Iṣe Apo 4:23-28
Iṣe Apo 4:23-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ, nwọn lọ sọdọ awọn ẹgbẹ wọn, nwọn si ròhin ohun gbogbo ti awọn olori alufa ati awọn agbàgba sọ fun wọn. Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn fi ọkàn kan gbé ohùn wọn soke si Ọlọrun nwọn si wipe, Oluwa, ìwọ ti o da ọrun on aiye, ati okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn: Iwọ nipa Ẹmi Mimọ́ ti o ti ẹnu Dafidi baba wa iranṣẹ rẹ wipe, Ẽṣe ti awọn keferi fi mbinu, ati ti awọn enia ngbero ohun asan? Awọn ọba aiye dide, ati awọn ijoye kó ara wọn jọ si Oluwa, ati si Kristi rẹ̀; Nitõtọ sá ni, si Jesu Ọmọ mimọ́ rẹ, ẹniti iwọ ti fi oróro yàn, ati Herodu, ati Pontiu Pilatu, pẹlu awọn keferi, ati awọn enia Israeli pejọ si, Lati ṣe ohunkohun ti ọwọ́ rẹ ati imọ rẹ ti pinnu ṣaju pe yio ṣẹ.
Iṣe Apo 4:23-28 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ wọn, wọ́n ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà sọ fún wọn. Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n jọ ké pe Ọlọrun pé, “Oluwa, ìwọ tí ó dá ọ̀run ati ayé ati òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn, ìwọ tí ó sọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ láti ẹnu baba ńlá wa, Dafidi, ọmọ rẹ pé, ‘Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń di rìkíṣí, tí àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè ń gbèrò asán? Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ, àwọn ìjòyè fohùn ṣọ̀kan, láti dìtẹ̀ sí Oluwa ati sí Mesaya rẹ̀.’ Nítorí òdodo ni pé Hẹrọdu ati Pọntiu Pilatu pẹlu àwọn tí kì í ṣe Juu ati àwọn eniyan Israẹli péjọpọ̀ ní ìlú yìí, wọ́n ṣe ohun tí ó lòdì sí ọmọ mímọ́ rẹ, Jesu tí o ti fi òróró yàn ní Mesaya, àwọn ohun tí ọwọ́ rẹ ati ètò rẹ ti ṣe ìlànà rẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Iṣe Apo 4:23-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí wọ́n sì ti fi wọ́n sílẹ̀ wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà sọ fún wọn. Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n fi ọkàn kan gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run, wọ́n sì wí pé, “Olúwa Olódùmarè, ìwọ tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn. Ìwọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ti ẹnu Dafidi baba wa ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé: “ ‘E é ṣe tí àwọn kèfèrí fi ń bínú, àti tí àwọn ènìyàn ń gbèrò ohun asán? Àwọn ọba ayé dìde, àti àwọn ìjòyè kó ara wọn jọ sí Olúwa, àti sí ẹni ààmì òróró rẹ̀.’ Àní nítòótọ́ ní Herodu àti Pọntiu Pilatu, pẹ̀lú àwọn aláìkọlà àti àwọn ènìyàn Israẹli kó ara wọn jọ ní ìlú yìí láti dìtẹ̀ sí Jesu Ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ, ẹni tí ìwọ ti fi ààmì òróró yàn, Láti ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ àti ìmọ̀ rẹ̀ ti pinnu ṣáájú pé yóò ṣe.