II. Sam 7:1-15
II. Sam 7:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, nigbati ọba si joko ni ile rẹ̀, ti Oluwa si fun u ni isimi yika kiri kuro lọwọ gbogbo awọn ọta rẹ̀. Ọba si wi fun Natani woli pe, Sa wõ, emi ngbe inu ile ti a fi kedari kọ, ṣugbọn apoti-ẹri Ọlọrun ngbe inu ibi ti a fi aṣọ ke. Natani si wi fun ọba pe, Lọ, ki o si ṣe gbogbo eyi ti o wà li ọkàn rẹ, nitoripe Oluwa wà pẹlu rẹ. O si ṣe li oru na, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Natani wá, pe, Lọ, sọ fun iranṣẹ mi, fun Dafidi, pe, Bayi li Oluwa wi, iwọ o ha kọ ile fun mi ti emi o gbe? Nitoripe, emi ko iti gbe inu ile kan lati ọjọ ti emi ti mu awọn ọmọ Israeli goke ti ilẹ Egipti wá, titi di oni yi, ṣugbọn emi ti nrin ninu agọ, ati ninu agberin. Ni ibi gbogbo ti emi ti nrin larin gbogbo awọn ọmọ Israeli, emi ko ti iba ọkan ninu ẹya Israeli, ti emi pa aṣẹ fun lati ma bọ awọn enia mi ani Israeli sọ̀rọ pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi kedari kọ ile fun mi? Njẹ, nitorina, bayi ni iwọ o si wi fun iranṣẹ mi ani Dafidi pe, Bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, emi ti mu iwọ kuro lati inu agbo agutan wá, lati má mã tẹle awọn agutan, mo si fi ọ jẹ olori awọn enia mi, ani Israeli. Emi si wà pẹlu rẹ nibikibi ti iwọ nlọ, emi sa ke gbogbo awọn ọta rẹ kuro niwaju rẹ, emi si ti sọ orukọ rẹ di nla, gẹgẹ bi orukọ awọn enia nla ti o wà li aiye. Emi o si yàn ibi kan fun awọn enia mi, ani Israeli, emi o si gbìn wọn, nwọn o si ma joko ni ibujoko ti wọn, nwọn kì yio si ṣipo pada mọ; awọn ọmọ enia buburu kì yio si pọn wọn loju mọ, bi igba atijọ. Ati gẹgẹ bi akoko igba ti emi ti fi aṣẹ fun awọn onidajọ lori awọn enia mi, ani Israeli, emi fi isimi fun ọ lọwọ gbogbo awọn ọta rẹ. Oluwa si wi fun ọ pe, Oluwa yio kọ ile kan fun ọ. Nigbati ọjọ rẹ ba pe, ti iwọ o si sùn pẹlu awọn baba rẹ, emi o si gbe iru-ọmọ rẹ leke lẹhin rẹ, eyi ti o ti inu rẹ jade wá, emi o si fi idi ijọba rẹ kalẹ. On o si kọ ile fun orukọ mi, emi o si fi idi itẹ ijọba rẹ̀ kalẹ lailai. Emi o ma ṣe baba fun u, on o si ma jẹ ọmọ mi. Bi on ba dẹṣẹ, emi o si fi ọpá enia nà a, ati inà awọn ọmọ enia. Ṣugbọn ãnu mi kì yio yipada kuro lọdọ rẹ̀, gẹgẹ bi emi ti mu u kuro lọdọ Saulu, ti emi ti mu kuro niwaju rẹ.
II. Sam 7:1-15 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn tí Dafidi ọba ti bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú ààfin rẹ̀, tí OLUWA ti fi ọkàn rẹ̀ balẹ̀, tí ó sì dáàbò bò ó lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, ọba wí fún Natani wolii pé, “Èmi ń gbé inú ààfin tí wọ́n fi igi kedari kọ́, ṣugbọn inú àgọ́ ni àpótí ẹ̀rí OLUWA wà!” Natani dá a lóhùn pé, “Ṣe ohunkohun tí ó bá wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ.” Ṣugbọn ní òru ọjọ́ náà, OLUWA wí fún Natani pé, “Lọ sọ fún Dafidi iranṣẹ mi, pé, báyìí ni OLUWA wí, ‘Ṣé o fẹ́ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé ni? Láti ìgbà tí mo ti gba àwọn ọmọ Israẹli kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti títí di àkókò yìí, n kò fi ìgbà kan gbé inú ilé rí, inú àgọ́ ni mò ń gbé káàkiri. Ninu gbogbo bí mo ti ṣe ń bá àwọn ọmọ Israẹli kiri, ǹjẹ́ mo bèèrè lọ́wọ́ ọ̀kan ninu àwọn olórí wọn tí mo yàn láti jẹ́ alákòóso àwọn eniyan mi, pé, Kí ló dé tí wọn kò fi igi kedari kọ́ ilé fún mi?’ “Nítorí náà, sọ fún Dafidi iranṣẹ mi pé, ‘Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo mú un kúrò níbi tí ó ti ń ṣọ́ àwọn aguntan, ninu pápá, mo sì fi jọba Israẹli, àwọn eniyan mi. Mo wà pẹlu rẹ̀ ní gbogbo ibi tí ó lọ, mo sì ń ṣẹgun gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ fún un, bí ó ti ń tẹ̀síwájú. N óo sọ ọ́ di olókìkí bí ọba tí ó lágbára jùlọ láyé. N óo yan ibìkan fún Israẹli, àwọn eniyan mi, n óo sì fìdí wọn múlẹ̀ níbẹ̀. Wọn yóo máa gbé ilẹ̀ wọn, ẹnikẹ́ni kò sì ní ni wọ́n lára, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹni ibi kò ní yọ wọ́n lẹ́nu mọ́ bíi ti ìgbà tí mo yan àwọn onídàájọ́ fún Israẹli, àwọn eniyan mi. N óo fún un ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀.’ OLUWA sì tún tẹnu mọ́ ọn fún un pé, ‘Èmi fúnra mi ni n óo sọ ìdílé rẹ̀ di ìdílé ńlá. Nígbà tí ó bá jáde láyé, tí ó bá sì re ibi àgbà rè, n óo fi ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ jọba, n óo sì jẹ́ kí ìjọba rẹ̀ lágbára. Òun ni yóo kọ́ ilé fún mi, n óo sì rí i dájú pé ìran rẹ̀ ni yóo máa jọba títí laelae. N óo jẹ́ baba fún un, yóo sì jẹ́ ọmọ mi. Bí ó bá ṣẹ̀, n óo bá a wí, n óo sì jẹ ẹ́ níyà, bí baba ti í ṣe sí ọmọ rẹ̀. Ṣugbọn n kò ní káwọ́ ìfẹ́ ńlá mi kúrò lára rẹ̀, bí mo ti ká a kúrò lára Saulu, tí mo sì yọ ọ́ lóyè, kí n tó fi í jọba.
II. Sam 7:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì ṣe, nígbà tí ọba ń gbé ní ilé rẹ̀, tí OLúWA sì fún un ní ìsinmi yíkákiri kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ọba sì wí fún Natani wòlíì pé, “Sá wò ó: èmi ń gbé inú ilẹ̀ tí a fi kedari kọ́, ṣùgbọ́n àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ń gbé inú ibi tí a fi aṣọ gé.” Natani sì wí fún ọba pé, “Lọ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé OLúWA wà pẹ̀lú rẹ.” Ó sì ṣe ní òru náà, ọ̀rọ̀ OLúWA tọ Natani wá pé: “Lọ, sọ fún ìránṣẹ́ mi, fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni OLúWA wí: Ìwọ ó ha kọ́ ilé fún mi tí èmi yóò gbé. Nítorí pé, èmi kò ì ti gbé inú ilé kan láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ọmọ Israẹli gòkè ti ilẹ̀ Ejibiti wá, títí di òní yìí, ṣùgbọ́n èmi ti ń rìn nínú àgọ́, fún ibùgbé mi. Ní ibi gbogbo tí èmi ti ń rìn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ǹjẹ́ èmi ti bá ọ̀kan nínú ẹ̀yà Israẹli, tí èmi pa àṣẹ fún láti máa bọ́ àwọn ènìyàn mi àní Israẹli, sọ̀rọ̀ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi kedari kọ́ ilé fún mi.” ’ “Ǹjẹ́, nítorí náà, báyìí ni ìwọ yóò sì wí fún ìránṣẹ́ mi àní Dafidi pé, ‘Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi ti mú ìwọ kúrò láti inú agbo àgùntàn wá láti má tẹ̀lé àwọn àgùntàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórí àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli. Èmi sì wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí ìwọ ń lọ, èmi sá à gé gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ, èmi sì ti sọ orúkọ rẹ di ńlá, gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ènìyàn ńlá tí ó wà ní ayé. Èmi ó sì yan ibìkan fún àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli, èmi ó sì gbìn wọ́n, wọn ó sì má gbé bí ibùjókòó tiwọn, wọn kì yóò sì sípò padà mọ́; àwọn ọmọ ènìyàn búburú kì yóò sì pọ́n wọn lójú mọ́, bí ìgbà àtijọ́. Àti gẹ́gẹ́ bí àkókò ìgbà tí èmi ti fi àṣẹ fún àwọn onídàájọ́ lórí àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli, èmi fi ìsinmi fún ọ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ. “ ‘OLúWA sì wí fún ọ pé OLúWA yóò kọ ilé kan fún ọ: Nígbà tí ọjọ́ rẹ bá pé, tí ìwọ ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ, èmi yóò sì gbé irú-ọmọ rẹ lékè lẹ́yìn rẹ, èyí tí ó ti inú rẹ jáde wá, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀. Òun ó sì kọ́ ilé fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ láéláé. Èmi ó máa ṣe baba fún un, òun yóò sì máa jẹ́ ọmọ mi. Bí òun bá dẹ́ṣẹ̀, èmi yóò sì fi ọ̀pá ènìyàn nà án, àti ìnà àwọn ọmọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àánú mi kì yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú un kúrò lọ́dọ̀ Saulu, tí èmi ti mú kúrò níwájú rẹ.