II. Sam 22

22
Orin ìṣẹ́gun tí Dafidi kọ
(O. Daf 18)
1DAFIDI si sọ ọ̀rọ orin yi si Oluwa li ọjọ ti Oluwa gbà a kuro li ọwọ́ gbogbo awọn ọta rẹ̀, ati kuro li ọwọ́ Saulu.
2O si wipe, Oluwa li apata mi; ati odi mi, ati olugbala mi;
3Ọlọrun apata mi; emi o gbẹkẹle e: asà mi, ati iwo igbala mi, ibi isadi giga mi, ati ibi ãbò mi, olugbala mi; iwọ li o ti gbà mi kuro lọwọ agbara.
4Emi o kepe Oluwa, ti o yẹ lati ma yìn: a o si gbà mi lọwọ awọn ọta mi.
5Nigbati ibilu irora ikú yi mi ka kiri, ti awọn iṣàn enia buburu dẹruba mi;
6Ọjá ipo-okú yi mi ka kiri; ikẹkun ikú ti ṣaju mi.
7Ninu ipọnju mi emi ke pe Oluwa, emi si gbe ohùn mi soke si Ọlọrun mi: o si gbohùn mi lati tempili rẹ̀ wá, igbe mi si wọ̀ eti rẹ̀.
8Ilẹ si mì, o si wariri; ipilẹ ọrun wariri, o si mì, nitoriti o binu.
9Ẽfin si jade lati iho-imu rẹ̀ wa, ina lati ẹnu rẹ̀ wa si njonirun, ẹyín si nràn nipasẹ rẹ̀.
10O tẹ ori ọrun ba pẹlu, o si sọkalẹ; okunkun biri-biri si mbẹ li atẹlẹsẹ rẹ̀.
11O si gun ori kerubu, o si fò: a si ri i lori iyẹ afẹfẹ.
12O si fi okunkun ṣe ibujoko yi ara rẹ̀ ka, ati agbajọ omi, ani iṣududu awọ sanma.
13Nipasẹ imọlẹ iwaju rẹ̀ ẹyin-iná ràn.
14Oluwa san ãra lati ọrun wá, ọga-ogo julọ si fọhùn rẹ̀.
15O si ta ọfà, o si tú wọn ka; o kọ màna-mána, o si ṣẹ wọn.
16Iṣàn ibu okun si fi ara hàn, ipilẹ aiye fi ara hàn, nipa ibawi Oluwa, nipa fifún ẽmi ihò imu rẹ̀.
17O ranṣẹ lati oke wá, o mu mi; o fà mi jade lati inu omi nla wá.
18O gbà mi lọwọ ọta mi alagbara, lọwọ awọn ti o korira mi: nitoripe nwọn li agbara jù mi lọ.
19Nwọn ṣaju mi li ọjọ ipọnju mi; ṣugbọn Oluwa li alafẹhinti mi.
20O si mu mi wá si àye nla: o gbà mi, nitoriti inu rẹ̀ dùn si mi.
21Oluwa san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi: o si san a fun mi gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ́ mi.
22Nitoripe emi pa ọ̀na Oluwa mọ, emi kò si fi ìwa buburu yapa kuro lọdọ Ọlọrun mi.
23Nitoripe gbogbo idajọ rẹ̀ li o wà niwaju mi: ati niti ofin rẹ̀, emi kò si yapa kuro ninu wọn.
24Emi si wà ninu iwà-titọ si i, emi si pa ara mi mọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi.
25Oluwa si san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi, gẹgẹ bi ìwa-mimọ́ mi niwaju rẹ̀.
26Fun alãnu ni iwọ o fi ara rẹ hàn li alãnu, ati fun ẹni-iduro-ṣinṣin li ododo ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni iduro-ṣinṣin li ododo.
27Fun oninu-funfun ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni funfun: ati fun ẹni-wiwọ ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni wiwọ.
28Awọn enia ti o wà ninu iyà ni iwọ o si gbàla: ṣugbọn oju rẹ wà lara awọn agberaga, lati rẹ̀ wọn silẹ.
29Nitori iwọ ni imọlẹ mi, Oluwa: Oluwa yio si sọ okunkun mi di imọlẹ.
30Nitori nipa rẹ li emi ti là arin ogun kọja: nipa Ọlọrun mi emi ti fò odi kan.
31Pipe li Ọlọrun li ọ̀na rẹ̀; ọ̀rọ Oluwa li a ti dan wò: on si ni asà fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e.
32Nitori tani iṣe Ọlọrun, bikoṣe Oluwa? tabi tani iṣe apáta, bikoṣe Ọlọrun wa?
33Ọlọrun alagbara li o fun mi li agbara, o si sọ ọ̀na mi di titọ́.
34O ṣe ẹsẹ mi bi ẹsẹ agbọnrin: o si mu mi duro ni ibi giga mi.
35O kọ ọwọ́ mi ni ogun jijà; tobẹ̃ ti apá mi fà ọrun idẹ.
36Iwọ si ti fun mi li asà igbala rẹ: irẹlẹ rẹ si ti sọ mi di nla.
37Iwọ si sọ itẹlẹ mi di nla li abẹ mi; tobẹ̃ ti ẹsẹ mi kò fi yọ̀.
38Emi ti lepa awọn ọta mi, emi si ti run wọn; emi kò pẹhinda titi emi fi run wọn.
39Emi ti pa wọn run, emi si ti fọ́ wọn, nwọn kò si le dide mọ: nwọn ṣubu labẹ ẹsẹ mi.
40Iwọ si ti fi agbara di mi li amure fun ijà: awọn ti o ti dide si mi ni iwọ si ti tẹ̀ li ori ba fun mi.
41Iwọ si mu awọn ọta mi pẹhindà fun mi, emi si pa awọn ti o korira mi run.
42Nwọn wò, ṣugbọn kò si ẹnikan lati gbà wọn; nwọn wò Oluwa, ṣugbọn kò da wọn lohùn.
43Nigbana ni emi si gun wọn wẹwẹ bi erupẹ ilẹ, emi si tẹ̀ wọn mọlẹ bi ẹrẹ̀ ita, emi si tẹ wọn gbọrọ.
44Iwọ si gbà mi kuro lọwọ ijà awọn enia mi, iwọ pa mi mọ ki emi ki o le ṣe olori awọn ajeji orilẹ-ède: awọn enia ti emi kò ti mọ̀ yio ma sìn mi.
45Awọn alejo yio fi ẹ̀tan tẹriba fun mi: bi nwọn ba ti gbọ́ iró mi, nwọn o si gbọ́ ti emi.
46Ìpaiyà yio dé bá awọn alejo, nwọn o si ma bẹ̀ru nibi kọ́lọfin wọn.
47Oluwa mbẹ; olubukun si ni apata mi: gbigbega si li Ọlọrun apata igbala mi.
48Ọlọrun li ẹniti ngbẹsan mi, ati ẹniti nrẹ̀ awọn enia silẹ labẹ mi.
49On ni o gbà mi kuro lọwọ awọn ọta mi: iwọ si gbe mi soke ju awọn ti o dide si mi lọ: iwọ si gbà mi kuro lọwọ ọkunrin ìwa agbara.
50Nitorina emi o fi ọpẹ fun ọ. Oluwa, larin awọn ajeji orilẹ-ède: emi o si kọrin si orukọ rẹ.
51On ni ile-iṣọ igbala fun ọba rẹ̀: o si fi ãnu hàn fun ẹni-ami-ororo rẹ̀; fun Dafidi, ati fun iru-ọmọ rẹ̀ titi lailai.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Sam 22: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀