II. Sam 22:1-3
II. Sam 22:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
DAFIDI si sọ ọ̀rọ orin yi si Oluwa li ọjọ ti Oluwa gbà a kuro li ọwọ́ gbogbo awọn ọta rẹ̀, ati kuro li ọwọ́ Saulu. O si wipe, Oluwa li apata mi; ati odi mi, ati olugbala mi; Ọlọrun apata mi; emi o gbẹkẹle e: asà mi, ati iwo igbala mi, ibi isadi giga mi, ati ibi ãbò mi, olugbala mi; iwọ li o ti gbà mi kuro lọwọ agbara.
II. Sam 22:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí OLUWA gba Dafidi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ati lọ́wọ́ Saulu, Dafidi kọ orin yìí sí OLUWA pé: “OLUWA ni àpáta mi, ààbò mi, ati olùgbàlà mi; Ọlọrun mi, àpáta mi, ọ̀dọ̀ ẹni tí mo sá pamọ́ sí. Àpáta mi ati ìgbàlà mi, ààbò mi ati ibi ìpamọ́ mi, olùgbàlà mi, ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìwà ipá.
II. Sam 22:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Dafidi sì kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sí OLúWA ní ọjọ́ tí OLúWA gbà á kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ Saulu. Ó sì wí pé: “OLúWA ni àpáta mi, àti Olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò, àti ìwo ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi. Àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi; ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá.