Iṣe Apo 12:1-24

Iṣe Apo 12:1-24 Bibeli Mimọ (YBCV)

LI akoko igbana ni Herodu ọba si nawọ́ rẹ̀ lati pọn awọn kan loju ninu ijọ. O si fi idà pa Jakọbu arakunrin Johanu. Nigbati o si ri pe, o dùnmọ awọn Ju, o si nawọ́ mu Peteru pẹlu. O si jẹ ìgba ọjọ àiwukàra. Nigbati o si mu u, o fi i sinu tubu, o fi i le ẹ̀ṣọ́ mẹrin awọn ọmọ-ogun lọwọ lati ma ṣọ ọ; o nrò lati mu u jade fun awọn enia wá lẹhin Irekọja. Nitorina nwọn pa Peteru mọ́ ninu tubu: ṣugbọn ijọ nfi itara gbadura sọdọ Ọlọrun fun u. Nigbati Herodu iba si mu u jade, li oru na Peteru sùn li arin awọn ọmọ-ogun meji, a fi ẹ̀wọn meji de e, ẹ̀ṣọ́ si wà li ẹnu-ọ̀na, nwọn nṣọ́ tubu na. Si wo o, angẹli Oluwa duro tì i, imọlẹ si mọ́ ninu tubu: nigbati o si lù Peteru pẹ́pẹ li ẹgbẹ o ji i, o ni, Dide kánkan. Ẹwọn rẹ̀ si bọ́ silẹ kuro lọwọ rẹ̀. Angẹli na si wi fun u pe, Di àmure, ki o si so salubàta rẹ. O si ṣe bẹ̃. O si wi fun u pe, Da aṣọ rẹ bora, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin. On si jade, o ntọ̀ ọ lẹhin; kò si mọ̀ pe otitọ li ohun na ṣe lati ọwọ́ angẹli na wá; ṣugbọn o ṣebi on wà li ojuran. Nigbati nwọn kọja iṣọ ikini ati keji, nwọn de ẹnu-ọ̀na ilẹkun irin, ti o lọ si ilu, ti o si tikararẹ̀ ṣí silẹ fun wọn: nigbati nwọn si jade, nwọn nlọ titi li ọ̀na igboro kan; lojukanna angẹli na si fi i silẹ lọ. Nigbati oju Peteru si walẹ, o ni, Nigbayi ni mo to mọ̀ nitõtọ pe, Oluwa rán angẹli rẹ̀, o si gbà mi li ọwọ́ Herodu, ati gbogbo ireti awọn enia Ju. Nigbati o si rò o, o lọ si ile Maria iya Johanu, ti apele rẹ̀ jẹ Marku; nibiti awọn enia pipọ pejọ si, ti nwọn ngbadura. Bi o si ti kàn ilẹkun ẹnu-ọ̀na ọmọbinrin kan ti a npè ni Roda, o wá dahun. Nigbati o si ti mọ̀ ohùn Peteru, kò ṣí ilẹkun fun ayọ̀, ṣugbọn o sure wọle, o si sọ pe, Peteru duro li ẹnu-ọ̀na. Nwọn si wi fun u pe, Iwọ nṣiwère. Ṣugbọn o tẹnumọ́ ọ gidigidi pe Bẹ̃ni sẹ. Nwọn si wipe, Angẹli rẹ̀ ni. Ṣugbọn Peteru nkànkun sibẹ, nigbati nwọn si ṣí ilẹkun, nwọn ri i, ẹnu si yà wọn. Ṣugbọn o juwọ́ si wọn pe ki nwọn ki o dakẹ, o si ròhin fun wọn bi Oluwa ti mu on jade kuro ninu tubu. O si wipe, Ẹ lọ isọ nkan wọnyi fun Jakọbu, ati awọn arakunrin. Nigbati o si jade, o lọ si ibomiran. Nigbati ilẹ si mọ́, èmimì diẹ kọ li o wà lãrin awọn ọmọ-ogun pe, nibo ni Peteru gbé wà. Nigbati Herodu si wá a kiri, ti kò si ri i, o wádi awọn ẹ̀ṣọ, o paṣẹ pe, ki a pa wọn. O si sọkalẹ lati Judea lọ si Kesarea, o si joko nibẹ̀. Herodu si mbinu gidigidi si awọn ara Tire on Sidoni: ṣugbọn nwọn fi ọkàn kan wá sọdọ rẹ̀, nigbati nwọn si ti tu Blastu iwẹfa ọba loju, nwọn mbẹbẹ fun alafia; nitori lati ilu ọba lọ li a ti mbọ́ ilu wọn. Lọjọ afiyesi kan, Herodu gunwà, o joko lori itẹ́, o si nsọ̀rọ fun wọn. Awọn enia si hó, wipe, Ohùn ọlọrun ni, kì si iṣe ti enia. Lojukanna angẹli Oluwa lù u, nitoriti kò fi ogo fun Ọlọrun: idin si jẹ ẹ, o si kú. Ṣugbọn ọ̀rọ Ọlọrun gbilẹ, o si bi si i.

Iṣe Apo 12:1-24 Yoruba Bible (YCE)

Ní àkókò náà Hẹrọdu ọba bẹ̀rẹ̀ sí ṣe inúnibíni sí àwọn kan ninu ìjọ. Ó bẹ́ Jakọbu arakunrin Johanu lórí. Nígbà tí ó rí i pé ó dùn mọ́ àwọn Juu, ó bá tún mú Peteru náà. Àkókò náà ni Àjọ̀dún Àìwúkàrà. Ó bá mú Peteru ó tì í mọ́lé. Ó fi í lé àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun mẹrin lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ; (ọmọ-ogun mẹrin ni ó wà ní ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan). Hẹrọdu fẹ́ mú Peteru wá siwaju gbogbo eniyan fún ìdájọ́ lẹ́yìn Àjọ̀dún Ìrékọjá. Wọ́n bá sọ Peteru sẹ́wọ̀n, ṣugbọn gbogbo ìjọ ń fi tọkàntọkàn gbadura sí Ọlọrun nítorí rẹ̀. Ní òru, mọ́jú ọjọ́ tí Hẹrọdu ìbá mú Peteru wá fún ìdájọ́, Peteru sùn láàrin àwọn ọmọ-ogun meji, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n meji dè é; àwọn ọmọ-ogun kan sì tún wà lẹ́nu ọ̀nà, tí wọn ń ṣọ́nà. Angẹli Oluwa kan bá yọ dé, ìmọ́lẹ̀ sì tàn ninu ilé náà. Angẹli náà bá rọra lu Peteru lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ní, “Dìde kíá.” Àwọn ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi de Peteru bá yọ bọ́ kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, Angẹli náà sọ fún un pé, “Di ìgbànú rẹ, sì wọ sálúbàtà rẹ.” Peteru bá ṣe bí angẹli náà ti wí. Angẹli yìí tún sọ fún un pé, “Da aṣọ rẹ bora, kí o máa tẹ̀lé mi.” Ni Peteru bá tẹ̀lé e jáde. Kò mọ̀ pé òtítọ́ ni ohun tí ó ti ọwọ́ angẹli náà ṣẹlẹ̀, ó ṣebí àlá ni. Wọ́n kọjá ẹ̀ṣọ́ kinni ati ekeji, wọ́n wá dé ẹnu ọ̀nà ńlá onírin tí ó jáde sinu ìlú. Fúnra ìlẹ̀kùn yìí ni ó ṣí sílẹ̀ fún wọn. Wọ́n bá jáde sí ojú ọ̀nà kan. Lójú kan náà, angẹli bá rá mọ́ Peteru lójú. Ojú Peteru wá wálẹ̀. Ó ní, “Mo wá mọ̀ nítòótọ́ pé Oluwa ni ó rán angẹli rẹ̀ láti gbà mí lọ́wọ́ Hẹrọdu, ati láti yọ mí kúrò ninu ohun gbogbo tí àwọn Juu ti ń retí.” Nígbà tí ó rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó lọ sí ilé Maria ìyá Johanu tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Maku. Ọpọlọpọ eniyan ni ó péjọ sibẹ tí wọn ń gbadura. Nígbà tí Peteru kan ìlẹ̀kùn tí ó wà lójúde, ọdọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Roda wá láti ṣí i. Nígbà tí ó gbọ́ ohùn Peteru, inú rẹ̀ dùn tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi dúró ṣí ìlẹ̀kùn; ṣugbọn ó sáré lọ sinu ilé, ó lọ sọ pé Peteru wà lóde lẹ́nu ọ̀nà. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bú u pé, “Orí rẹ dàrú!” Ṣugbọn ó ṣá tẹnumọ́ ọn pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí. Wọ́n wá sọ pé, “A jẹ́ pé angẹli rẹ̀ ni!” Ṣugbọn Peteru tún ń kanlẹ̀kùn. Nígbà tí wọ́n ṣí i, tí wọ́n rí i, ẹnu yà wọ́n. Ó bá fi ọwọ́ ṣe àmì sí wọn kí wọ́n dákẹ́; ó ròyìn fún wọn bí Oluwa ti ṣe mú òun jáde kúrò lẹ́wọ̀n. Ó ní kí wọn ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jakọbu ati fún àwọn arakunrin yòókù. Ó bá jáde, ó lọ sí ibòmíràn. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ìdààmú ńlá bá àwọn ọmọ-ogun. Wọn kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Peteru. Hẹrọdu wá Peteru títí, ṣugbọn kò rí i. Lẹ́yìn tí ó ti wádìí lẹ́nu àwọn ẹ̀ṣọ́ tán, ó ní kí wọ́n pa wọ́n. Ni Hẹrọdu bá kúrò ní Judia, ó lọ sí Kesaria, ó lọ gbé ibẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Inú bí Hẹrọdu pupọ sí àwọn ará Tire ati Sidoni. Àwọn ará ìlú wọnyi bá fi ohùn ṣọ̀kan, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n tu Bilasitu tíí ṣe ìjòyè ọba tí ó ń mójútó ààfin lójú, wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ pé kí ọba má bínú sí àwọn nítorí láti ilé ọba ni wọ́n ti ń rí oúnjẹ jẹ. Nígbà tí ó di ọjọ́ tí ọba dá fún wọn, Hẹrọdu yọ dé pẹlu aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó wá bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀. Ni àwọn eniyan náà bá ń kígbe pé, “Ohùn Ọlọrun nìyí, kì í ṣe ti eniyan!” Lẹsẹkẹsẹ angẹli Oluwa bá lù ú pa, nítorí kò fi ògo fún Ọlọrun. Ni ìdin bá jẹ ẹ́ pa. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun bẹ̀rẹ̀ sí fìdí múlẹ̀ sí i, ó sì túbọ̀ ń tàn káàkiri.

Iṣe Apo 12:1-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní àkókò ìgbà náà ni Herodu ọba sì nawọ́ rẹ̀ mú àwọn kan nínú ìjọ, pẹ̀lú èrò láti pọ́n wọn lójú. Ó sì fi idà pa Jakọbu arákùnrin Johanu. Nígbà tí ó sì rí pé èyí dùn mọ́ àwọn Júù nínú, ó sì nawọ́ mú Peteru pẹ̀lú. Ó sì jẹ́ ìgbà àjọ àìwúkàrà. Nígbà tí o sì mú un, ó fi i sínú túbú, ó fi lé àwọn ẹ̀ṣọ́ mẹ́rin ti ọmọ-ogun lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ. Herodu ń rò láti mú un jáde fún àwọn ènìyàn lẹ́yìn ìrékọjá fún ìdájọ́. Nítorí náà wọn fi Peteru pamọ́ sínú túbú; ṣùgbọ́n ìjọ ń fi ìtara gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run fún un. Ní òru náà gan an ti Herodu ìbá sì mú un jáde, Peteru ń sùn láàrín àwọn ọmọ-ogun méjì, a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é, ẹ̀ṣọ́ sí wà ní ẹnu-ọ̀nà, wọ́n ń ṣọ́ túbú náà. Sì wò ó, angẹli Olúwa farahàn, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ nínú túbú; ó sì lu Peteru pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ni, “Dìde kánkán!” Ẹ̀wọ̀n sí bọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ Peteru. Angẹli náà sì wí fún un pé, “Di àmùrè rẹ̀, kí ó sì wọ sálúbàtà rẹ!” Peteru sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Da aṣọ rẹ́ bora, ki ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn!” Peteru sì jáde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; kò sí mọ̀ pé ohun tí a ṣe láti ọwọ́ angẹli náà jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe bí òun wà lójú ìran. Nígbà tí wọ́n kọjá ìṣọ́ èkínní àti èkejì, wọ́n dé ẹnu-ọ̀nà ìlẹ̀kùn irin tí ó lọ sí ìlú. Ó sí tìkára rẹ̀ ṣí sílẹ̀ fún wọn: wọ́n sì jáde, wọ́n ń gba ọ̀nà ìgboro kan lọ; lójúkan náà angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ. Nígbà tí ojú Peteru sì wálẹ̀, ó ní, “Nígbà yìí ni mo tó mọ̀ nítòótọ́ pé, Olúwa rán angẹli rẹ̀, ó sì gbà mi lọ́wọ́ Herodu àti gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn Júù ń retí!” Nígbà tó sì rò ó, ó lọ sí ilé Maria ìyá Johanu, tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku; níbi tí àwọn ènìyàn púpọ̀ péjọ sí, tí wọn ń gbàdúrà. Bí ó sì ti kan ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin kan tí a n pè ní Roda wá láti dáhùn. Nígbà tí ó sì ti mọ ohùn Peteru, kò ṣí ìlẹ̀kùn nítorí tí ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀ gidigidi, ṣùgbọ́n ó súré wọ ilé, ó sísọ pé, Peteru dúró ní ẹnu-ọ̀nà. Wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ń ṣe òmùgọ̀!” Ṣùgbọ́n ó tẹnumọ́ ọn gidigidi pé bẹ́ẹ̀ ni sẹ́. Wọn sì wí pé, “Angẹli rẹ̀ ni!” Ṣùgbọ́n Peteru ń kànkùn síbẹ̀, nígbà tí wọn sì ṣí ìlẹ̀kùn, wọ́n rí i, ẹnu sì yá wọ́n. Ṣùgbọ́n ó juwọ́ sí wọn pé kí wọn dákẹ́, ó sì ròyìn fún wọn bí Olúwa ti mú òun jáde kúrò nínú túbú. Ó sì wí pé “Ẹ ro èyí fún Jakọbu àti àwọn arákùnrin yòókù!” Ó sì jáde, ó lọ sí ibòmíràn. Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìrúkèrúdò díẹ̀ kọ́ ni ó wà láàrín àwọn ọmọ-ogun nípa ohun tí ó dé bá Peteru. Nígbà tí Herodu sì wá a kiri, tí kò sì rí i, ó wádìí àwọn ẹ̀ṣọ́, ó pàṣẹ pé, kí a pa wọ́n. Herodu sì sọ̀kalẹ̀ láti Judea lọ sí Kesarea, ó sì wà níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Herodu sí ń bínú gidigidi sí àwọn ará Tire àti Sidoni; ṣùgbọ́n wọ́n fi ìmọ̀ ṣọ̀kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọn sì ti tu Bilasitu ìwẹ̀fà ọba lójú, wọn ń bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà, nítorí pé ìlú ọba náà ni ìlú tí wọ́n ti ń gba oúnjẹ. Ni ọjọ́ àfiyèsí kan, Herodu sì wà nínú aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ni orí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì ń bá àwọn àjọ ènìyàn sọ̀rọ̀ ní gbangba. Àwọn ènìyàn sì hó wí pé, “Ohùn ọlọ́run ni èyí, kì í sì í ṣe ti ènìyàn!” Lójúkan náà, nítorí ti Herodu kò fi ògo fún Ọlọ́run, angẹli Olúwa lù ú, ó sì kú, ìdin sì jẹ ẹ́. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbilẹ̀, ó sì bí sí i.