II. Sam 6:14-23

II. Sam 6:14-23 Bibeli Mimọ (YBCV)

Dafidi si fi gbogbo agbara rẹ̀ jó niwaju Oluwa; Dafidi si wọ̀ efodu ọgbọ̀. Bẹ̃ni Dafidi ati gbogbo ile Israeli si gbe apoti-ẹri Oluwa goke wá, ti awọn ti iho ayọ̀, ati pẹlu iro ipè. Bi apoti-ẹri Oluwa si ti wọ̀ ilu Dafidi wá; Mikali ọmọbinrin Saulu si wò lati oju ferese, o si ri Dafidi ọba nfò soke o si njo niwaju Oluwa; on si kẹgàn rẹ̀ li ọkàn rẹ̀. Nwọn si mu apoti-ẹri Oluwa na wá, nwọn si gbe e kalẹ sipò rẹ̀ larin agọ na ti Dafidi pa fun u: Dafidi si rubọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ niwaju Oluwa. Dafidi si pari iṣẹ ẹbọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ na, o si sure fun awọn enia na li orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun. O si pin fun gbogbo awọn enia na, ani fun gbogbo ọpọ enia Israeli, ati ọkunrin ati obinrin; fun olukuluku iṣu akara kan ati ẹkirí ẹran kan, ati akara didun kan. Gbogbo awọn enia na si tuka lọ, olukuluku si ile rẹ̀. Dafidi si yipada lati sure fun awọn ara ile rẹ̀, Mikali ọmọbinrin Saulu si jade lati wá pade Dafidi, o si wipe, Bi o ti ṣe ohun ogo to loni fun ọba Israeli, ti o bọ ara rẹ̀ silẹ loni loju awọn iranṣẹbinrin awọn iranṣẹ rẹ̀, gẹgẹ bi ọkan ninu awọn enia asan iti bọra rẹ̀ silẹ! Dafidi si wi fun Mikali pe, Niwaju Oluwa ni, ẹniti o yàn mi fẹ jù baba rẹ lọ, ati ju gbogbo idile rẹ̀ lọ, lati fi emi ṣe olori awọn enia Oluwa, ani lori Israeli, emi o si ṣire niwaju Oluwa. Emi o si tun rẹ̀ ara mi silẹ jù bẹ̃ lọ, emi o si ṣe alainiyìn loju ara mi, ati loju awọn iranṣẹbinrin wọnni ti iwọ wi, lọdọ wọn na li emi o si li ogo. Mikali ọmọbinrin Saulu kò si bi ọmọ, titi o fi di ọjọ ikú rẹ̀.

II. Sam 6:14-23 Yoruba Bible (YCE)

Dafidi sán aṣọ mọ́dìí, ó sì ń jó pẹlu gbogbo agbára níwájú OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni ọba ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbé àpótí ẹ̀rí OLUWA wọ Jerusalẹmu, pẹlu ìhó ayọ̀ ati ìró fèrè. Bí wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí náà wọ inú ìlú Dafidi, Mikali ọmọ Saulu yọjú wo òde láti ojú fèrèsé, ó rí Dafidi ọba tí ó ń jó tí ó sì ń fò sókè níwájú OLUWA, Mikali sì kẹ́gàn rẹ̀ ninu ọkàn rẹ̀. Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí náà wọnú ìlú, wọ́n sì gbé e sí ààyè rẹ̀, ninu àgọ́ tí Dafidi ti kọ́ sílẹ̀ fún un. Dafidi sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA. Nígbà tí ó rú ẹbọ tán, ó súre fún àwọn eniyan náà ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun. Ó sì pín oúnjẹ fún gbogbo wọn, lọkunrin ati lobinrin. Ó fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìṣù àkàrà kọ̀ọ̀kan, ati ègé ẹran kọ̀ọ̀kan, ati àkàrà tí wọ́n fi èso resini sí ninu. Lẹ́yìn náà, olukuluku lọ sí ilé. Nígbà tí wọ́n parí, Dafidi pada sí ilé láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀. Mikali, ọmọ Saulu, bá lọ pàdé rẹ̀, ó ní, “Ọba Israẹli mà dárà lónìí! Ọba yán gbogbo aṣọ kúrò lára, bí aláìlóye eniyan níwájú àwọn iranṣẹbinrin àwọn iranṣẹ rẹ̀!” Dafidi dá a lóhùn pé, “Ijó ni mò ń jó, níwájú OLUWA tí ó yàn mí dípò baba rẹ ati gbogbo ìdílé rẹ̀, láti fi mí ṣe alákòóso Israẹli, àwọn eniyan OLUWA. N óo tún máa jó níwájú OLUWA. Kékeré ni èyí tí mo ṣe yìí, n óo máa ṣe jù bí mo ti ṣe yìí lọ. N kò ní jẹ́ nǹkankan lójú rẹ, ṣugbọn àwọn iranṣẹbinrin tí o sọ nípa wọn yìí, yóo bu ọlá fún mi.” Mikali, ọmọbinrin Saulu, kò sì bímọ títí ó fi kú.

II. Sam 6:14-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Dafidi sì fi gbogbo agbára rẹ̀ jó níwájú OLúWA; Dafidi sì wọ efodu ọ̀gbọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA gòkè wá, pẹ̀lú ìhó ayọ̀, àti pẹ̀lú ìró ìpè. Bí àpótí ẹ̀rí OLúWA sì ti wọ ìlú Dafidi wá; Mikali ọmọbìnrin Saulu sì wo láti ojú fèrèsé, ó sì rí Dafidi ọba ń fò sókè ó sì ń jó níwájú OLúWA; òun sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀. Wọ́n sì mú àpótí ẹ̀rí OLúWA náà wá, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sípò rẹ̀ láàrín àgọ́ náà tí Dafidi pa fún un: Dafidi sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níwájú OLúWA. Dafidi sì parí ìṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà, ó sì súre fún àwọn ènìyàn náà ní orúkọ OLúWA àwọn ọmọ-ogun. Ó sì pín fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, àní fún gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn Israẹli, àti ọkùnrin àti obìnrin; fún olúkúlùkù ìṣù àkàrà kan àti ekìrí ẹran kan, àti àkàrà díndín kan. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì túká lọ, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀. Dafidi sì yípadà láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀, Mikali ọmọbìnrin Saulu sì jáde láti wá pàdé Dafidi, ó sì wí pé, “Báwo ni ọba Israẹli ṣe ṣe ara rẹ̀ lógo bẹ́ẹ̀ lónìí, tí ó bọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ lónìí lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn lásán tí ń bọ́ra rẹ̀ sílẹ̀.” Dafidi sì wí fún Mikali pé, “Níwájú OLúWA ni, ẹni tí ó yàn mí fẹ́ ju baba rẹ lọ, àti ju gbogbo ìdílé rẹ lọ, láti fi èmi ṣe olórí àwọn ènìyàn OLúWA, àní lórí Israẹli, èmi ó sì súre níwájú OLúWA. Èmi ó sì tún rẹ ara mi sílẹ̀ jú bẹ́ẹ̀ lọ, èmi ó sì ṣe aláìníyìn lójú ara mi, àti lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà ti ìwọ wí, lọ́dọ̀ wọn náà ni èmi ó sì ní ògo.” Mikali ọmọbìnrin Saulu kò sì bí ọmọ, títí o fi di ọjọ́ ikú rẹ̀ nítorí tí ó sọ̀rọ̀-òdì yìí sí Dafidi.