Iṣe Apo 4:16-20
Iṣe Apo 4:16-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Wipe, Kili a o ti ṣe awọn ọkunrin wọnyi? ti pe iṣẹ àmi ti o daju ti ọwọ́ wọn ṣe, o hàn gbangba fun gbogbo awọn ti ngbé Jerusalemu; awa kò si le sẹ́ ẹ. Ṣugbọn ki o má bà tàn kalẹ siwaju mọ́ lãrin awọn enia, ẹ jẹ ki a kìlọ fun wọn pe, lati isisiyi lọ ki nwọn ki o máṣe fi orukọ yi sọ̀rọ fun ẹnikẹni mọ́. Nigbati nwọn si pè wọn, nwọn paṣẹ fun wọn, ki nwọn máṣe sọ̀rọ rara, bẹni ki nwọn máṣe kọ́ni li orukọ Jesu mọ́. Ṣugbọn Peteru on Johanu dahùn, nwọn si wi fun wọn pe, Bi o ba tọ́ li oju Ọlọrun lati gbọ́ ti nyin jù ti Ọlọrun lọ, ẹ gbà a rò, Awa kò sá le ṣaima sọ ohun ti awa ti ri, ti a si ti gbọ́.
Iṣe Apo 4:16-20 Yoruba Bible (YCE)
“Kí ni a óo ṣe sí àwọn ọkunrin wọnyi o? Nítorí ó hàn lónìí sí gbogbo àwọn tí ó ń gbé Jerusalẹmu pé wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abàmì. A kò sì lè wí pé èyí kò rí bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn kí ó má baà tún máa tàn kálẹ̀ sí i láàrin àwọn eniyan, ẹ jẹ́ kí á kìlọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ dárúkọ Jesu fún ẹnikẹ́ni mọ́.” Àwọn ìgbìmọ̀ bá tún pè wọ́n wọlé, wọ́n pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ tún dárúkọ Jesu mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ tún fi orúkọ Jesu kọ́ àwọn eniyan mọ́. Ṣugbọn Peteru ati Johanu dá wọn lóhùn pé, “Èwo ni ó tọ́ níwájú Ọlọrun: kí á gbọ́ràn si yín lẹ́nu ni, tabi kí á gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu? Ẹ̀yin náà ẹ dà á rò. Ní tiwa, a kò lè ṣe aláìsọ ohun tí a ti rí ati ohun tí a ti gbọ́.”
Iṣe Apo 4:16-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wí pé, “Kí ni a ó ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí? Ní ti pé iṣẹ́ ààmì tí ó dájú tí ọwọ́ wọn ṣe, ó hàn gbangba fún gbogbo àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu; àwa kò sì lè sẹ́ èyí. Ṣùgbọ́n kí ó má ba à tànkálẹ̀ síwájú mọ́ láàrín àwọn ènìyàn, ẹ jẹ́ kí a kìlọ̀ fún wọn pé, láti ìsinsin yìí lọ kí wọn má ṣe fi orúkọ yìí sọ̀rọ̀ sí ẹnikẹ́ni mọ́.” Wọ́n sì pè wọ́n, wọ́n pàṣẹ fún wọn, kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ tàbí kọ́ni rárá mọ́ ní orúkọ Jesu. Ṣùgbọ́n Peteru àti Johanu dáhùn, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá tọ́ lójú Ọlọ́run láti gbọ́ tiyín ju ti Ọlọ́run lọ ẹ gbà á rò. Àwa kò lè ṣàìmá sọ ohun tí àwa ń rí, tí a sì ti gbọ́.”