II. Sam 20:1-13
II. Sam 20:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọkunrin Beliali kan si mbẹ nibẹ orukọ rẹ̀ si njẹ Ṣeba ọmọ Bikri ara Benjamini; o si fún ipè o si wipe, Awa kò ni ipa ni Dafidi, bẹ̃li awa kò ni ini ni ọmọ Jesse: ki olukuluku ọkunrin lọ si agọ rẹ̀, ẹnyin Israeli. Gbogbo awọn ọkunrin Israeli si lọ kuro lẹhin Dafidi, nwọn si ntọ Ṣeba ọmọ Bikri lẹhin: ṣugbọn awọn ọkunrin Juda si fi ara mọ́ ọba wọn lati odo Jordani wá titi o fi de Jerusalemu. Dafidi si wá si ile rẹ̀ ni Jerusalemu; ọba si mu awọn obinrin mẹwa ti iṣe alè rẹ̀, awọn ti o ti fi silẹ lati ma ṣọ́ ile. O si há wọn mọ ile, o si mbọ́ wọn, ṣugbọn kò si tun wọle tọ̀ wọn mọ a si se wọn mọ titi di ọjọ ikú wọn, nwọn si wà bi opo. Ọba si wi fun Amasa pe, Pe awọn ọkunrin Juda fun mi niwọn ijọ mẹta oni, ki iwọ na ki o si wá nihinyi. Amasa si lọ lati pe awọn ọkunrin Juda: ṣugbọn o si duro pẹ jù akoko ti o fi fun u. Dafidi si wi fun Abiṣai pe, Nisisiyi Ṣeba ọmọ Bikri yio ṣe wa ni ibi jù ti Absalomu lọ; iwọ mu awọn iranṣẹ Oluwa rẹ, ki o si lepa rẹ̀, ki o ma ba ri ilu olodi wọ̀, ki o si bọ́ lọwọ wa, Awọn ọmọkunrin Joabu si jade tọ̀ ọ lọ, ati awọn Kereti, ati awọn Peleti, ati gbogbo awọn ọkunrin alagbara: nwọn si ti Jerusalemu jade lọ, lati lepa Ṣeba ọmọ Bikri. Nigbati nwọn de ibi okuta nla ti o wà ni Gibeoni, Amasa si ṣaju wọn. Joabu si di amùre si agbada rẹ̀ ti o wọ̀, o si sán idà rẹ̀ mọ idi, ninu akọ̀ rẹ̀, bi o si ti nlọ, o yọ jade. Joabu si bi Amasa lere pe, Ara rẹ ko le bi, iwọ arakunrin mi? Joabu si na ọwọ́ ọtún rẹ̀ di Amasa ni irungbọ̀n mu lati fi ẹnu kò o li ẹnu. Ṣugbọn Amasa ko si kiyesi idà ti mbẹ li ọwọ́ Joabu: bẹ̃li on si fi gun u li ẽgun ìha ikarun, ifun rẹ̀ si tú dá silẹ, on kò si tun gún u mọ́; o si kú. Joabu ati Abiṣai arakunrin rẹ̀ si lepa Ṣeba ọmọ Bikri. Ọkan ninu awọn ọdọmọdekunrin ti o wà lọdọ Joabu si duro tì i, o si wipe, Tali ẹni ti o ba fẹran Joabu? tali o si nṣe ti Dafidi, ki o ma tọ̀ Joabu lẹhin. Amasa si nyira ninu ẹ̀jẹ larin ọ̀na. Ọkunrin na si ri pe gbogbo enia si duro tì i, o si gbe Amasa kuro loju ọ̀na lọ sinu ìgbẹ́, o si fi aṣọ bò o, nigbati o ti ri pe ẹnikẹni ti o ba de ọdọ rẹ̀, a duro. Nigbati o si gbe e kuro li oju ọ̀na, gbogbo enia si tọ̀ Joabu lẹhin lati lepa Ṣeba ọmọ Bikri.
II. Sam 20:1-13 Yoruba Bible (YCE)
Aláìníláárí ẹ̀dá kan wà ní ààrin àwọn ará Giligali tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikiri, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Ọkunrin yìí fọn fèrè, ó ní, “Kò sí ohun tí ó kàn wá pẹlu Dafidi, a kò sì ní ìpín nílé ọmọ Jese. Ẹ pada sí ilé yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.” Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada lẹ́yìn Dafidi, wọ́n tẹ̀lé Ṣeba. Ṣugbọn àwọn eniyan Juda tẹ̀lé Dafidi, ọba wọn, pẹlu ẹ̀mí òtítọ́, láti odò Jọdani títí dé Jerusalẹmu. Nígbà tí Dafidi pada dé ààfin rẹ̀ ní Jerusalẹmu, ó mú àwọn obinrin rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó fi sílẹ̀, pé kí wọ́n máa tọ́jú ààfin, ó fi wọ́n sinu ilé kan pẹlu olùṣọ́, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún wọn, ṣugbọn kò bá wọn lòpọ̀ mọ́. Ninu ìhámọ́ ni wọ́n wà, tí wọ́n ń gbé bí opó, títí tí wọ́n fi kú. Lẹ́yìn náà, ọba sọ fún Amasa pé, “Pe gbogbo àwọn ọkunrin Juda jọ, kí o sì kó wọn wá sọ́dọ̀ mi láàrin ọjọ́ mẹta; kí ìwọ náà sì wá.” Amasa bá lọ kó àwọn eniyan Juda jọ, ṣugbọn kò dé títí àkókò tí ọba dá fún un fi kọjá. Ọba bá pe Abiṣai, ó ní, “Ìyọnu tí Ṣeba yóo kó bá wa yóo ju ti Absalomu lọ. Nítorí náà, kó àwọn eniyan mi lẹ́yìn kí o sì máa lépa rẹ̀ lọ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè gba àwọn ìlú olódi bíi mélòó kan kí ó sì dá wahala sílẹ̀ fún wa.” Gbogbo àwọn ọmọ ogun Joabu, ati àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun yòókù, tí wọ́n kù ní Jerusalẹmu bá tẹ̀lé Abiṣai láti lépa Ṣeba. Nígbà tí wọ́n dé ibi òkúta ńlá kan, tí ó wà ní Gibeoni, Amasa lọ pàdé wọn. Ẹ̀wù ọmọ ogun ni Joabu wọ̀; ó sán ìgbànú kan, idà rẹ̀ sì wà ninu àkọ̀ lára ìgbànú tí ó ti sán mọ́ ìbàdí. Bí Joabu ti rìn siwaju bẹ́ẹ̀ ni idà yìí bọ́ sílẹ̀. Ó bá bèèrè lọ́wọ́ Amasa pé, “Ṣé alaafia ni, arakunrin mi?” Ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbá Amasa ní irùngbọ̀n mú, bí ẹni pé ó fẹ́ fi ẹnu kò ó ní ẹnu. Amasa kò fura rárá pé idà wà ní ọwọ́ Joabu. Joabu bá gún un ní idà níkùn, gbogbo ìfun rẹ̀ tú jáde. Amasa kú lẹsẹkẹsẹ, láì jẹ́ pé Joabu tún gún un ní idà lẹẹkeji. Joabu ati Abiṣai arakunrin rẹ̀ bá ń lépa Ṣeba lọ. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Joabu dúró ti òkú Amasa, ó sì ń kígbe pé, “Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ti Joabu ati ti Dafidi tẹ̀lé Joabu.” Òkú Amasa, tí ẹ̀jẹ̀ ti bò, wà ní ojú ọ̀nà gbangba, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń kọjá, tí ó bá rí i ń dúró. Nígbà tí ọkunrin tí ó dúró ti òkú náà rí i pé gbogbo eniyan ní ń dúró, ó wọ́ òkú náà kúrò lójú ọ̀nà, sinu igbó, ó sì fi aṣọ bò ó. Nígbà tí ó wọ́ ọ kúrò lójú ọ̀nà tán, gbogbo àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí sá tẹ̀lé Joabu, wọ́n ń lépa Ṣeba lọ.
II. Sam 20:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọkùnrin Beliali kan sì ń bẹ níbẹ̀ orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣeba ọmọ Bikri ará Benjamini; ó sì fún ìpè ó sì wí pé, “Àwa kò ní ipa nínú Dafidi, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ni ìní nínú ọmọ Jese! Kí olúkúlùkù ọkùnrin lọ sí àgọ́ rẹ̀, ẹ̀yin Israẹli!” Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli sì lọ kúrò lẹ́yìn Dafidi, wọ́n sì ń tọ́ Ṣeba ọmọ Bikri lẹ́yìn: ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Juda sì fi ara mọ́ ọba wọn láti odò Jordani wá títí ó fi dé Jerusalẹmu. Dafidi sì wà ní ilé rẹ̀ ní Jerusalẹmu; ọba sì mú àwọn obìnrin mẹ́wàá tí í ṣe àlè rẹ̀, àwọn tí ó ti fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé, Ó sì há wọn mọ́ ilé, ó sì ń bọ́ wọn, ṣùgbọ́n kò sì tún wọlé tọ̀ wọ́n mọ́. A sì sé wọn mọ́ títí di ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì wà bí opó. Ọba sì wí fún Amasa pé, “Pe àwọn ọkùnrin Juda fún mi ní ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta òní, kí ìwọ náà kí o sì wà níhìn-ín yìí.” Amasa sì lọ láti pe àwọn ọkùnrin Juda; ṣùgbọ́n ó sì dúró pẹ́ ju àkókò tí a fi fún un. Dafidi sì wí fún Abiṣai pé, “Nísinsin yìí Ṣeba ọmọ Bikri yóò ṣe wá ní ibi ju ti Absalomu lọ; ìwọ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ, kí o sì lépa rẹ̀, kí ó má ba à rí ìlú olódi wọ̀, kí ó sì bọ́ lọ́wọ́ wa.” Àwọn ọmọkùnrin Joabu sì jáde tọ̀ ọ́ lọ, àti àwọn Kereti, àti àwọn Peleti, àti gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára: wọ́n sì ti Jerusalẹmu jáde lọ, láti lépa Ṣeba ọmọ Bikri. Nígbà tí wọ́n dé ibi òkúta ńlá tí ó wà ní Gibeoni, Amasa sì ṣáájú wọn, Joabu sì di àmùrè sí agbádá rẹ̀ tí ó wọ̀, ó sì sán idà rẹ̀ mọ́ ìdí, nínú àkọ̀ rẹ̀, bí ó sì ti ń lọ, ó yọ́ jáde. Joabu sì bi Amasa léèrè pé, “Àlàáfíà ha kọ́ ni bí, ìwọ arákùnrin mi?” Joabu sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, di Amasa ní irùngbọ̀n mú láti fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Ṣùgbọ́n Amasa kò sì kíyèsi idà tí ń bẹ lọ́wọ́ Joabu: bẹ́ẹ̀ ni òun sì fi gún un ní ikùn, ìfun rẹ̀ sì tú dà sílẹ̀, òun kò sì tún gún un mọ́: Amasa sì kú. Joabu àti Abiṣai arákùnrin rẹ̀ sì lépa Ṣeba ọmọ Bikri. Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Joabu sì dúró tì Amasa, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni tí ó fẹ́ràn Joabu? Ta ni ó sì ń ṣe ti Dafidi, kí ó máa tọ Joabu lẹ́yìn.” Amasa sì ń yíràá nínú ẹ̀jẹ̀ láàrín ọ̀nà. Ọkùnrin náà sì rí i pé gbogbo ènìyàn sì dúró tì í, ó sì gbé Amasa kúrò lójú ọ̀nà lọ sínú igbó, ó sì fi aṣọ bò ó, nígbà tí ó rí i pé ẹnikẹ́ni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, á dúró. Nígbà tí ó sì gbé Amasa kúrò lójú ọ̀nà gbogbo ènìyàn sì tọ Joabu lẹ́yìn láti lépa Ṣeba ọmọ Bikri.