Iṣe Apo 2:1-13

Iṣe Apo 2:1-13 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ Pẹntikọsti, gbogbo wọn wà pọ̀ ní ibìkan náà. Lójijì ìró kan dún láti ọ̀run, ó dàbí ìgbà tí afẹ́fẹ́ líle bá ń fẹ́, ó sì kún gbogbo inú ilé níbi tí wọ́n gbé jókòó. Wọ́n rí nǹkankan tí ó dàbí ahọ́n iná, tí ó pín ara rẹ̀, tí ó sì bà lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. Gbogbo wọn bá kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ oríṣìíríṣìí èdè mìíràn gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti fi fún wọn láti máa sọ. Ní àkókò náà, àwọn Juu tí wọ́n jẹ́ olùfọkànsìn ti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé wá, wọ́n wà ní Jerusalẹmu. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìró yìí, àwọn eniyan rọ́ wá. Ẹnu yà wọ́n nítorí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gbọ́ tí wọn ń sọ èdè tirẹ̀. Èyí dà wọ́n láàmú, ó sì yà wọ́n lẹ́nu. Wọ́n ní, “Ṣebí ará Galili ni gbogbo àwọn tí ó ń sọ̀rọ̀ wọnyi? Kí ló dé tí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa fi gbọ́ tí wọn ń sọ èdè abínibí rẹ̀? Ati ará Patia, ati ará Media ati ará Elamu; àwọn tí ó ń gbé ilẹ̀ Mesopotamia, ilẹ̀ Judia ati ilẹ̀ Kapadokia; ilẹ̀ Pọntu, ilẹ̀ Esia, ilẹ̀ Firigia ati ilẹ̀ Pamfilia; ilẹ̀ Ijipti ati agbègbè Libia lẹ́bàá Kirene; àwọn àlejò láti ìlú Romu, àwọn Juu ati àwọn aláwọ̀ṣe ẹ̀sìn Juu; àwọn ará Kirete ati àwọn ará Arabia, gbogbo wa ni a gbọ́ tí wọ́n ń sọ àwọn iṣẹ́ ńlá Ọlọrun ní oríṣìíríṣìí èdè wa.” Ìdààmú bá gbogbo àwọn eniyan, ó pá wọn láyà. Wọ́n ń bi ara wọn pé, “Kí ni ìtumọ̀ èyí?” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n ní, “Wọ́n ti mu ọtí yó ni!”

Iṣe Apo 2:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí ọjọ́ Pentikosti sì dé, gbogbo wọn fi ọkàn kan wà ní ibìkan. Lójijì ìró sì ti ọ̀run wá, gẹ́gẹ́ bí ìró ẹ̀fúùfù líle, ó sì kún gbogbo ilé níbi tí wọ́n gbé jókòó. Ẹ̀là ahọ́n bí i iná sì yọ sí wọn, ó pín, ó sì bà lé olúkúlùkù wọn. Gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi èdè mìíràn sọ̀rọ̀, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti fi fún wọn ni ohùn. Àwọn Júù olùfọkànsìn láti orílẹ̀-èdè gbogbo lábẹ́ ọ̀run sì ń gbé Jerusalẹmu. Nígbà tí wọn sì gbọ́ ìró yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ pẹ̀lú ìyàlẹ́nu, nítorí tí olúkúlùkù gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní èdè rẹ̀. Ẹnu sì yà wọ́n, wọn ń wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ ara Galili kọ́ ni gbogbo àwọn tí ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́? Èéha sì tí ṣe ti olúkúlùkù wa fi ń gbọ́ bí wọ́n tí ń fi èdè sọ̀rọ̀? Àwọn ará Partia, àti Media, àti Elamu; àti àwọn tí ń gbé Mesopotamia, Judea, àti Kappadokia, Pọntu àti Asia. Frigia, àti pamfilia, Ejibiti, àti agbègbè Libia níhà Kirene; àti àwọn àtìpó Romu, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù (àti àwọn Júù àti àwọn tí a ti ipa ẹ̀sìn sọ di Júù); àwọn ará Krete àti Arabia; àwa gbọ́ tí wọ́n sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu ńlá Ọlọ́run ni èdè wa.” Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì wárìrì. Wọn wí fún ara wọn pé, “Kí ni èyí túmọ̀ sí?” Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn ń ṣẹ̀fẹ̀, wọn sí wí pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kún fún wáìnì tuntun”.