II. Sam 22:31-37
II. Sam 22:31-37 Bibeli Mimọ (YBCV)
Pipe li Ọlọrun li ọ̀na rẹ̀; ọ̀rọ Oluwa li a ti dan wò: on si ni asà fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e. Nitori tani iṣe Ọlọrun, bikoṣe Oluwa? tabi tani iṣe apáta, bikoṣe Ọlọrun wa? Ọlọrun alagbara li o fun mi li agbara, o si sọ ọ̀na mi di titọ́. O ṣe ẹsẹ mi bi ẹsẹ agbọnrin: o si mu mi duro ni ibi giga mi. O kọ ọwọ́ mi ni ogun jijà; tobẹ̃ ti apá mi fà ọrun idẹ. Iwọ si ti fun mi li asà igbala rẹ: irẹlẹ rẹ si ti sọ mi di nla. Iwọ si sọ itẹlẹ mi di nla li abẹ mi; tobẹ̃ ti ẹsẹ mi kò fi yọ̀.
II. Sam 22:31-37 Yoruba Bible (YCE)
Ní ti Ọlọrun yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀, òtítọ́ ni ìlérí OLUWA, ó sì jẹ́ apata fun gbogbo àwọn tí wọ́n bá sápamọ́ sábẹ́ ààbò rẹ̀. Ta ni Ọlọrun bí kò ṣe OLUWA? Ta sì ni àpáta ààbò bí kò ṣe Ọlọrun wa? Ọlọrun yìí ni ààbò mi tí ó lágbára, ó mú gbogbo ewu kúrò ní ọ̀nà mi. Ó fún ẹsẹ̀ mi lókun láti sáré bí àgbọ̀nrín, ó sì mú kí n wà ní àìléwu lórí àwọn òkè. Ó kọ́ mi ní ogun jíjà, tóbẹ́ẹ̀ tí mo lè lo ọrun idẹ. “O fún mi ní àpáta ìgbàlà rẹ, ìrànlọ́wọ́ rẹ ni ó sọ mí di ẹni ńlá. Ìwọ ni o kò jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tá tẹ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni o kò jẹ́ kí ẹsẹ̀ mí kí ó yẹ̀.
II. Sam 22:31-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ọlọ́run yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀; ọ̀rọ̀ OLúWA ni a ti dánwò. Òun sì ni asà fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e. Nítorí ta ni Ọlọ́run, bí kò ṣe OLúWA? Ta ni àpáta, bí kò ṣe Ọlọ́run wa. Ọlọ́run alágbára ni ó fún mi ní agbára, ó sì sọ ọ̀nà mi di títọ́. Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín; ó sì mú mi dúró ní ibi gíga mi. Ó kọ́ ọwọ́ mi ní ogun jíjà; tó bẹ́ẹ̀ tí apá mi fa ọrun idẹ. Ìwọ sì ti fún mi ní asà ìgbàlà rẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ sì ti sọ mí di ńlá. Ìwọ sì sọ ìtẹ̀lẹ̀ di ńlá ní abẹ́ mi; tó bẹ́ẹ̀ tí ẹsẹ̀ mi kò fi yọ̀.