Iṣe Apo 4:32-37
Iṣe Apo 4:32-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìjọ àwọn tí ó gbàgbọ́ sì wà ní ọkàn kan àti inú kan; kò sì ṣí ẹnìkan tí ó wí pé ohun kan nínú ohun ìní rẹ̀ jẹ́ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n gbogbo wọn ní ohun gbogbo ní ìṣọ̀kan. Agbára ńlá ni àwọn aposteli sì fi ń jẹ́rìí àjíǹde Jesu Olúwa, oore-ọ̀fẹ́ púpọ̀ sì wà lórí gbogbo wọn. Nítorí kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó ṣe aláìní, nítorí iye àwọn tí ó ní ilẹ̀ tàbí ilé tà wọ́n, wọ́n sì mú owó ohun tí wọn tà wá. Wọ́n sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli, wọn sì ń pín fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe aláìní sí. Àti Josẹfu, tí a ti ọwọ́ àwọn aposteli sọ àpèlé rẹ̀ ní Barnaba (ìtumọ̀ èyí tí ń jẹ Ọmọ-Ìtùnú), ẹ̀yà Lefi, àti ará Saipurọsi. Ó ní ilẹ̀ kan, ó tà á, ó mú owó rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli.
Iṣe Apo 4:32-37 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ijọ awọn ti o gbagbọ́ si wà li ọkàn kan ati inu kan: kò si si ẹnikan ti o pè ohun kan ninu ohun ini rẹ̀ ni ti ara rẹ̀: ṣugbọn gbogbo nwọn ni gbogbo nkan ṣọkan. Agbara nla li awọn aposteli si fi njẹri ajinde Jesu Oluwa; ore-ọfẹ pipọ si wà lori gbogbo wọn. Nitori kò si ẹnikan ninu wọn ti o ṣe alaini: nitori iye awọn ti o ni ilẹ tabi ile tà wọn, nwọn si mu owo ohun ti nwọn tà wá. Nwọn si fi i lelẹ li ẹsẹ awọn aposteli: nwọn si npín fun olukuluku, gẹgẹ bi o ti ṣe alaini si. Ati Josefu, ti a ti ọwọ awọn aposteli sọ apele rẹ̀ ni Barnaba (itumọ̀ eyi ti ijẹ Ọmọ-Itùnu), ẹ̀ya Lefi, ati ara Kipru. O ni ilẹ kan, o tà a, o mu owo rẹ̀ wá, o si fi i lelẹ li ẹsẹ awọn aposteli.
Iṣe Apo 4:32-37 Yoruba Bible (YCE)
Ọkàn kan ati ẹ̀mí kan ni gbogbo àwùjọ àwọn onigbagbọ ní. Kò sí ẹnìkan ninu wọn tí ó dá àwọn nǹkan tirẹ̀ yà sọ́tọ̀, wọ́n jọ ní gbogbo nǹkan papọ̀ ni. Àwọn aposteli ń fi ẹ̀rí wọn hàn pẹlu agbára ńlá nípa ajinde Jesu Oluwa. Gbogbo àwọn eniyan sì ń bọlá fún wọn. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ṣe aláìní ohun kan láàrin wọn. Àwọn tí ó ní ilẹ̀ tabi ilé tà wọ́n, wọ́n mú owó tí wọ́n tà wọ́n wá, wọ́n dà á sílẹ̀ níwájú àwọn aposteli kí wọ́n lè pín in fún àwọn tí ó bá ṣe aláìní. Josẹfu, ọmọ ìdílé Lefi ará Kipru ẹni tí àwọn aposteli ń pè ní Banaba, (èyí ni “Ọmọ ìtùnú,”) ní ilẹ̀ kan. Ó tà á, ó sì mú owó rẹ̀ wá fún àwọn aposteli.