Iṣe Apo 20:28-38

Iṣe Apo 20:28-38 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹ kiyesara nyin, ati si gbogbo agbo ti Ẹmí Mimọ́ fi nyin ṣe alabojuto rẹ̀, lati mã tọju ijọ Ọlọrun, ti o ti fi ẹ̀jẹ ara rẹ̀ rà. Nitoriti emi mọ̀ pe, lẹhin lilọ mi, ikõkò buburu yio wọ̀ ãrin nyin, li aidá agbo si. Ati larin ẹnyin tikaranyin li awọn enia yio dide, ti nwọn o ma sọ̀rọ òdi, lati fà awọn ọmọ-ẹhin sẹhin wọn. Nitorina ẹ mã ṣọra, ki ẹ si mã ranti pe, fun ọdún mẹta, emi kò dẹkun ati mã fi omije kìlọ fun olukuluku li ọsán ati li oru. Njẹ nisisiyi, ará, mo fi nyin le Ọlọrun lọwọ ati ọ̀rọ ore-ọfẹ rẹ̀, ti o le gbe nyin duro, ti o si le fun nyin ni ini lãrin gbogbo awọn ti a sọ di mimọ́. Emi kò ṣe ojukòkoro fadaka, tabi wura, tabi aṣọ ẹnikẹni. Ẹnyin tikaranyin sá mọ̀ pe, ọwọ́ wọnyi li o ṣiṣẹ fun aini mi, ati ti awọn ti o wà pẹlu mi. Ninu ohun gbogbo mo fi apẹrẹ fun nyin pe, nipa ṣiṣe iṣẹ bẹ̃, yẹ ki ẹ mã ràn awọn alailera lọwọ, ki ẹ si mã ranti ọ̀rọ Jesu Oluwa, bi on tikararẹ̀ ti wipe, Ati funni o ni ibukún jù ati gbà lọ. Nigbati o si ti wi nkan wọnyi, o kunlẹ, o si ba gbogbo wọn gbadura. Gbogbo wọn si sọkun gidigidi, nwọn si rọ̀ mọ́ Paulu li ọrùn, nwọn si fi ẹnu kò o li ẹnu, Inu wọn si bajẹ julọ fun ọ̀rọ ti o sọ pe, nwọn kì yio ri oju on mọ́. Nwọn si sìn i lọ sinu ọkọ̀.

Iṣe Apo 20:28-38 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ ṣọ́ra yín, ẹ sì ṣọ́ agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alabojuto lórí rẹ̀, kí ẹ máa bọ́ ìjọ Ọlọrun tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ṣe ní tirẹ̀. Mo mọ̀ pé lẹ́yìn tí mo bá lọ, àwọn ẹhànnà ìkookò yóo wọ ààrin yín; wọn kò sì ní dá agbo sí. Mo mọ̀ pé láàrin yín àwọn ẹlòmíràn yóo dìde tí wọn yóo fi irọ́ yí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ́kàn pada láti tẹ̀lé wọn. Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́ra. Ẹ ranti pé fún ọdún mẹta, tọ̀sán-tòru ni n kò fi sinmi láti máa gba ẹnìkọ̀ọ̀kan yín níyànjú pẹlu omi lójú. “Nisinsinyii, mo fi yín lé Ọlọrun lọ́wọ́ ati ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí ó lè mu yín dàgbà, tí ó sì lè fun yín ní ogún pẹlu gbogbo àwọn tí a ti sọ di mímọ́. N kò ṣe ojúkòkòrò owó tabi aṣọ tabi góòlù ẹnikẹ́ni. Ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé ọwọ́ ara mi yìí ni mo fi ṣiṣẹ́ tí mo fi ń gbọ́ bùkátà mi ati ti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi. Mo ti fihàn yín pé bẹ́ẹ̀ ni a níláti ṣiṣẹ́ láti ran àwọn aláìlera lọ́wọ́. Kí á máa ranti àwọn ọ̀rọ̀ Oluwa Jesu, nítorí òun fúnra rẹ̀ sọ pé, ‘Ayọ̀ pọ̀ ninu kí a máa fúnni ní nǹkan ju kí á máa gbà lọ.’ ” Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó kúnlẹ̀ pẹlu gbogbo wọn, ó sì gbadura. Gbogbo wọn bá ń sunkún. Wọ́n ń dì mọ́ ọn, wọ́n ń fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Èyí tí ó dùn wọ́n jù ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ, pé wọn kò tún ní rí ojú òun mọ́. Wọ́n bá sìn ín lọ sí ìdíkọ̀.

Iṣe Apo 20:28-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ kíyèsára yin, àti sí gbogbo agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alábojútó rẹ̀, láti máa tọ́jú ìjọ Ọlọ́run, tí ó tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ rà. Nítorí tí èmi mọ̀ pé, lẹ́yìn lílọ mi, ìkookò búburú yóò wọ àárín yín, yóò sì tú agbo ká. Láàrín ẹ̀yin tìkára yín ni àwọn ènìyàn yóò sì dìde, tí wọn yóò máa sọ̀rọ̀-òdì, láti fa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sẹ́yìn wọn. Nítorí náà ẹ máa ṣọ́ra, ki ẹ sì máa rántí pé, fún ọdún mẹ́ta, èmi kò dẹ́kun láti máa fi omijé kìlọ̀ fún olúkúlùkù ní ọ̀sán àti ní òru. “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, mo fi yín lé Ọlọ́run lọ́wọ́ àti ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, tí ó lè gbé yín dúró, tí ó sì lè fún yín ní ìní láàrín gbogbo àwọn tí a sọ di mímọ́. Èmí kò ṣe ojúkòkòrò fàdákà, tàbí wúrà, tàbí aṣọ ẹnikẹ́ni. Ẹ̀yin tìkára yín sá à mọ̀ pé, ọwọ́ mi wọ̀nyí ni mo fi ṣiṣẹ́ láti fi pèsè fún àìní mi, àti tí àwọn tí ó wà pẹ̀lú mi. Nínú ohun gbogbo mo fi àpẹẹrẹ fún un yín pé, nípa ṣíṣe iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ki ẹ sì máa rántí ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, bí òun tìkára rẹ̀ tí wí pé, ‘láti fún ni ní ìbùkún ju láti gbà lọ.’  ” Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, ó kúnlẹ̀, ó sì bá gbogbo wọn gbàdúrà. Gbogbo wọn sì sọkún gidigidi, wọ́n sì rọ̀ mọ́ Paulu lọ́rùn, wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Inú wọn sì bàjẹ́ jùlọ fún ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé, wọn kì yóò rí ojú òun mọ́, wọ́n sì sìn ín títí dé inú ọkọ̀.