Iṣe Apo 4:13-31
Iṣe Apo 4:13-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati nwọn si kiyesi igboiya Peteru on Johanu, ti nwọn si mọ̀ pe, alaikẹkọ ati òpe enia ni nwọn, ẹnu yà wọn; nwọn si woye wọn pe, nwọn a ti ma ba Jesu gbé. Nigbati nwọn si nwò ọkunrin na ti a mu larada, ti o ba wọn duro, nwọn kò ri nkan wi si i. Ṣugbọn nigbati nwọn si paṣẹ pe ki nwọn jade kuro ni igbimọ, nwọn ba ara wọn gbèro, Wipe, Kili a o ti ṣe awọn ọkunrin wọnyi? ti pe iṣẹ àmi ti o daju ti ọwọ́ wọn ṣe, o hàn gbangba fun gbogbo awọn ti ngbé Jerusalemu; awa kò si le sẹ́ ẹ. Ṣugbọn ki o má bà tàn kalẹ siwaju mọ́ lãrin awọn enia, ẹ jẹ ki a kìlọ fun wọn pe, lati isisiyi lọ ki nwọn ki o máṣe fi orukọ yi sọ̀rọ fun ẹnikẹni mọ́. Nigbati nwọn si pè wọn, nwọn paṣẹ fun wọn, ki nwọn máṣe sọ̀rọ rara, bẹni ki nwọn máṣe kọ́ni li orukọ Jesu mọ́. Ṣugbọn Peteru on Johanu dahùn, nwọn si wi fun wọn pe, Bi o ba tọ́ li oju Ọlọrun lati gbọ́ ti nyin jù ti Ọlọrun lọ, ẹ gbà a rò, Awa kò sá le ṣaima sọ ohun ti awa ti ri, ti a si ti gbọ́. Nigbati nwọn si kìlọ fun wọn si i, nwọn jọwọ wọn lọwọ lọ, nigbati nwọn kò ti ri nkan ti nwọn iba fi jẹ wọn ni ìya, nitori awọn enia: nitori gbogbo wọn ni nyìn Ọlọrun logo fun ohun ti a ṣe. Nitori ọkunrin na jù ẹni-ogoji ọdún lọ, lara ẹniti a ṣe iṣẹ àmi dida ara yi. Nigbati nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ, nwọn lọ sọdọ awọn ẹgbẹ wọn, nwọn si ròhin ohun gbogbo ti awọn olori alufa ati awọn agbàgba sọ fun wọn. Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn fi ọkàn kan gbé ohùn wọn soke si Ọlọrun nwọn si wipe, Oluwa, ìwọ ti o da ọrun on aiye, ati okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn: Iwọ nipa Ẹmi Mimọ́ ti o ti ẹnu Dafidi baba wa iranṣẹ rẹ wipe, Ẽṣe ti awọn keferi fi mbinu, ati ti awọn enia ngbero ohun asan? Awọn ọba aiye dide, ati awọn ijoye kó ara wọn jọ si Oluwa, ati si Kristi rẹ̀; Nitõtọ sá ni, si Jesu Ọmọ mimọ́ rẹ, ẹniti iwọ ti fi oróro yàn, ati Herodu, ati Pontiu Pilatu, pẹlu awọn keferi, ati awọn enia Israeli pejọ si, Lati ṣe ohunkohun ti ọwọ́ rẹ ati imọ rẹ ti pinnu ṣaju pe yio ṣẹ. Njẹ nisisiyi, Oluwa, kiyesi ikilọ wọn: ki o si fifun awọn ọmọ-ọdọ rẹ lati mã fi igboiya gbogbo sọ ọ̀rọ rẹ. Ki iwọ si fi ninà ọwọ́ rẹ ṣe dida ara, ati ki iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu ki o mã ṣe li orukọ Jesu Ọmọ mimọ́ rẹ. Nigbati nwọn gbadura tan, ibi ti nwọn gbé pejọ si mi titi; gbogbo wọn si kún fun Ẹmí Mimọ́, nwọn si nfi igboiya sọ ọ̀rọ Ọlọrun.
Iṣe Apo 4:13-31 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n rí ìgboyà Peteru ati ti Johanu, tí wọ́n wòye pé wọn kò mọ ìwé àtipé òpè eniyan ni wọ́n, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n ṣe akiyesi wọn pé wọ́n ti wà pẹlu Jesu. Wọ́n wo ọkunrin tí wọ́n mú lára dá tí ó dúró lọ́dọ̀ wọn, wọn kò sì mọ ohun tí wọn yóo sọ. Wọ́n bá pàṣẹ pé kí wọ́n jáde kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìgbìmọ̀. Àwọn ìgbìmọ̀ wá ń bi ara wọn pé, “Kí ni a óo ṣe sí àwọn ọkunrin wọnyi o? Nítorí ó hàn lónìí sí gbogbo àwọn tí ó ń gbé Jerusalẹmu pé wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abàmì. A kò sì lè wí pé èyí kò rí bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn kí ó má baà tún máa tàn kálẹ̀ sí i láàrin àwọn eniyan, ẹ jẹ́ kí á kìlọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ dárúkọ Jesu fún ẹnikẹ́ni mọ́.” Àwọn ìgbìmọ̀ bá tún pè wọ́n wọlé, wọ́n pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ tún dárúkọ Jesu mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ tún fi orúkọ Jesu kọ́ àwọn eniyan mọ́. Ṣugbọn Peteru ati Johanu dá wọn lóhùn pé, “Èwo ni ó tọ́ níwájú Ọlọrun: kí á gbọ́ràn si yín lẹ́nu ni, tabi kí á gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu? Ẹ̀yin náà ẹ dà á rò. Ní tiwa, a kò lè ṣe aláìsọ ohun tí a ti rí ati ohun tí a ti gbọ́.” Lẹ́yìn tí wọ́n tún halẹ̀ mọ́ wọn, wọ́n dá wọn sílẹ̀, nítorí wọn kò rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi jẹ wọ́n níyà, nítorí àwọn eniyan. Gbogbo eniyan ni wọ́n sì ń fi ìyìn fún Ọlọrun fún ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ọkunrin tí wọn ṣe iṣẹ́ abàmì ìmúláradá yìí lára rẹ̀ ju ẹni ogoji ọdún lọ. Nígbà tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ wọn, wọ́n ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà sọ fún wọn. Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n jọ ké pe Ọlọrun pé, “Oluwa, ìwọ tí ó dá ọ̀run ati ayé ati òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn, ìwọ tí ó sọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ láti ẹnu baba ńlá wa, Dafidi, ọmọ rẹ pé, ‘Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń di rìkíṣí, tí àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè ń gbèrò asán? Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ, àwọn ìjòyè fohùn ṣọ̀kan, láti dìtẹ̀ sí Oluwa ati sí Mesaya rẹ̀.’ Nítorí òdodo ni pé Hẹrọdu ati Pọntiu Pilatu pẹlu àwọn tí kì í ṣe Juu ati àwọn eniyan Israẹli péjọpọ̀ ní ìlú yìí, wọ́n ṣe ohun tí ó lòdì sí ọmọ mímọ́ rẹ, Jesu tí o ti fi òróró yàn ní Mesaya, àwọn ohun tí ọwọ́ rẹ ati ètò rẹ ti ṣe ìlànà rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ǹjẹ́ nisinsinyii, Oluwa, ṣe akiyesi bí wọ́n ti ń halẹ̀, kí o sì fún àwọn iranṣẹ rẹ ní ìgboyà ní gbogbo ọ̀nà láti lè sọ ọ̀rọ̀ rẹ. Kí o wá na ọwọ́ rẹ kí o ṣe ìwòsàn, ṣe iṣẹ́ abàmì, ati iṣẹ́ ìyanu nípa orúkọ Jesu ọmọ mímọ́ rẹ.” Bí wọ́n ti ń gbadura, ibi tí wọ́n péjọ sí mì tìtì, gbogbo wọn bá kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n bá ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun.
Iṣe Apo 4:13-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí wọ́n sì kíyèsi ìgboyà Peteru àti Johanu, tí wọ́n mọ̀ pé, aláìkẹ́kọ̀ọ́ àti òpè ènìyàn ni wọn, ẹnu yà wọ́n, wọ́n sì wòye pé, wọ́n ti ń bá Jesu gbé. Nígbà tí wọ́n sì ń wo ọkùnrin náà tí a mú láradá, tí ó bá wọn dúró, wọn kò rí nǹkan wí sí i. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sì ti pàṣẹ pé kí wọn jáde kúrò ní ìgbìmọ̀, wọ́n bá ara wọn gbèrò. Wí pé, “Kí ni a ó ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí? Ní ti pé iṣẹ́ ààmì tí ó dájú tí ọwọ́ wọn ṣe, ó hàn gbangba fún gbogbo àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu; àwa kò sì lè sẹ́ èyí. Ṣùgbọ́n kí ó má ba à tànkálẹ̀ síwájú mọ́ láàrín àwọn ènìyàn, ẹ jẹ́ kí a kìlọ̀ fún wọn pé, láti ìsinsin yìí lọ kí wọn má ṣe fi orúkọ yìí sọ̀rọ̀ sí ẹnikẹ́ni mọ́.” Wọ́n sì pè wọ́n, wọ́n pàṣẹ fún wọn, kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ tàbí kọ́ni rárá mọ́ ní orúkọ Jesu. Ṣùgbọ́n Peteru àti Johanu dáhùn, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá tọ́ lójú Ọlọ́run láti gbọ́ tiyín ju ti Ọlọ́run lọ ẹ gbà á rò. Àwa kò lè ṣàìmá sọ ohun tí àwa ń rí, tí a sì ti gbọ́.” Nígbà tí wọ́n sì kìlọ̀ fún wọn sí i, wọn fi wọ́n sílẹ̀ lọ, nígbà tí wọn kò ì tí ì rí nǹkan tí wọn ìbá fi jẹ wọ́n ní ìyà, nítorí àwọn ènìyàn; nítorí gbogbo wọn ni wọ́n yin Ọlọ́run lógo fún ohun tí ó ṣe. Nítorí ọkùnrin náà lára ẹni tí a ṣe iṣẹ́ ààmì ìmúláradá, ju ẹni ogójì ọdún lọ. Nígbà tí wọ́n sì ti fi wọ́n sílẹ̀ wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà sọ fún wọn. Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n fi ọkàn kan gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run, wọ́n sì wí pé, “Olúwa Olódùmarè, ìwọ tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn. Ìwọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ti ẹnu Dafidi baba wa ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé: “ ‘E é ṣe tí àwọn kèfèrí fi ń bínú, àti tí àwọn ènìyàn ń gbèrò ohun asán? Àwọn ọba ayé dìde, àti àwọn ìjòyè kó ara wọn jọ sí Olúwa, àti sí ẹni ààmì òróró rẹ̀.’ Àní nítòótọ́ ní Herodu àti Pọntiu Pilatu, pẹ̀lú àwọn aláìkọlà àti àwọn ènìyàn Israẹli kó ara wọn jọ ní ìlú yìí láti dìtẹ̀ sí Jesu Ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ, ẹni tí ìwọ ti fi ààmì òróró yàn, Láti ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ àti ìmọ̀ rẹ̀ ti pinnu ṣáájú pé yóò ṣe. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Olúwa, kíyèsi ìhàlẹ̀ wọn; kí ó sì fi fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ láti máa fi ìgboyà ńlá sọ ọ̀rọ̀ rẹ. Kí ìwọ sì fi nína ọwọ́ rẹ ṣe ìmúláradá, àti kí iṣẹ́ ìyanu máa ṣẹ̀ ní orúkọ Jesu ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ.” Nígbà tí wọ́n gbàdúrà tan, ibi tí wọ́n gbé péjọpọ̀ sí mì tìtì; gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n sì ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.