ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 20:28-38

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 20:28-38 YCE

Ẹ ṣọ́ra yín, ẹ sì ṣọ́ agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alabojuto lórí rẹ̀, kí ẹ máa bọ́ ìjọ Ọlọrun tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ṣe ní tirẹ̀. Mo mọ̀ pé lẹ́yìn tí mo bá lọ, àwọn ẹhànnà ìkookò yóo wọ ààrin yín; wọn kò sì ní dá agbo sí. Mo mọ̀ pé láàrin yín àwọn ẹlòmíràn yóo dìde tí wọn yóo fi irọ́ yí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ́kàn pada láti tẹ̀lé wọn. Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́ra. Ẹ ranti pé fún ọdún mẹta, tọ̀sán-tòru ni n kò fi sinmi láti máa gba ẹnìkọ̀ọ̀kan yín níyànjú pẹlu omi lójú. “Nisinsinyii, mo fi yín lé Ọlọrun lọ́wọ́ ati ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí ó lè mu yín dàgbà, tí ó sì lè fun yín ní ogún pẹlu gbogbo àwọn tí a ti sọ di mímọ́. N kò ṣe ojúkòkòrò owó tabi aṣọ tabi góòlù ẹnikẹ́ni. Ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé ọwọ́ ara mi yìí ni mo fi ṣiṣẹ́ tí mo fi ń gbọ́ bùkátà mi ati ti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi. Mo ti fihàn yín pé bẹ́ẹ̀ ni a níláti ṣiṣẹ́ láti ran àwọn aláìlera lọ́wọ́. Kí á máa ranti àwọn ọ̀rọ̀ Oluwa Jesu, nítorí òun fúnra rẹ̀ sọ pé, ‘Ayọ̀ pọ̀ ninu kí a máa fúnni ní nǹkan ju kí á máa gbà lọ.’ ” Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó kúnlẹ̀ pẹlu gbogbo wọn, ó sì gbadura. Gbogbo wọn bá ń sunkún. Wọ́n ń dì mọ́ ọn, wọ́n ń fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Èyí tí ó dùn wọ́n jù ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ, pé wọn kò tún ní rí ojú òun mọ́. Wọ́n bá sìn ín lọ sí ìdíkọ̀.