Ìṣe àwọn Aposteli 2:1-13

Ìṣe àwọn Aposteli 2:1-13 YCB

Nígbà tí ọjọ́ Pentikosti sì dé, gbogbo wọn fi ọkàn kan wà ní ibìkan. Lójijì ìró sì ti ọ̀run wá, gẹ́gẹ́ bí ìró ẹ̀fúùfù líle, ó sì kún gbogbo ilé níbi tí wọ́n gbé jókòó. Ẹ̀là ahọ́n bí i iná sì yọ sí wọn, ó pín, ó sì bà lé olúkúlùkù wọn. Gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi èdè mìíràn sọ̀rọ̀, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti fi fún wọn ni ohùn. Àwọn Júù olùfọkànsìn láti orílẹ̀-èdè gbogbo lábẹ́ ọ̀run sì ń gbé Jerusalẹmu. Nígbà tí wọn sì gbọ́ ìró yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ pẹ̀lú ìyàlẹ́nu, nítorí tí olúkúlùkù gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní èdè rẹ̀. Ẹnu sì yà wọ́n, wọn ń wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ ara Galili kọ́ ni gbogbo àwọn tí ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́? Èéha sì tí ṣe ti olúkúlùkù wa fi ń gbọ́ bí wọ́n tí ń fi èdè sọ̀rọ̀? Àwọn ará Partia, àti Media, àti Elamu; àti àwọn tí ń gbé Mesopotamia, Judea, àti Kappadokia, Pọntu àti Asia. Frigia, àti pamfilia, Ejibiti, àti agbègbè Libia níhà Kirene; àti àwọn àtìpó Romu, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù (àti àwọn Júù àti àwọn tí a ti ipa ẹ̀sìn sọ di Júù); àwọn ará Krete àti Arabia; àwa gbọ́ tí wọ́n sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu ńlá Ọlọ́run ni èdè wa.” Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì wárìrì. Wọn wí fún ara wọn pé, “Kí ni èyí túmọ̀ sí?” Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn ń ṣẹ̀fẹ̀, wọn sí wí pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kún fún wáìnì tuntun”.