Iṣe Apo 12:6-12
Iṣe Apo 12:6-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati Herodu iba si mu u jade, li oru na Peteru sùn li arin awọn ọmọ-ogun meji, a fi ẹ̀wọn meji de e, ẹ̀ṣọ́ si wà li ẹnu-ọ̀na, nwọn nṣọ́ tubu na. Si wo o, angẹli Oluwa duro tì i, imọlẹ si mọ́ ninu tubu: nigbati o si lù Peteru pẹ́pẹ li ẹgbẹ o ji i, o ni, Dide kánkan. Ẹwọn rẹ̀ si bọ́ silẹ kuro lọwọ rẹ̀. Angẹli na si wi fun u pe, Di àmure, ki o si so salubàta rẹ. O si ṣe bẹ̃. O si wi fun u pe, Da aṣọ rẹ bora, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin. On si jade, o ntọ̀ ọ lẹhin; kò si mọ̀ pe otitọ li ohun na ṣe lati ọwọ́ angẹli na wá; ṣugbọn o ṣebi on wà li ojuran. Nigbati nwọn kọja iṣọ ikini ati keji, nwọn de ẹnu-ọ̀na ilẹkun irin, ti o lọ si ilu, ti o si tikararẹ̀ ṣí silẹ fun wọn: nigbati nwọn si jade, nwọn nlọ titi li ọ̀na igboro kan; lojukanna angẹli na si fi i silẹ lọ. Nigbati oju Peteru si walẹ, o ni, Nigbayi ni mo to mọ̀ nitõtọ pe, Oluwa rán angẹli rẹ̀, o si gbà mi li ọwọ́ Herodu, ati gbogbo ireti awọn enia Ju. Nigbati o si rò o, o lọ si ile Maria iya Johanu, ti apele rẹ̀ jẹ Marku; nibiti awọn enia pipọ pejọ si, ti nwọn ngbadura.
Iṣe Apo 12:6-12 Yoruba Bible (YCE)
Ní òru, mọ́jú ọjọ́ tí Hẹrọdu ìbá mú Peteru wá fún ìdájọ́, Peteru sùn láàrin àwọn ọmọ-ogun meji, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n meji dè é; àwọn ọmọ-ogun kan sì tún wà lẹ́nu ọ̀nà, tí wọn ń ṣọ́nà. Angẹli Oluwa kan bá yọ dé, ìmọ́lẹ̀ sì tàn ninu ilé náà. Angẹli náà bá rọra lu Peteru lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ní, “Dìde kíá.” Àwọn ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi de Peteru bá yọ bọ́ kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, Angẹli náà sọ fún un pé, “Di ìgbànú rẹ, sì wọ sálúbàtà rẹ.” Peteru bá ṣe bí angẹli náà ti wí. Angẹli yìí tún sọ fún un pé, “Da aṣọ rẹ bora, kí o máa tẹ̀lé mi.” Ni Peteru bá tẹ̀lé e jáde. Kò mọ̀ pé òtítọ́ ni ohun tí ó ti ọwọ́ angẹli náà ṣẹlẹ̀, ó ṣebí àlá ni. Wọ́n kọjá ẹ̀ṣọ́ kinni ati ekeji, wọ́n wá dé ẹnu ọ̀nà ńlá onírin tí ó jáde sinu ìlú. Fúnra ìlẹ̀kùn yìí ni ó ṣí sílẹ̀ fún wọn. Wọ́n bá jáde sí ojú ọ̀nà kan. Lójú kan náà, angẹli bá rá mọ́ Peteru lójú. Ojú Peteru wá wálẹ̀. Ó ní, “Mo wá mọ̀ nítòótọ́ pé Oluwa ni ó rán angẹli rẹ̀ láti gbà mí lọ́wọ́ Hẹrọdu, ati láti yọ mí kúrò ninu ohun gbogbo tí àwọn Juu ti ń retí.” Nígbà tí ó rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó lọ sí ilé Maria ìyá Johanu tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Maku. Ọpọlọpọ eniyan ni ó péjọ sibẹ tí wọn ń gbadura.
Iṣe Apo 12:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Ní òru náà gan an ti Herodu ìbá sì mú un jáde, Peteru ń sùn láàrín àwọn ọmọ-ogun méjì, a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é, ẹ̀ṣọ́ sí wà ní ẹnu-ọ̀nà, wọ́n ń ṣọ́ túbú náà. Sì wò ó, angẹli Olúwa farahàn, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ nínú túbú; ó sì lu Peteru pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ni, “Dìde kánkán!” Ẹ̀wọ̀n sí bọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ Peteru. Angẹli náà sì wí fún un pé, “Di àmùrè rẹ̀, kí ó sì wọ sálúbàtà rẹ!” Peteru sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Da aṣọ rẹ́ bora, ki ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn!” Peteru sì jáde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; kò sí mọ̀ pé ohun tí a ṣe láti ọwọ́ angẹli náà jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe bí òun wà lójú ìran. Nígbà tí wọ́n kọjá ìṣọ́ èkínní àti èkejì, wọ́n dé ẹnu-ọ̀nà ìlẹ̀kùn irin tí ó lọ sí ìlú. Ó sí tìkára rẹ̀ ṣí sílẹ̀ fún wọn: wọ́n sì jáde, wọ́n ń gba ọ̀nà ìgboro kan lọ; lójúkan náà angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ. Nígbà tí ojú Peteru sì wálẹ̀, ó ní, “Nígbà yìí ni mo tó mọ̀ nítòótọ́ pé, Olúwa rán angẹli rẹ̀, ó sì gbà mi lọ́wọ́ Herodu àti gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn Júù ń retí!” Nígbà tó sì rò ó, ó lọ sí ilé Maria ìyá Johanu, tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku; níbi tí àwọn ènìyàn púpọ̀ péjọ sí, tí wọn ń gbàdúrà.