Iṣe Apo 23:1-11
Iṣe Apo 23:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI Paulu si tẹjumọ igbimọ, o ni, Ará, emi ti nfi gbogbo ẹri-ọkàn rere lò aiye mi niwaju Ọlọrun titi fi di oni yi. Anania olori alufa si paṣẹ fun awọn ti o duro tì i pe, ki o gbún u li ẹnu. Nigbana ni Paulu wi fun u pe, Ọlọrun yio lù ọ, iwọ ogiri ti a kùn li ẹfun: iwọ joko lati dajọ mi ni gẹgẹ bi ofin, iwọ si pè ki a lù mi li òdi si ofin? Awọn ti o duro tì i si wipe, Olori alufa Ọlọrun ni iwọ ngàn? Paulu si wipe, Ará, emi kò mọ̀ pe olori alufa ni: nitori a ti kọ ọ pe, Iwọ kò gbọdọ sọ̀rọ olori awọn enia rẹ ni buburu. Ṣugbọn nigbati Paulu ṣakiyesi pe, apakan wọn jẹ Sadusi, apakan si jẹ Farisi, o kigbe ni igbimọ pe, Ará, Farisi li emi, ọmọ Farisi: nitori ireti ati ajinde okú li a ṣe ba mi wijọ. Nigbati o si ti wi eyi, iyapa de lãrin awọn Farisi ati awọn Sadusi: ajọ si pin meji. Nitoriti awọn Sadusi wipe, kò si ajinde, tabi angẹli, tabi ẹmí: ṣugbọn awọn Farisi jẹwọ mejeji. O si di ariwo nla: ninu awọn akọwe ti o wà li apa ti awọn Farisi dide, nwọn njà, wipe, Awa kò ri ohun buburu kan lara ọkunrin yi: ki si ni bi ẹmi kan tabi angẹli kan li o ba a sọ̀rọ? Nigbati iyapa si di nla, ti olori ogun bẹ̀ru ki Paulu ki o má bà di fifaya lọwọ wọn, o paṣẹ pe ki awọn ọmọ-ogun sọkalẹ lọ lati fi ipá mu u kuro lãrin wọn, ki nwọn si mu u wá sinu ile-olodi. Li oru ijọ nã Oluwa duro tì i, o si wipe, Tujuka: nitori bi iwọ ti jẹri fun mi ni Jerusalemu, bẹ̃ni iwọ kò le ṣaijẹrí ni Romu pẹlu.
Iṣe Apo 23:1-11 Yoruba Bible (YCE)
Paulu kọjú sí àwọn ìgbìmọ̀, ó ní, “Ẹ̀yin ará, ní gbogbo ìgbé-ayé mi, ọkàn mí mọ́ níwájú Ọlọrun títí di òní.” Bí ó ti sọ báyìí, bẹ́ẹ̀ ni Anania Olórí Alufaa sọ fún àwọn tí ó dúró ti Paulu pé kí wọ́n gbá a lẹ́nu. Paulu wá sọ fún un pé, “Ọlọrun yóo lù ọ́. Ìwọ ògiri tí wọ́n kùn lẹ́fun lásán yìí! O jókòó sibẹ, ò ń dá mi lẹ́jọ́ lórí Òfin, sibẹ o pa Òfin tì, o ní kí wọ́n lù mí.” Àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ bá ní, “Olórí Alufaa Ọlọrun ni ò ń bú bẹ́ẹ̀?” Paulu dáhùn pé, “Ará, n kò mọ̀ pé Olórí Alufaa ni. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ burúkú sí aláṣẹ àwọn eniyan rẹ.’ ” Nígbà tí Paulu mọ̀ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Sadusi ni apá kan ninu àwọn tí wọ́n wà ninu ìgbìmọ̀, àtipé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Farisi ni àwọn mìíràn, ó kígbe pé, “Ẹ̀yin ará, Farisi ni mí. Farisi ni àwọn òbí mi. Nítorí ìrètí wa pé àwọn òkú yóo jí dìde ni wọ́n ṣe mú mi wá dáhùn ẹjọ́.” Nígbà tí ó sọ báyìí, ìyapa bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn Farisi ati àwọn Sadusi, ìgbìmọ̀ bá pín sí meji. Nítorí àwọn Sadusi sọ pé kò sí ajinde, bẹ́ẹ̀ ni kò sí angẹli tabi àwọn ẹ̀mí; ṣugbọn àwọn Farisi gbà pé mẹtẹẹta wà. Ni ariwo ńlá bá bẹ́ sílẹ̀. Àwọn amòfin kan ninu àwọn Farisi dìde, wọ́n tẹnu mọ́ ọn pé, “Àwa kò rí nǹkan burúkú tí ọkunrin yìí ṣe. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀mí ni ó sọ̀rọ̀ fún un ńkọ́? Tabi angẹli?” Nígbà tí àríyànjiyàn náà pọ̀ pupọ, ẹ̀rù ba ọ̀gágun pé kí wọn má baà fa Paulu ya. Ó bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ogun kí wọn wá fi agbára mú Paulu kúrò láàrin wọn, kí wọn mú un wọnú àgọ́ àwọn ọmọ-ogun lọ. Ní òru ọjọ́ keji, Oluwa dúró lẹ́bàá Paulu, ó ní, “Ṣe ọkàn rẹ gírí. Gẹ́gẹ́ bí o ti jẹ́rìí iṣẹ́ mi ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni o níláti jẹ́rìí nípa mi ní Romu náà.”

Iṣe Apo 23:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Paulu tẹjúmọ́ ìgbìmọ̀, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi tí ń fi gbogbo ẹ̀rí ọkàn rere lo ayé mi níwájú Ọlọ́run títí fi di òní yìí.” Nígbà yìí ni Anania olórí àlùfáà pàṣẹ fún àwọn tí ó dúró tí Paulu pé, kí wọn ó gbá a lẹ́nu. Nígbà náà ni Paulu wí fún un pé, “Ọlọ́run yóò lù ọ́, ìwọ ògiri tí a kùn lẹ́fun: ìwọ jókòó láti dá mi lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin, ṣùgbọ́n ìwọ gan an rú òfin nípa pípàṣẹ pé kí a lù mí!” Àwọn tí ó dúró tì Paulu sì wí pé, “Ìwọ́ ń gan olórí àlùfáà Ọlọ́run?” Paulu sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi kò mọ̀ pé olórí àlùfáà ni: nítorí a tí kọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní búburú.’ ” Ṣùgbọ́n nígbà tí Paulu ṣàkíyèsí pé, apá kan wọn jẹ́ Sadusi, apá kan sì jẹ́ Farisi, ó kígbe ní ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, Èmi jẹ́ Farisi, ọmọ Farisi sì ni èmi. Mo dúró ní ìdájọ́ nítorí ìrètí mi nínú àjíǹde òkú.” Nígbà tí ó sì tí wí èyí, ìyapa dé láàrín àwọn Farisi àti àwọn Sadusi: àjọ sì pín sì méjì. Nítorí tí àwọn Sadusi wí pé, kò sì àjíǹde, tàbí angẹli, tàbí ẹ̀mí: ṣùgbọ́n àwọn Farisi jẹ́wọ́ méjèèjì: Ó sì di ariwo ńlá, nínú àwọn olùkọ́ òfin tí ó wà ni apá tí àwọn Farisi dìde, wọ́n ń jà, wí pé, “Àwa kò rí ohun búburú kan lára ọkùnrin yìí,” wọ́n wí “àwa kò sì mọ̀ nítòótọ́ bí angẹli kan tàbí ẹ̀mí kan ń ba à sọ̀rọ̀?” Nígbà tí ìyapa sì di ńlá, tí olórí ogun bẹ̀rù kí Paulu má ba à di fífàya lọ́wọ́ wọn, ó pàṣẹ pé ki àwọn ọmọ-ogun sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ipá mú un kúrò láàrín wọn, kí wọn sì mú un wá sínú àgọ́ àwọn ológun. Ní òru ọjọ́ náà Olúwa dúró tì Paulu, ó wí pé, “Mú ọkàn le! Bí ìwọ ti jẹ́rìí fún mi ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò lè ṣàìjẹ́rìí ni Romu pẹ̀lú.”