II. Sam 23:20-23
II. Sam 23:20-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkunrin kan ti Kabseeli, ẹniti o pọ̀ ni iṣe agbara, on pa awọn ọmọ Arieli meji ti Moabu; o sọkalẹ pẹlu o si pa kiniun kan ninu iho lakoko sno. O si pa ara Egipti kan, ọkunrin ti o tó wò: ara Egipti na si ni ọ̀kọ kan li ọwọ́ rẹ̀: ṣugbọn on si sọkalẹ tọ̀ ọ lọ, ton ti ọ̀pá li ọwọ́, o si gba ọ̀kọ na lọwọ ara Egipti na, o si fi ọ̀kọ tirẹ̀ pa a. Nkan wọnyi ni Benaia ọmọ Jehoiada ṣe, o si li orukọ ninu awọn ọkunrin alagbara mẹta nì. Ninu awọn ọgbọ̀n na, on ṣe ọlọlajulọ, ṣugbọn on kò to awọn mẹta ti iṣaju. Dafidi si fi i ṣe igbimọ̀ rẹ̀.
II. Sam 23:20-23 Yoruba Bible (YCE)
Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, ará Kabiseeli, náà tún jẹ́ akọni ọmọ ogun, ọpọlọpọ nǹkan ńláńlá ni ó fi ìgboyà ṣe. Ó pa àwọn akikanju ọmọ ogun ará Moabu meji ní àkókò kan. Ní ọjọ́ kan lẹ́yìn tí yìnyín bọ́ sílẹ̀, ó wọ inú ihò kan lọ, ó sì pa kinniun kan sibẹ. Bẹ́ẹ̀ náà ni, ó pa ọkunrin ará Ijipti kan tí ó ṣígbọnlẹ̀, tí ó sì dira ogun tòun tọ̀kọ̀. Kùmọ̀ lásán ni Bẹnaya mú lọ́wọ́ tí ó fi dojú kọ ọ́, ó já ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ ọmọ ogun ará Ijipti yìí gbà, ó sì fi pa á. Àwọn nǹkan akikanju ti Bẹnaya ṣe nìwọ̀nyí, ó sì ní òkìkí, yàtọ̀ sí ti “Àwọn Akọni Mẹta”. Akọni ni láàrin “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni”, ṣugbọn kò lókìkí tó “Àwọn Akọni Mẹta” ti àkọ́kọ́, òun ni Dafidi sì fi ṣe olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.
II. Sam 23:20-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkùnrin kan tí Kabṣeeli, ẹni tí ó pọ̀ ní iṣẹ́ agbára, òun pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu; ó sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ó sì pa kìnnìún kan nínú ihò lákoko òjò-dídì. Ó sì pa ará Ejibiti kan, ọkùnrin tí ó dára láti wò: ará Ejibiti náà sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀: ṣùgbọ́n Benaiah sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́, ó sì gba ọ̀kọ̀ náà lọ́wọ́ ará Ejibiti náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa á. Nǹkan wọ̀nyí ní Benaiah ọmọ Jehoiada ṣe, ó sì ní orúkọ nínú àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta náà. Nínú àwọn ọgbọ̀n (30) náà, òun ní ọlá jùlọ, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ti ìṣáájú. Dafidi sì fi í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀.