II. Tes 3:1-5
II. Tes 3:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
LAKOTAN, ará, ẹ mã gbadura fun wa, ki ọ̀rọ Oluwa le mã sáre, ki o si jẹ ãyìn logo, ani gẹgẹ bi o ti ri lọdọ nyin: Ati ki a le gbà wa lọwọ awọn aṣodi ati awọn enia buburu: nitoripe ki iṣe gbogbo enia li o gbagbọ́. Ṣugbọn olododo li Oluwa, ẹniti yio fi ẹsẹ nyin mulẹ, ti yio si pa nyin mọ́ kuro ninu ibi. Awa si ni igbẹkẹle ninu Oluwa niti nyin, pe nkan wọnni ti a palaṣẹ fun nyin li ẹnyin nṣe ti ẹ o si mã ṣe. Ki Oluwa ki o si mã tọ́ ọkan nyin sinu ifẹ Ọlọrun, ati sinu sũru Kristi.
II. Tes 3:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ní ìparí, ẹ̀yin ará, ẹ máa gbadura fún wa, pé kí ọ̀rọ̀ Oluwa lè máa gbilẹ̀, kí ògo rẹ̀ máa tàn sí i, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láàrin yín. Kí ẹ tún máa gbadura pé kí Ọlọrun gbà wá lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn ìkà, nítorí kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó gbàgbọ́. Ṣugbọn olódodo ni Oluwa, òun ni yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóo sì pa yín mọ́ kúrò ninu ibi gbogbo. A ní ìdánilójú ninu Oluwa nípa yín pé àwọn ohun tí a ti sọ, tí ẹ sì ń ṣe, ni ẹ óo máa ṣe. Oluwa yóo tọ́ ọkàn yín láti mọ ìfẹ́ Ọlọrun ati ohun tí Kristi faradà nítorí yín.
II. Tes 3:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní àkótán, ará, ẹ máa gbàdúrà fún wa, kí ọ̀rọ̀ Olúwa lè máa tàn káàkiri, kí ó sì jẹ́ èyí tí a bu ọlá fún, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọ̀dọ̀ yín. Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún wa kí a lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìkà àti àwọn ènìyàn búburú, nítorí pé kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló ní ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n olódodo ni Olúwa, ẹni tí yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóò sì pa yín mọ́ kúrò nínú ibi. Àwa sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ní ti ohun tí ẹ ń ṣe, àti pé àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a pàṣẹ fún un yín ni ẹ̀yin ń ṣe. Kí Olúwa máa tọ́ ọkàn yín ṣọ́nà sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti sínú sùúrù Kristi.