Iṣe Apo 23

23
1NIGBATI Paulu si tẹjumọ igbimọ, o ni, Ará, emi ti nfi gbogbo ẹri-ọkàn rere lò aiye mi niwaju Ọlọrun titi fi di oni yi.
2Anania olori alufa si paṣẹ fun awọn ti o duro tì i pe, ki o gbún u li ẹnu.
3Nigbana ni Paulu wi fun u pe, Ọlọrun yio lù ọ, iwọ ogiri ti a kùn li ẹfun: iwọ joko lati dajọ mi ni gẹgẹ bi ofin, iwọ si pè ki a lù mi li òdi si ofin?
4Awọn ti o duro tì i si wipe, Olori alufa Ọlọrun ni iwọ ngàn?
5Paulu si wipe, Ará, emi kò mọ̀ pe olori alufa ni: nitori a ti kọ ọ pe, Iwọ kò gbọdọ sọ̀rọ olori awọn enia rẹ ni buburu.
6Ṣugbọn nigbati Paulu ṣakiyesi pe, apakan wọn jẹ Sadusi, apakan si jẹ Farisi, o kigbe ni igbimọ pe, Ará, Farisi li emi, ọmọ Farisi: nitori ireti ati ajinde okú li a ṣe ba mi wijọ.
7Nigbati o si ti wi eyi, iyapa de lãrin awọn Farisi ati awọn Sadusi: ajọ si pin meji.
8Nitoriti awọn Sadusi wipe, kò si ajinde, tabi angẹli, tabi ẹmí: ṣugbọn awọn Farisi jẹwọ mejeji.
9O si di ariwo nla: ninu awọn akọwe ti o wà li apa ti awọn Farisi dide, nwọn njà, wipe, Awa kò ri ohun buburu kan lara ọkunrin yi: ki si ni bi ẹmi kan tabi angẹli kan li o ba a sọ̀rọ?
10Nigbati iyapa si di nla, ti olori ogun bẹ̀ru ki Paulu ki o má bà di fifaya lọwọ wọn, o paṣẹ pe ki awọn ọmọ-ogun sọkalẹ lọ lati fi ipá mu u kuro lãrin wọn, ki nwọn si mu u wá sinu ile-olodi.
11Li oru ijọ nã Oluwa duro tì i, o si wipe, Tujuka: nitori bi iwọ ti jẹri fun mi ni Jerusalemu, bẹ̃ni iwọ kò le ṣaijẹrí ni Romu pẹlu.
Àwọn Juu Dìtẹ̀ láti Pa Paulu
12Nigbati ilẹ mọ́, awọn Ju kan dimọlu, nwọn fi ara wọn bu pe, awọn kì yio jẹ bẹ̃li awọn kì yio mu, titi awọn ó fi pa Paulu.
13Awọn ti o ditẹ yi si jù ogoji enia lọ.
14Nwọn si tọ̀ olori awọn alufa ati awọn àgbagba lọ, nwọn si wipe, Awa ti fi èpe nla bu ara wa pe, a kì yio tọ́ ohun nkan wò titi awa ó fi pa Paulu.
15Njẹ nisisiyi ki ẹnyin pẹlu ajọ igbimọ wi fun olori-ogun, ki o mu u sọkalẹ tọ̀ nyin wá, bi ẹnipe ẹnyin nfẹ wadi ọ̀ran rẹ̀ dajudaju: ki o to sunmọ itosi, awa ó si ti mura lati pa a.
16Nigbati ọmọ arabinrin Paulu si gburó idena wọn, o lọ, o si wọ̀ inu ile-olodi lọ, o si sọ fun Paulu.
17Paulu si pè ọkan ninu awọn balogun ọrún sọdọ rẹ̀, o ni, Mu ọmọkunrin yi tọ̀ olori-ogun lọ: nitori o ni nkan lati sọ fun u.
18O mu u, o si sìn i lọ sọdọ olori-ogun, o si wipe, Paulu ondè pè mi sọdọ rẹ̀, o si bẹ̀ mi pe ki emi mu ọmọkunrin yi tọ̀ ọ wá, ẹniti o ni nkan lati sọ fun ọ.
19Olori-ogun fà a lọwọ, o si lọ si apakan, o si bi i lere nikọkọ pe, Kili ohun ti iwọ ni isọ fun mi?
20O si wipe, Awọn Ju fi ìmọ ṣọkan lati wá ibẹ̀ ọ ki o mu Paulu sọkalẹ wá si ajọ igbimọ li ọla, bi ẹnipe iwọ nfẹ bère nkan dajudaju nipa rẹ̀.
21Nitorina máṣe gbọ́ tiwọn: nitori awọn ti o dèna dè e ninu wọn jù ogoji ọkunrin lọ, ti nwọn fi ara wọn bu pe, awọn kì yio jẹ, bẹ̃li awọn kì yio mu titi awọn o fi pa a: nisisiyi nwọn si ti mura tan, nwọn nreti idahùn lọdọ rẹ.
22Nigbana li olori ogun jọwọ ọmọkunrin na lọwọ lọ, o si kìlọ fun u pe, Máṣe wi fun ẹnikan pe, iwọ fi nkan wọnyi hàn mi.
A fi Paulu Ranṣẹ sí Fẹliksi Gomina
23O si pè meji awọn balogun ọrún sọdọ rẹ̀, o si wipe, Ẹ mura igba ọmọ-ogun silẹ, lati lọ si Kesarea, ati adọrin ẹlẹṣin, ati igba ọlọkọ̀, ni wakati kẹta oru;
24O si wipe, ki nwọn pèse ẹranko, ki nwọn gbé Paulu gùn u, ki nwọn si le mu u de ọdọ Feliksi bãlẹ li alafia.
25O si kọ iwe kan bayi pe:
26Klaudiu Lisia si Feliksi bãlẹ ọlọla julọ, alafia.
27Awọn Ju mu ọkunrin yi, nwọn si npete ati pa a: nigbana ni mo de pẹlu ogun, mo si gbà a lọwọ wọn nigbati mo gbọ́ pe ara Romu ni iṣe.
28Nigbati mo si nfẹ mọ̀ idi ọ̀ran ti nwọn fi i sùn si, mo mu u sọkalẹ lọ si ajọ igbimọ wọn:
29Ẹniti mo ri pe, nwọn fisùn nitori ọ̀ran ofin wọn, bẹ̃ni kò dà ọ̀ran kan ti o tọ́ si ikú ati si ìde.
30Nigbati a si ti sọ fun mi pe, nwọn ó dèna dè ọkunrin na, ọgan mo si rán a si ọ, mo si paṣẹ fun awọn olufisùn rẹ̀ pẹlu, lati sọ ohun ti nwọn ba ri wi si i niwaju rẹ.
31Nigbana li awọn ọmọ-ogun gbà Paulu, nwọn si mu u li oru lọ si Antipatri, gẹgẹ bi a ti paṣẹ fun wọn.
32Nijọ keji nwọn si jọwọ awọn ẹlẹṣin lati mã ba a lọ, nwọn si pada wá sinu ile-olodi.
33Nigbati nwọn de Kesarea, ti nwọn si fi iwe fun bãlẹ, nwọn mu Paulu pẹlu wá siwaju rẹ̀.
34Nigbati o si ti kà iwe na, o bère pe ara ilẹ wo ni iṣe. Nigbati o si gbọ́ pe ara Kilikia ni;
35O ni, Emi ó gbọ́ ẹjọ rẹ, nigbati awọn olufisùn rẹ pẹlu ba de. O si paṣẹ pe ki nwọn ki o pa a mọ́ ni gbọ̀ngan idajọ Herodu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Iṣe Apo 23: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀