo àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ká. To ò, mo sọ fun yín o! Ẹ gáfárà fún àwọn ọkunrin yìí; ẹ fi wọ́n sílẹ̀ o! Bí ète yìí tabi ohun tí wọn ń ṣe bá jẹ́ láti ọwọ́ eniyan, yóo parẹ́. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ láti ọwọ́ Ọlọrun ni, ẹ kò lè pa wọ́n run, ẹ óo kàn máa bá Ọlọrun jagun ni!” Àwọn ìgbìmọ̀ rí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n bá pe àwọn aposteli wọlé, wọ́n nà wọ́n, wọ́n kìlọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ fi orúkọ Jesu sọ̀rọ̀ mọ́. Wọ́n bá dá wọn sílẹ̀. Wọ́n jáde kúrò níwájú ìgbìmọ̀, wọ́n ń yọ̀ nítorí a kà wọ́n yẹ kún àwọn tí a fi àbùkù kan nítorí orúkọ Jesu. Lojoojumọ, ninu Tẹmpili ati láti ilé dé ilé, wọn kò dẹ́kun láti máa kọ́ eniyan ati láti máa waasu pé Jesu ni Mesaya.