II. Tes 3
3
Ẹ Gbadura Fún Wa
1LAKOTAN, ará, ẹ mã gbadura fun wa, ki ọ̀rọ Oluwa le mã sáre, ki o si jẹ ãyìn logo, ani gẹgẹ bi o ti ri lọdọ nyin:
2Ati ki a le gbà wa lọwọ awọn aṣodi ati awọn enia buburu: nitoripe ki iṣe gbogbo enia li o gbagbọ́.
3Ṣugbọn olododo li Oluwa, ẹniti yio fi ẹsẹ nyin mulẹ, ti yio si pa nyin mọ́ kuro ninu ibi.
4Awa si ni igbẹkẹle ninu Oluwa niti nyin, pe nkan wọnni ti a palaṣẹ fun nyin li ẹnyin nṣe ti ẹ o si mã ṣe.
5Ki Oluwa ki o si mã tọ́ ọkan nyin sinu ifẹ Ọlọrun, ati sinu sũru Kristi.
Ìkìlọ̀ Nípa Àwọn Onímẹ̀ẹ́lẹ́
6Awa si paṣẹ fun nyin, ará, li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa, ki ẹnyin ki o yẹra kuro lọdọ olukuluku arakunrin, ti nrin ségesège, ti kì iṣe gẹgẹ bi ìlana ti nwọn ti gbà lọwọ wa.
7Nitori ẹnyin tikaranyin mọ̀ bi o ti yẹ ki ẹnyin na farawe wa: nitori awa kò rin ségesège larin nyin;
8Bẹ̃li awa kò si jẹ onjẹ ẹnikẹni lọfẹ; ṣugbọn ninu ãpọn ati lãlã li a nṣiṣẹ́ lọsan ati loru, ki awa ki o ma bã dẹruba ẹnikẹni ninu nyìn:
9Kì iṣe pe awa kò li agbara, ṣugbọn awa nfi ara wa ṣe apẹrẹ fun nyin ki ẹnyin kì o le mã farawe wa.
10Nitori nigbati awa tilẹ wà pẹlu nyin, eyi li awa palaṣẹ fun nyin, pe bi ẹnikẹni kò bá fẹ ṣiṣẹ, ki o maṣe jẹun.
11Nitori awa gburo awọn kan ti nrin ségesège larin nyìn ti nwọn kò nṣiṣẹ rara, ṣugbọn nwọn jẹ àtọjú-ile-kiri.
12Njẹ irú awọn ẹni bẹ̃ li awa npaṣẹ fun, ti a si nrọ̀ ninu Oluwa Jesu Kristi, pe ki nwọn ki o mã fi ìwa pẹlẹ ṣiṣẹ, ki nwọn ki o si mã jẹ onjẹ awọn tikarawọn.
13Ṣugbọn ẹnyin, ará, ẹ máṣe ṣãrẹ̀ ni rere iṣe.
14Bi ẹnikẹni kò ba si gbà ọ̀rọ wa gbọ́ nipa iwe yi, ẹ sami si oluwarẹ, ki ẹ má si ṣe ba a kẹgbẹ, ki oju ki o le tì i.
15Sibẹ ẹ máṣe kà a si ọtá, ṣugbọn ẹ mã gbà a niyanju bi arakunrin.
Gbolohun Ìparí
16Njẹ ki Oluwa alafia tikararẹ̀ mã fun nyin ni alafia nigbagbogbo lọna gbogbo. Ki Oluwa ki o pẹlu gbogbo nyin.
17Ikíni emi Paulu lati ọwọ́ ara mi, eyiti iṣe àmi ninu gbogbo iwe; bẹ̃ni mo nkọwe.
18Ore-ọfẹ Oluwa wa Jesu Kristi ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Tes 3: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.